Ìbò abẹ́nú PDP Èkìtì: Olújìnmí yẹ̀bá fún Adéyẹyè

Awọn aṣojú tí yóò kópa n fi orukọ silẹ

Oríṣun àwòrán, facebook/lere olayinka

Àkọlé àwòrán, Ètò ààbò gbópọn níbi tí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ti ń ṣètò ìdìbò abẹ́nú rẹ̀

Ètò ìdìbò ti bẹ̀rẹ̀ nílùú Àdó Èkìtì níbi tí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ti ń ṣètò ìdìbò abẹ́nú láti yan ẹni tí yóò gbé àṣìá ẹgbẹ́ òṣèlú náà, lásìkò ìdìbò sípò gómìnà ìpínlè ọ̀hún lóṣù keje odun yìí.

Ó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì àwọn aṣojú tí yóò kópa nínú ètò ìdìbò náà.

Àwọn olùdíje mẹ́ta, igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Ẹ̀kìtì, Olúṣọlá Eleka, Dayo Adeyeye tó fìgbàkan rí jẹ́ alukoro ẹgbẹ́ òṣèlú PDP pẹ̀lú Sẹ́nétọ̀ Abiodun Olujimo tó ń ṣojú ẹkún gúúsù ìpínlẹ̀ Èkìtì nílé aṣòfin àgbà, ló ń du àsìá náà mọ́ ara wọn lọ́wọ́.

Awọn aṣojú tí yóò kópa n fi orukọ silẹ

Oríṣun àwòrán, facebook/lere olayinka

Àkọlé àwòrán, Àwọn olùdíje mẹ́ta ló ń du àsìá náà mọ́ arawọn lọ́wọ́.

Sùgbọ́n ìròyìn tó ń tẹ̀ wá lọ́wọ́ báyìí ní, Seneto to n soju ẹkun idibo guusu Ekiti, Abiodun Olujimi, ti yẹ̀bá fun minisita tẹ́lẹ̀rí fun ọ̀rọ̀ isẹ́ lorileede Naijiria, Ọ́mọọba Dayo Adeyeye ninu idije sipo gomina ipinle Ekiiti.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Olujimi sọ wipe oun fi ipo naa silẹ lati gba alaafia laaye, ati fun igbeleke pelu itẹsiwaju ẹgbẹ oselu alaburada, PDP ni ipinle ekiti.

Olujinmi wa parọwa si awọn alatilẹyin rẹ lati fọwọsowọpọ pẹlu Ọ́mọọba Dayo Adeyeye lati lee yege ninu idibo si ipo gomina ti yoo waye ni ọjọ kẹrinla, osu kẹfa ọdun 2018.

Awọn aṣojú tí yóò kópa n fi orukọ silẹ

Oríṣun àwòrán, facebook/lere olayinka

Àkọlé àwòrán, Ó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì àwọn aṣojú tí yóò kópa nínú ètò ìdìbò abẹ́nú PDP

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé igbákejì gómìnà rẹ ni Fayose ń ṣàtìlẹyìn fún láti gba ipo rẹ̀, èyí ti fa ìkùnsínú láàárín àwọn olùdíje tí wọ́n ti fi ẹ̀họ́nú hàn lórí èyí.

Ìròyìn tó ń tẹ̀ wá lọ́wọ́ láti ibùdó ìdìbò abẹ́nú náà ní, ètò ààbò gbópọn nibẹ̀, eléyìí tó ṣeéṣe kó níí ṣe pẹ̀lú àbájáde irúfẹ́ ìdìbò abẹ́nú tí ẹgbẹ́ òṣèlú APC ṣe lọ́jọ àbámẹ́ta tó kọjá.