Abdullahi Dikko Inde: Wo ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu tí wọn fi kan ọ̀gá àgbà ilé-iṣẹ́ aṣọ́bodè tó kú

Oríṣun àwòrán, @Preseidency
Ọ̀gá àgbà ilé-iṣẹ́ aṣọ́bodè(Customs) tẹ́lẹ̀ tó kú tí wọ́n fẹ̀sùn kíkó ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ bílíọ̀nù jẹ kan
Ọpọ eeyan lo n ṣe idaro ọga agba ileeṣẹ aṣọbode orilẹ ede Naijiria tẹlẹ, Abdullahi Dikko Inde to jade laye.
Koda Igbakeji Aarẹ Naijiria nigba kan ri, Atiku Abubakar darapọ mawọn to n ṣedaro Inde to ku l'Ọjọbọ, ọjọ kejidinlogun oṣu keji ọdun 2021 yii.
Dikko Inde jade laye lẹni ọdun mọkanlelọgọta gẹgẹ bi ileeṣẹ aṣọbobe Naijiria ti ṣalaye.

Oríṣun àwòrán, @NigeriaCustom
Iroyin kan tiẹ sọ pe Inde papoda nile iwosan kan niluu Abuja nibi to ti n gba itọju lẹyin ti o ṣaarẹ.
Ẹwẹ, ọga agba ileeṣẹ aṣọbode Naijiria n jẹjọ lọwọ lori ẹsun iwa ajẹbanu ṣáájú iku rẹ.
Lara ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o ko ẹgbẹlẹgbẹ biliọnu owo naira to jẹ owo ijọba jẹ nigba to wa lori aleefa gẹgẹ bi ọga agba ileeṣẹ aṣọbode Naijiria.
- Ẹ̀yin ọmọ Yoruba, ẹ dáàbò bo ara yín lọ́wọ́ àwọn jàǹdùkú tó ń kọlù yín - Sunday Igboho
- Àwọn obìnrin mánigbàgbé tó ti kópa nínú sáà ìjọba tiwantiwa láti ọdún 1999
- Ìjọba ti ileẹ̀kọ́ pà lẹ́yìn tí àwọn jàndùkú ṣèkọlù sí Osogbo, ìpínlẹ̀ Osun
- Irọ́ ni pé wọ́n ti fi àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Kagara sílẹ̀- Gomina ìpínlẹ̀ Niger
- Ṣé lóòtó ni ilé-iṣẹ́ ológun gbé hẹlikópítà ìjagun lọ si Orlu ní ìpínlẹ̀ Imo?
Ajọ ICPC to n gbogun ti iwa ibajẹ lawujọ lo kọkọ gbe Inde lọ si ileẹjọ lori iwa ajẹbanu.
Lẹyin naa ni ajọ EFCC gba ọkọ bọginni mẹtadinlogun lọwọ Dikko nibi to ko wọn sì nile rẹ ni Kaduna lọdun 2017.
Ṣugbọn lọdun 2019, adajọ Nnamdi Dimgba ileẹjọ giga niluu Abuja pàṣẹ pe ki ajọ EFCC da ẹjọ ti o pe Inde duro lẹyin ti minisita eto idajọ, Abubakar Malami ati Inde buwọlu iwe adehun lati pari ẹjọ ọhún.
Iroyin kan sọ pe Dikko da biliọnu kan ati abọ pada fun ijọba lara owo to ko jẹ ni wọn pè e.
Amọ, loṣu keji, ọdun 2020, ileẹjọ giga ijọba apapọ kan l'Abuja tun paṣẹ pe ki wọn lọ gbe Inde pada nitori ko wá sí ile ẹjọ mọ.
Ṣugbọn agbẹjọro rẹ, Solomon Akuma fi iwe ẹri ile iwosan hàn pe Inde n ṣe aisan ni ko jẹ ko lanfaani lati wa sile ẹjọ.
Agbẹjọro Inde tun sọ pe o wa nile iwosan niluu London nibi to ti n gba itọju.
- Wo ẹ̀bùn owó tabua tí gbajúgbajà oníṣòwò kan fún bàbá "Lórí Irọ́"
- Ṣé lóòtọ́ ni omidan yìí ya wèrè ní kété tí ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ ní òun fẹ́ fi ṣaya?
- Akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá mú ìbọn ìléwọ́ lọ ilé ìwé láti yìín lu olùkọ́ tó ní kó gé irun orí rẹ̀
- Kí ló mú kí géńdé Olorun fi àfọ́kù ìgò gé ǹkan ọmọkùnrin rẹ̀ ní Kano?
- Ìjọba Naijiria ti kùnà lórí ojúṣe rẹ̀ lóri ètò aàbò- Bode George
- Ọwọ́ pálábá Abubakar, mọ́káliíkì ségi níbi tó ti fẹ́ jí ọkọ̀ gbé l'Abuja















