#EKITIDECIDES: Ìdàrúdàpọ̀ wáyé níbí ìpàdé ìdìbò l'Ékìtì

Àkọlé fídíò, #EKITIDECIDES: Ìdàrúdàpọ̀ wáyé níbí ìpàdé ìdìbò l'Ékìtì

Idarudapọ waye nibi ipade apero ti ẹgbẹ ajọ eleto idibo INEC pe nilu Ado Ekiti laarin awọn ti ọrọ idibo gomina nipinlẹ Ekiti kan gbọn-gbọn-gbọn.

Eredi ipade naa ni lati fi ibi ti igbaradi de duro laarin ajọ INEC ati awọn agbofinro.

Ipade naa ti bẹrẹ ni irọwọ-irọsẹ, ti Kọmiṣọa ajọ INEC nipinlẹ Ekiti, Ọjọgbọn Abdulganiy Raji si ti yannana igbaradi ajọ naa fun idibo ọhun ti yoo waye ni ọjọ abamẹta.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa, Ọmọọba Solomọn Soyebi to jẹ Kọmiṣọna apapọ fun ipinlẹ Ondo, Ekiti ati Ọṣun si tun ti kede isunsiwaju eto gbigba kaadi idibo ni ipinlẹ naa ṣaaju eto idibo ọhun, ti ga ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Ibrahim Ringim si ṣalaye pe ko saye fun iregbe lasiko idibo naa.

Amọṣa, ni kete ti wọn gbe ẹrọ gbohungbohun fun aṣoju ẹgbẹ oṣelu PDP, Samuel Ọmọtọṣọ to sọrọ nipa bi wọn ṣe n dukuku mọ awọn eeyan kan, lawọn ololufẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ba bẹrẹ ariwo nla.

Gbogbo akitiyan Ọga ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Ibrahim Ringim ati awọn ọbalaye to wa ni ikalẹ lati pẹtu si wọn pe ki wọn ṣinmọdọ lo ja si pabo.

Ariwo yii tẹ siwaju fun ọpọlọpọ iṣẹju eleyi to mu ki awọn oṣiṣẹ ajọ INEC ati awọn olori ẹka agbofinro gbogbo o fi ipade naa silẹ