Thailand: Wọ́n ti yọ àwọ̀n mẹ́rin mìíràn nínú áwọn ọmọ tó jìn sí kòtò!

Nínú àwọn ọmọkùnrin méjìlá tó já sínú ihò lórílẹ̀èdè Thailand, wọ́n ti yọ mẹ́rin miran pelu awọn mẹrin ti wọn yọ tẹlẹ ni ọjọ keji igbiyanju lati yọ awọn ọmọ naa.
Awọn omuwẹ ti ilẹ Thailand sọ wi pe awọn mẹrin lo ku pẹlu akọnimọọgba wọn si inu iwo naa.
Ileesẹ Ọmọogun Ilẹ Thailand to n gbe igbese lati doola ẹmi awọn ọmọ naa sọ wi pe o ti da mẹjọ ninu awọn agbabọọlu naa ti wọn ti yọ.
Ọjọ Isinmi ni wọn yọ awọn mẹrin akọọkọ, sugbon wọn dawọ rẹ duro lẹyin ti afẹfẹ gaasi tan ti wọn si wa ọna lati wa omiran.









