Thailand: Gbogbo àwọn agbábọ́ọ́lù náà láti yọ kúrò nínú ihò

Gbogbo awọn ogo wẹẹrẹ mejila to jẹ agbabọọlu ni orilẹede Thailand ni wọn ti doola ẹmi wọn lẹyin ti wọn ha si inu iwo lati bi ọsẹ meji sẹhin.
Ile isẹ ọmọogun ilẹ Thailand to fi ọrọ naa lede sọ wi pe omuwe kọọkan lo gbe awọn ọmọ naa jade ni ẹyọ kọọkan.

Awọn omuwẹ ti ilẹ Thailand to bẹrẹ ni Ọjọ Isinmi lati doola ẹmi wọn, yọ mẹ́rin miran pẹlu awọn mẹrin ti wọn yọ tẹlẹ ni ọjọ keji igbiyanju lati yọ awọn ọmọ naa.

Oríṣun àwòrán, Alamy
Nibayii, iroyin sọ wi pe wọn gbogbo awọn omuwẹ mẹrin ati dokita to tọju awọn ọmọ naa ni inu iho ti wọn ha si ti jade si ita kuro ni inu iho ohun.









