Olùdije ipò gómínà ní Ìpínlẹ̀ Ekiti, Kole Ajayi, jáde láyé

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/BANKOLE AJAYI
Ọkan lára àwọn olùdíje tí ó kọkọ jáde fun ipò gomina lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlu APC ní Ipínlẹ̀ Ekiti fun ibò tí ó ń bọ lọna yìí, Kole Ajayi, ti jáde laye.
A gbọ́ pé olóògbé ẹni ọdún mọkànleláàdọ́ta náà ń lọ ṣe ìpàdé kan ni ilú Eko ní ọjọ Etì ni àárẹ̀ ba mu tí wọn sì gbe lọ ilé ìwòsan níbi tí ó ti gbẹ́mìí mì.
Akọ̀wé APC ní Ìpínlẹ̀ Ekiti, Taiwo Olatunbosun, ni ibanujẹ́ ńláálà ni iku reẹ̀ jẹ́ fun gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ náà ní Ekiti.
Olóògbé náà kọkọ jáde láti díje nínú ìdìbo abẹ́le tí ó kọjá yìí ṣugbọn, ìgbà tó yá, ó ní òun kò ṣe mọ, ó sì ṣe àtìlẹ́yìn fun gomina ìpínlẹ̀ náà nígbà kan rí, Kayode Fayemi tí ó jáwé olú bórí.








