Fulani herdsmen: Ìjọba Naijiria ti kùnà nínú ojúṣe rẹ̀ lóri ètò aàbò- Bode George

Oríṣun àwòrán, @DailyPostNGR
Eekan ẹgbẹ oṣelu PDP, oloye Bode George ti bu ẹnu ẹtẹ lu ọwọ ti ijọba apapọ fi mu eto abo to mẹhẹ ni Naijiria.
George lo sọ ọrọ naa nibi ipade awọn akọroyin kan to waye ni ile rẹ to wa niluu Eko.
O ni "Pẹlu iyalẹnu ni mo fi n wo gbogbo ohun to n ṣẹlẹ ni Naijiria lẹnu ọjọ mẹta yii."
- A kò tíì gbọ́ pé ilé ẹjọ́ wọ́gilé gbígba owó lọ́wọ́ àwọn dẹ́rẹ́bà ni ibudokọ ipinlẹ Oyo- awọn Awakọ̀
- Akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá mú ìbọn ìléwọ́ lọ ilé ìwé láti yìín lu olùkọ́ tó ní kó gé irun orí rẹ̀
- Alhaja Muslimot Salami tí àwọn darandaran kọlù ní Ogun tí padà jẹ́ Olorun nípè!
- Àìṣàtìpó rí ló ń da Ejiogbe láàmú, àsìkò ìjọba tèmi ló dé- Alhaji Mukaila Auxilliary
"Ko si aabo mọ lawọn opopona Naijiria, ni ṣe lo si da bi pe ko si ijọba mọ ni Najiria.
Ajagunfẹyinti naa sọ pe inu ibẹrubojo lawọn eeyan fi rinrin ajo lati awọn ipinlẹ kan si omiran bii, Sokoto si Eko, Ebonyi si Bornu, Katsina si Ogun, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
O ṣalaye pe ojojumọ ni wọn n ge ẹmi awọn eeyan kuru ti wọn si n ji ọpọlọpọ gbe ṣugbọn ijọba ko ri nkankan ṣe sii.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, "ojuṣe ijọba ni lati dabo bo ẹmi ati dukia awọn eeyan ilu, ṣugbọn ijọba Naijiria ti ba ojuṣe rẹ ku ninu awọn nnkan wọnyii."
Bode George ni ko si alaafia laarin ilu to bẹ ti awọn baba isalẹ ti ni agbegbe ti wọn n ṣakoso, ti nkankan ko si ti ẹyin jade.
Ni ti iwọde EndSARS to waye lọdun 2020, Bode George sọ pe ko tii to asiko fun ijọba ipinlẹ Eko lati ṣi iloro Lekki Toll Gate pada nitori ẹmi awọn eeyan to sọnu logunjọ, oṣu Kẹwaa nibẹ.
Lẹyin naa lo ke si Aarẹ Muhammadu Buhari lati gbẹsẹle bi awọn darandaran ṣe maa n da maluu laarin ilu, bi bẹẹ kọ, ija lemọlemọ laarin awọn agbẹ atawọn darandan naa ko le wa sopin.
- Wo ẹ̀bùn owó tabua tí gbajúgbajà oníṣòwò kan fún bàbá "Lórí Irọ́"
- Mínístà, Kọ̀wé fipò rẹ sílẹ̀ tàbí kí o dákẹ́ tí ò kó bá wá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó sọnù- ọmọ Nàìjíríà
- Philip ẹni ọdún 99 tó jẹ́ ọkọ Ọbabìnrin Elizabeth ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ nílé ìwòsàn
- Wo iye kọ́ńdọ́mù táwọn ọmọ Nàìjíríà fi ń ṣara rindin lọ́dún
- Ìjì òtútù pa èèyàn 21 ní Amẹ́ríkà, ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ míràn ń dojúkọ ìṣoro àìsíná ẹ̀lẹ́ńtíríkì
- Gbenga Daniel kò ṣẹ̀ṣẹ̀ kúrò ní PDP, ó kàn fi ẹ̀ka APC kan sílẹ̀ lọ sí òmíràn ni- PDP














