Ekiti Election: Ǹkan méwàá tó yẹ kí o mọ̀ nípa Oluṣọla Eleka

Oríṣun àwòrán, @elekaolusola
Oluṣọla Eleka tó ń díje fún ipò gómìnà Ekiti lábẹ́ asia ẹgbẹ́ oṣelu PDP.
- Pa. Joshua Olusola Eleka ati Eunice Ademolabi Ojo Eleka bi Ọjọgbọn Kọlapọ Olubunmi Oluṣola lọdun 1968 ni Ikẹrẹ-Ekiti nipinlẹ Ekiti.
- O lọ sile iwe St. Matthew's Primary School, Ikere-Ekiti (1972-1978) ati Annunciation School, Ikere-Ekiti (1978-1983).
- Lati kekere lo ti n gba ẹbun ọmọ to yege titi to fi gba oye imọ ijinlẹ akọkọ ninu ẹkọ ile kikọ ni Fasiti olódòdó ti Obafemi Awolowo (1989), ikeji ni Fasiti Eko (1993) ati ọmọwe ni OAU lọdun 2005.

Oríṣun àwòrán, @solaeleeka
- O ṣiṣẹ olukọni ninu imọ ijinle nipa ile kikọ ni Fasiti OAU ki wọn to yan an nigbakeji Gomina Ayodele Fayose lọdun 2014.
- O jẹ oluṣọagutan pẹlu ijọ Christ Apostolic Church nibi to ti jẹ ọkan lara awọn igbimọ alakoso wọn.
- O jẹ alaga ẹgbẹ awọn kọlekọle nipinlẹ Ọṣun lọdun 2006 si 2009 ati alakoso NIOB ni 2007 si 2009.

Oríṣun àwòrán, @pdp
- Ojọgbọn Oluṣọla lo n ṣamojuto eto ẹkọ ipinlẹ Ekiti labẹ Fayoṣe, eyi to mu idagbasoke ba àṣeyọri awọn akẹkọọ loriṣiiriṣi Ekiti lọdun 2016.
- O ti gba ami ẹyẹ pupọ nile, ati loke okun bii ti: Ami ẹyẹ Adari rere ni fasiti Pittsburgh USA, ami idanimọ fun iṣẹ rere ti fasiti Stanford University, America; ami ẹyẹ ògo lẹnu iṣẹ akanṣe ẹni ni fasiti Pittsburgh, America.
- O gbe Diakoni Janet Oluṣọla niyawo.
- Igbeyawo wọn ni èso ọmọ mẹta.











