Thailand Shooting: Àwọn ológun ti pa Sọjà tó pa èèyàn 26

Thailand

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ọmọogun kan to yinbọn pa araalu mẹrindinlọgbọn ni ilu Nakhon Ratchasima lawọn ologun naa ti shina ibọn bolẹ pa gẹgẹ bi Ọlọpaa orilẹede Thailand ṣe sọ ọ.

Lọjọ abamẹta, Jakraphanth Thomma pa ọga rẹ ko to lọ ji awọn nkan ijagun ko ni bareke awọn ologun.

Ṣe ni afurasi yii bẹrẹ si ni da ibọn bolẹ to si n pa awọn eniyan loju popo ati ninu ile itaja lagbegbe naa.

Awọn oṣiṣẹ alaabo naa ba doju ibọn kọ Thomma nigba ti wọn yi ika lẹgbẹ ibi kan ti wọn ti ba a to wa ni gbogbo alẹ ana.

Olootu ilẹ Thailand, Prayuth Chan-ocha ohun to wa nidi ikọlu ọhun gan ni Ọgbẹni Thoma binu lori pe o gbagbọ pe wọn yan oun jẹ lori ọrọ ilẹ.

Olootu naa ti ṣabẹwo si eniyan mẹtadinlọgọta to fara pa nibi ikọlu naa lọjọ aiku nibẹ lo si ti kede pe iye eniyan to ku tun ti le logun bayii.

O ni "iru nkan bayi kii ṣẹlẹ ni Thailand tẹlẹ mo dẹ fẹ ki eyi jẹ igba ikẹyin ti iru rẹ yoo ṣẹlẹ.