Fani Kayode, Herdmen crisis: A tún lé àwọn Fulani kúrò ní Anglican School, Owode, Idiroko níbi tán ti fẹ́ ṣọṣẹ́- Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, others
Sunday Adeyemọ, oloye agba ti ọpọ n pe ni Sunday Igboho lo tun ti sọrọ soke ninu fọnran fidio kan to ṣẹṣẹ jade lẹyin ipade rẹ pẹlu oloye Femi Fani Kayode.
Lasiko ti Femi Fani Kayode n ṣabẹwo o kare si Sunday Igboho ni awọn ọrọ wọn yii jade sita.
Nigba naa ni Igboho mẹnuba bi oun ati awọn eeyan rẹ ṣe lọ le awọn afurasi Fulani oniṣẹ ibi kan ti wọn da ẹran wọ ile ẹkọ Anglican School ni Owode ni Idiroko ni ipinlẹ Ogun lọjọ kejidinlogun, oṣu keji, ọdun yii.
Nibẹ ni Sunday ti ni awọn gba ipe lasiko ti wọn n kọja ti awọn si lọ le awọn Fulani naa kuro nibẹ.
- Sunday Igboho sọ̀rọ̀ lórí ohun tó kan fún ilẹ̀ Yorùbá lọ́dún 2021
- N kò jà fún ìṣọ̀kan Yorùbá láti wá ipò tàbí orúkọ - Sunday Igboho
- Seyi Makinde lo ṣí ilé mi tó jóná pẹ̀lú ‘transformer 500kva’ - Sunday Igboho
- Àwọn jàǹdùkú yìnbọn sókè lọ́pọ̀ ìgbà kí wọn tó jó ilé Sunday Igboho - Ọlọ́pàá Oyo
- Sunday Igboho ṣọ́ra ṣe, jẹ́ kí Seyi Makinde ṣiṣẹ́ tí òfin gbé le lọ́wọ́ - Ooni Ife
- Ọ̀gá àgbà ilé-iṣẹ́ aṣọ́bodè (Customs) tẹ́lẹ̀ tó kú tí wọ́n fẹ̀sùn kíkó ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ bílíọ̀nù jẹ kan
- Àwọn obìnrin mánigbàgbé tó ti kópa nínú sáà ìjọba tiwantiwa láti ọdún 1999
Sunday Igboho salaye pe ọrọ Oloye Obafemi Awolowo, baba Yoruba ninu oṣelu ni oun n tẹle.
O ni Awolowo ti ni pe nigba ti asiko ba to, awọn ọdọ yoo dide fun ominira, wọn yoo si ja funra wọn.
Sunday Igboho tun mẹnuba awọn eekan agba Yoruba ti wọn wa lẹyin rẹ ki ija ilẹ Yoruba le yọri.
Lara awọn to darukọ ni Oloye Ayo Adebanjo, Oloye Akintoye, Oga agba ọlọpaa fẹyinti Tunde Alapinni ati awọn miran pe wọn fi da oun loju pe mimi kan ko le mi oun.
- Oríṣìí àrùn mẹ́jọ tó máa ń ṣáábà mú aláboyún rèé
- Ọkùnrin kan gún olólùfẹ́ rẹ̀ lọ́bẹ lórí N85,000 lẹ́yìn tó kọ̀ láti ṣèyàwó pẹ̀lú rẹ̀
- Wo ìgbà mẹ́rin táwọn agbébọn ti jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé nílé ẹ̀kọ́ wọn ní Nàìjíríà
- Ọ̀pọ̀ èèyàn lórí ayélujára dá Shina Peters lẹ́bi lórí ọ̀rọ̀ ọmọ tí Funmi Martins bí kó tó kú
- Àwọn Olùkọ́ Yorùbá ní ìlú Ondo fọkọyọ lórí ètò Akọ́mọlédè àti Àṣà lórí BBC Yorùbá
- Fáàbàdà! Ìjọba ò sanwó fáwọn ajínigbé láti fi àwọn akẹ́kọ̀ọ́ iléèwé Kagara sílẹ̀- Lai Mohammed

Oríṣun àwòrán, @ondomagazine
Ẹ̀yin ọmọ Yoruba, ẹ dáàbò bo ara yín lọ́wọ́ àwọn jàǹdùkú tó ń kọlù yín - Sunday Igboho
Ó yẹ kí ará ìlú lè dáàbò ara wọn tí àwọn darandaran bá lè máá gbé AK47 rìn kiri - Fani-Kayode
Femi Fani-Kayode ba awọn akọroyin sọro lẹyin to ṣabẹwo si Sunday Igboho niluu Ibadan.

Oríṣun àwòrán, others
Ajafẹtọọmọniyan, Oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ti rọ awọn ọmọ Yoruba lati dabo bo ara wọn lọwọ awọn janduku to n fi ẹmi wọn ṣofo.
Igboho lo sọ ọrọ naa lasiko ti minisita fun eto irinna ọkọ ofurufu tẹlẹri ati eekan ẹgbẹ oṣelu PDP, Femi Fani-Kayode ṣabẹwo si nilẹ rẹ to wa ni Soka, niluu Ibadan.
Ajafẹtọọmọniyan ọhun sọ pe ohun kan sọṣo ti oun n fẹ ni alaafia nilẹ Yoruba.
Lẹyin ipade idankọnkọ oni wakati mẹta pẹlu minisita tẹlẹ naa, Igboho ni "mi o ni ọrọ kankan lati sọ bayii, ẹgbọn mi, iyẹn Fani-kayode, ti sọ gbogbo ọrọ to yẹ ki n sọ."
"Ohun ti a n fẹ nilẹ Yoruba ni alaafia, a kọ fẹ awọn janduku, a ko fẹ ki awọn Fulani maa pa awọn eeyan wa, a fẹ ki awọn eeyan wa wà ní ominira."
Igboho tẹsiwaju pe "ọrọ mi si awọn ọmọ Yoruba ni pe ki wọn dabo ara wọn lọwọ awọn to n pa wọn.
- Àwọn obìnrin mánigbàgbé tó ti kópa nínú sáà ìjọba tiwantiwa láti ọdún 1999
- Ìjọba ti ileẹ̀kọ́ pà lẹ́yìn tí àwọn jàndùkú ṣèkọlù sí Osogbo, ìpínlẹ̀ Osun
- Irọ́ ni pé wọ́n ti fi àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Kagara sílẹ̀- Gomina ìpínlẹ̀ Niger
- Ṣé lóòtó ni ilé-iṣẹ́ ológun gbé hẹlikópítà ìjagun lọ si Orlu ní ìpínlẹ̀ Imo?
- Alhaja Muslimot Salami tí àwọn darandaran kọlù ní Ogun tí padà jẹ́ Olorun nípè!
"Ẹ ma ṣe gba ẹnikẹni laaye lati wa pa yin ninu ile tabi oko yin, eyii si wa lara ọrọ ti minisita ti sọ ṣaaju."
Nigba to n sọrọ lẹyin ipade naa, Fani-Kayode ni oun ko faramọ ohun ti gomina ipinlẹ Bauchi, Bala Mohammed sọ nigba to sọ pe o yẹ ki ijọba apapọ fun awọn Fulani darandaran lanfani lati maa gbe ibọn Ak47 lati dabo bo awọn maalu wọn.

Oríṣun àwòrán, Isokan Omo Yoruba
Fani-Kayode ni, ti awọn Fulani ba lanfani lati maa gbe ibọn AK17 rin kiri, o yẹ ki awọn ara ilu naa le ni anfani lati dabo bo ara wọn lọwọ awọn darandaran to dukoko mọ wọn.
O ni "mo faramọ pupọ ki awọn eeyan maa gbe ibọn fun abo ara wọn, ṣebi wọn n ṣeru ẹ l'Amẹrika, o si wa ninu ofin wọn."
"Boya ti a ba tilẹ n gbe ibọn fun abo ara wa, o ṣeṣe ko ma si irufẹ awọn akọlu to n waye lemọlemọ yii."
Nigba to n sọrọ lori abẹwo rẹ si Igboho, Fani-kayode ni oun bẹẹ wo lati dupẹ lọwọ rẹ fun iṣẹ akin to n ṣe lori ilẹ Yoruba lai tẹ ofin loju mọlẹ.
O fi kun pe oun bẹ Igboho wo lati fidi rẹ mulẹ pe ija rẹ kii ṣe pẹlu awọn Fulani, bikoṣe pẹlu awọn ọdaran to wa laarin awọn Fulani darandaran ọhun.

Oríṣun àwòrán, @Sunday
Mo dúpẹ́ fún N6.5 mílíọ̀nù owó mọ̀tò tí ẹ fún wa- Sunday Igboho
Sunday Adeyemo ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho ti fi imoore han si awọn iran Yoruba loke okun.
O dupẹ pupọ lọwọ wọn fun bi wọn ṣe ṣatilẹyin fun oun ati iran Yoruba nipa did owo to ti pe miliọnu mẹfa ataabọ naira lati fi ra mọto.
O ni Yoruba Nation's Security in Diaspora gbiyanju gidi laisko ọgbẹlẹ yii lati ko owo naa jọ.
- '' Ìrọ ní ò, N51.8million kọ́ ní àwọn Naijiria dá fún Sunday Igboho, N4milion ní''
- Bukola Saraki sọ̀rọ̀ sókè lórí ìgbésẹ̀ Sunday Igboho
- Ṣé ìyàwó ilé tàbí àlè níta ló yé kí ọkùnrin lo 'Valentine' rẹ̀ pẹ̀lú?- Mercy Aigbe
- Wọ́n ti kéde Ngozi Okonjo Iweala gẹ́gẹ́ bíi alákóso WTO
- Mo ṣetán láti tún àwọn ilé tó jóná ní ọjà Sasa kọ́- Makinde
- Àwọn darandaran gbẹ̀mí èèyàn mẹ́ta níjọba ìbílẹ̀ Ariwa Yewa lẹ́yìn àbẹ̀wò àwọn aṣojú ìjọba ní ìpínlẹ̀ Ogun
Bakan naa ni Sunday Igboho tun ṣeileri lati fi tọkan tara ṣiṣẹ titi Yoruba yoo fi ni alaafia, ominira ninu eto aabo ati isinmi.
Sunday Igboho fi tọkan tọkan ṣadura fun awọn ọmọ Yoruba ni oke okun to da owo naa pe wọn a ko ere oko dele.
Bakan naa lo tun ki wọn ku aduroti pe oun ko ni doju ti wọn rara lori ọrọ Yoruba.
























