Shasha Crisis in Ibadan: Gbọ́ ohun tó ṣokùnfà ìjà láàrin Aláboyún, soo bàtà àti Hausa alábárù ní Sasa

Àkọlé fídíò, Shasha Crisis in Ibadan: Gbọ́ ohun tó ṣokùnfà ìjà láàrin Aláboyún, soo bàtà àti Hausa alá

Kini Seriki Sasa se ninu ọrọ to ṣẹlẹ ni ọja yii?

Ile ati ṣọọbu ti jona tan, ko si aṣọ, ko si owo mọ- Ontaja

Dadi mi lo kọ ṣọọbu yii bẹẹ wọn joo tan lati oke de ilẹ ni- Oniṣọọbu to jona.

Gbogbo gilaasi ọkọ mi ni wọn fọ tan ti wọn tun jo ṣọọbu iyawo mi- ọkan lara awọn ti dukia rẹ bajẹ.

Awọn olugbe ọja Sasa ati awọn Ontaja nibẹ sọrọ pẹlu ibanujẹ lori awọn nkan ti wọn padanu ninu iaj Yoruba ati Hausa to waye nibẹ.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye ni kikun lori ohun to kọkọ ṣẹlẹ laarin alaboyun ati ọkunrin Hausa alabaru tomati ati Soo bata ọkunrin Yoruba ti o kọkọ ku ninu iṣẹlẹ naa fun BBC Yoruba.