Prince Philip: Ọkọ Ọbabìnrin Elizabeth ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ nílé ìwòsàn

Oríṣun àwòrán, PA Media
Duke Edinburgh, Ọmọba Philip to jẹ ọkọ Ọbabinrin Elizabeth ilẹ Gẹẹsi ti n gba itọju lọwọ bayii nile iwosan lẹyin ti ara baba fẹ ṣe diẹ.
Ọjọ Iṣẹgun ni wọn gbe Phillip to jẹ ẹni ọdun mọkandinlọgọrun de ile iwosan gẹgẹ bi aafin Buckingham ṣe ṣalaye.
Atẹjade ti aafin Buckingham fi sita sọ pe ile iwosan Oba Edward VII laarin gbungbun ilu London ni wọn gbe Phillip lọ.
Atẹjade naa tun sọ pe dokita lo ni ki Phillip duro nile iwosan fun itọju.
Iroyin ti BBC gbọ ni pe Duke Edinburgh ti n ṣojojo fun igba diẹ, amọ ailera rẹ ko ni ṣe pẹlu arun covid-19.
Ṣugbọn iroyin lati aafin Buckingham sọ pe ara Phillip ti yoo pé ẹni ọgọrun ọdun loṣu kẹfa, ọdun 2021 yii ti n balẹ.
Amọ, awọn dokita ni Philip yoo lo ọjọ bi melo kan nile iwosan lati le sinmi daadaa ati pe ki awọn dokita le lanfaani lati ṣe ayẹwo rẹ finni finni.
Ẹwẹ, Ọbabinrin Elizabeth ẹni ọdun mẹrinlelaadọrun si n ba iṣẹ lọ laafin Windsor Castle ni tiẹ.
Koda Ọmọba Charles naa ko gbẹyin, l'Ọjọru ọsẹ yii lo ṣabẹwo si ile iwosan Queen Elizabeth ni Birmingham nibi to ti bawọn oṣiṣẹ eleto ilera at'awọn alaisan sọrọ.













