Ekiti Election: Ǹkan mẹ́wàà tó yẹ kí o mọ̀ nípa Ṣẹgun Adewale

Oríṣun àwòrán, @segunaeroland
Ṣẹgun Adewale, olùdíje fún ipò gómìnà l'Ekiti lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú ADP
- Ọ̀gbẹ́ni Michael Adewale ati Abilekọ Micheal Adewale ti agboole Aremọ bi Ṣẹgun Adewale lọjọ kẹẹdogun, oṣu karun un, ọdun 1966.
- O lọ sile iwe Seventh-day Adventist School, Abule Oja, ipinlẹ Eko (1972 si 1978); o pari iwe girama rẹ ni Oriwu College, Ikorodu lọdun 1983 o si gba oye keji nipa iṣakoso gbogboogbo ni Fasiti ipinlẹ Eko (1995).
- Ọdún 2012 si 2013 lo kẹkọ to tun gba iwe aṣẹ lati maa fo loke pẹlu Institute of Flight Operations and Dispatcher (IFOD), Texas ni America.

Oríṣun àwòrán, @actiondemocraticparty
- Otunba Ṣẹgun Adewale ni alaga ile iṣẹ Aeroland Group Companies.
- O darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party lọdun 2007.
- O dije fun ipo aṣojuṣofin lọdun 2011 ati ti Sẹnetọ lọdun 2015.
- Ọpọ èèyan lo maa n pe e ni Oṣaprapra nitori iwa ati ìṣe rẹ.
- Die lara awọn ami ẹyẹ rẹ̀ ni: BRITISH AIRWAYS: Best Travel Agency Awards lọdun 2005/6,VIRGIN ATLANTIC: Best Partner Award (2005),BRITSH AIRWAYS: Platinum Agent Award (2004/5),QATAR AIRWAYS: special travel partner award (2007/8) ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, @segunaeroland
- Otunba Adewale gbe Abilekọ Victoria Adewale niyawo.
- Wọn bi ọmọ meji: Tosin ati Tobilọba Adewale.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:












