Russia 2018: Ebola kò le di ìdíje Nigeria àti DR Congo lọwọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ láàrin ìkọ àgbà bóòlù Super Eagles pẹlú akẹgbẹ wọn lati ìlú DR Congo, to n bo lọna lo ti n kọ kan awọn ololufẹ ere bọọlu nínú.
Sugbọn ifoya awọn ọmọ Naijiria kii se lori boya Super eagles yoo bori idije naa, bikose ẹrù arun kogboogun níí, Ebola.
Ìtànkálẹ̀ ààrùn náà ti n tan kalẹ bii ọwara ojo ni orilẹede DR Congo, ti iye eniyan to ku sí ti to márùndínlọ́gbọ̀n.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ní ṣé ní awọn kan to sọrọ loju Twitter n fòyà pé ti àwọn àgba bóòlù DR Congo bà wá sí Nàìjíríà, ṣe wọn ko ni gbe àrùn náà wọlé.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ṣùgbọ́n Toyin Ibitoye, tó jẹ agbẹnusọ fún Super Eagles ni, kò sí ifoya.
Nínú ìfòrò wá ni lé nu wò pẹlú BBC Yorùbá, o ni ''àwọn ẹka ìjọba to n mojuto ìlera ati awọn Àjọ tí ó ń rí sí ìwọlé wọ̀de wa ní ṣepe láti rí pé wọn ṣe ayẹwo to kojú oṣuwọn fún àwọn agbaboolu to n bo fún ifẹsẹwọnsẹ náà.''
''Ọpọlọpọ awọn agbaboolu DR Congo kò gbe ile gẹgẹ bíi àwọn agbaboolu tiwa náà. Lati ìlẹ̀ òkéré ní won yóò ti wa''
Ẹ gbọ Toyin Ibitoye siwaju si:
Nípa igbaradi awọn agbaboolu Super Eagles, o ni Ibudo igbaradi to wa ni Uyo ni wọn yoo kọkọ gunlẹ si.
" Igbaradi yóò bẹrẹ ní ọjọ Ajé ni Uyo .Ti ifẹsẹwọnsẹ náà bá kú ọjọ meji, ni a o gbera lọ Portharcourt, Ti a ba sí pari idije naa, a lero ati se abewo si Aare Buhari''
Ninu awọn ifesewonse miran ti iko Super Eagles fẹ gba, lati gbaradi de ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé ni:
- England ati Nigeria - Ọjọ keji Osu kẹfa ni Ilu Oba
- Nigeria ati Czech - Ọjọ kẹfa Osu kẹfa lorileede Austria.













