BBC Africa Eye tú àṣírí ìfiyàjẹni àwọn Ológun, SARS káàkiri Nàìjíríà

Àkọlé fídíò, BBC Africa Eye tú àṣírí ìfìyàjẹni àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò

ÌKÌLỌ̀ PÀTÀKÌ: Fọnran yii ni aworan awọn nkan to lee ba ni lọkan jẹ atawọn aworan ifiyajẹni pupọ.

Akanṣe eto BBC Africa to maa n tu aṣiri awọn nkan ikọkọ tabi to fara sin to si n ṣakoba fun araalu ati ijọba ti fi fidio to wa loke yii tu aṣiri kan ni Naijiria.

Pẹlu awọn fidio to n ṣe aridaju awọn iṣẹlẹ yii ti wọn fi han, aṣiri tu sita pe ifiyajẹni ti di aṣa ti ọpọlọpọ ẹka ileeṣẹ Ọlọpaa Naijira atawọn ologun n lo.

Ofin Naijiria lodi si ifiyajẹni. Ṣugbọn awọn aworan taa ri lori ayelujara fi han pe aṣa kan wa ni pato to wọpọ ti wọn maa n lo lati fi wa ọrọ lẹnu awọn ti wọn ko nigbekun ati lati fiya jẹ wọn koda ko yọ awọn ọmọde silẹ.

Akanṣe iwadii yii boju wo ibẹrẹpẹpẹ aṣa ifiyajẹni awọn agbofinro yii, o foju awọn tọwọ wọn wa ninu rẹ ju han, o si wadii idi ti wọn ko fi fi wọn jofin.

Bakan naa, o ṣafihan pe lọdun 2014, ọga agba Ọlọpaa kan lọwọ ninu ifiyajẹ ọmọkunrin kan to pada ku tori bi wọn ṣe fiya jẹ ẹ.