Sasa Market Ibadan: "Ọja Ṣaṣa ti ṣi ṣugbọn..."

Awọn ontaja ninu ọja Ṣaṣa ilu Ibadan ti gbarata wi pe nnkan ko ti i fi bẹẹ bọ sipo to wa tẹlẹ botilẹ jẹ wipe wọn ti bẹrẹ sini na ọja naa pada.BBC Yoruba ṣe abẹwo si ọja naa l'owurọ Ọjọbọ a si ba pupọ ninu awọn to n taja nibẹ sọrọ.Lara awọn to n ṣe ọrọ aje ninu ọja naa ṣe alaye fun akọroyin wa wi pe lọọtọ ni wọn ti ṣi ọja pada, ṣugbọn nnkan ti wọn ju tẹlẹ lọ.
- Glaucoma lè fọ́ gbogbo ènìyàn lójú tán níbí - Dókìtà Nàìjírìà
- Fayemi ló tó gbangba sùn lọ́yẹ́ láti jẹ ààrẹ Nàìjíríà lọdún 2023- Àwọn lọ́balọ́ba Ekiti
- Ẹ gbọ́ ohun tí àwọn ọmọ Naijiria ń sọ lẹ́yìn tí àwọn ajìjàgbara Niger Delta ṣèlérí láti kọlu Eko àti Abuja
- Mo ń ṣe ẹ̀tọ́ mi fún Damilare lọ́dọ̀ màmá àgbà, àmọ́ ǹkan tí ẹ kò mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí ló pọ̀ - Mide-Funmi Martins

Ọkan ninu wọn ti a ri ni isọ ti wọn ti n ta alubọsa ṣe alaye wi pe ọwọngogo nnkan ti oun ta tẹlẹ lo sun oun de idi alubọsa nitori ọna atijẹ.Awọn ontaja naa fi kun ọrọ wọn wi pe gbogbo awọn ẹya Yoruba ati Hausa to fi ibẹru sa kuro ninu ọja naa ti n pada wa na ọja bayii, botilẹ jẹ wi pe ibẹru diẹ diẹ ṣi wa lọkan wọn.Bakan naa ni awọn ọkọ nla to n ko ọja bi i ata, alubọsa ati bẹẹ bẹẹ lọ lati Ariwa orilẹede yii ti pada sẹnu iṣẹ wọn. Awọn onibara lati ipinlẹ Ọyọ, Ogun ati awọn ipinlẹ mi i naa ko gbẹyin ninu ọja Ṣaṣa lasiko ti a ṣe abẹwo sibẹ.Awọn ontaja naa parọwa si ijọba lati mu ileri ṣẹ fun imubọsipo ọja naa.

Ita gbangba ni gbogbo awọn ti a ba ninu ọja naa ti n ṣe karakata wọn bayii nitori pupọ ninu awọn ṣọọbu ti wọn n lo tẹlẹ lo ti jona ninu rogbodiyan to ṣẹlẹ lọja naa.Awọn onikarakata kan ti o jẹ Hausa naa fi idi ọrọ mulẹ wi pe ọja ti ṣi lootọ ṣugbọn awọn ko ti i le sọ bi ọja ṣe ri nitori pe oni ni ọjọ keji ti ọja naa di ṣiṣi pada. Awọn to kọja nnkan ti wọn n ta lọ si ọja Bodija naa ti n pada si ọja Ṣaṣa ti wọn ti n ta ọja wọn tẹlẹ.

Ṣaaju ni Gomina Ṣeyi Makinde ṣe ileri wi pe ijọba ipinlẹ Ọyọ fi ọkọ itulẹ, Budosa ṣọwọ si ọja naa lati wo gbogbo awọn ṣọọbu to jọna palẹ ninu ọja naa.A ri apẹrẹ wi pe iṣẹ naa ti bẹrẹ lasiko ti a ṣe abẹwo sibẹ.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo Ṣeyi Makinde ti pàṣẹ pe ki ọjà Ṣaṣa di ṣíṣí padà

Gomina ipinlẹ Ọyọ Ṣeyi Makinde ti paṣẹ wi pe ki wọn ṣi ọja Ṣaṣa pada lẹyin ọsẹ melo kan ti wọn ti ọja naa pa.Makinde kede ọrọ yii lọjọ Iṣẹgun nibi ipade ti o ṣe ni gbọgan nla igbalejo "House of Chiefs" to n bẹ ni Agodi, ilu Ibadan pẹlu igun mejeeji ti o n ba ara wọn ja ninu ọja naa.Gomina ṣe alaye wi pe nitori eto ọrọ aje ati awọn nnkan mii to niṣe pẹlu ipinlẹ yii ni oun ṣe gbe igbesẹ naa.
- Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ìbálọ̀pọ̀ pẹ̀lú aya tàbí ọkọ rẹ lè jẹ́ kí o dàbí ọmọdé?
- 129,300 ló ti jàjà bọ́ lọ́wọ́ Covid-19 ní orílẹ́èdè Nàìjíríà
- Ìtumọ̀ orúkọ ọmọ Banky W àti àwọn ìtàn míràn nípa gbájúgbajà tọkọtaya naa
- Auxiliary àtàwọn míì gba ìwé ìyànsípò tuntun gẹ́gẹ́ bí ìjọba ìbílẹ̀ ṣe gba ìṣàkóso àwọn ibùdókọ̀ nípinlẹ̀ Oyo

Oríṣun àwòrán, Gov Makinde
O ni, "Ti a ba wo eto ọrọ aje ati bi nnkan ṣe ri fun wa, mo ti gbọ nnkan ti ẹ sọ, lẹsẹkẹsẹ si ni a o ṣi ọja naa pada. Wọn yoo gbe awọn ẹrọ itulẹ lọ si ọja naa lonii".Makinde tẹsiwaju wi pe, "Lasiko ti emi ati awọn arakunrin mi ti o jẹ Gomina ṣe abẹwo si aafin Seriki Ṣaṣa, nigba ti a n rin kaakiri mo ṣe akiyesi wi pe awọn eeyan ti a ri nibẹ ati awọn eeyan ti a pade ni ọdọ Baalẹ ni inu wọn ko dun nitori pe ọna ati jẹ ti di mọ wọn"."Ti ẹ ba wo ipinlẹ Ọyọ kodaa gan nigba ti aarun Corona de gongo, mo kọ lati ti awọn ọja wa nitori mo mọ pe nnkan ti pupọ eeyan ba ri lonii ni yoo sọ boya wọn a ri ounẹ jẹ lọla".












