Queen Elizabeth and Nigeria at 60: Obabinrin Elizabeth kí Nàìjíríà kú oríire òmìnira ọgọ́ta ọdún

Ọbabinrin Elisabẹti Keji

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Obabainrin ilẹ Gẹẹsi, Obabinrin Elizabeth keji kí Nàìjíríà kú oríire òmìnira ọgọ́ta ọdún

Obabainrin ilẹ Gẹẹsi, Obabinrin Elizabeth keji ti ransẹ ikinni si Aarẹ Muhammadu Buhari lori ajọdun ominira ọgọta ọdun ti Naijiria n se laarọ ọla.

Ileesẹ ilẹ Britiko to wa ni Naijiria, British High Commission lo gbe isẹ oriire na wa fun Aare Buhari

Ogbeni Femi Adesina to jẹ oluranlọwọ pataki fun Aare Buhari lo fi ikinni naa lede fun awọn akọroyin.

Lara ohun ti Obabinrin Elizabeth sọ ni pe: " Pẹlu ayọ ati inu didun ni m fi ki Naijiria ku oriire ọgọta ọdun lẹyin ominira.

Mo gbadura ilọsiwaju sii fun orile-ede Naijiria.

UK ati Naijiria ni ajọsepọ to dan mọran ti awọn mejeeji si jọ n se anfani fun ara wọn.

Itan awa mejeeji jọ ara wọn, bẹẹ naa si ni awọn eeyan wa jọ ara wọn.

Mo gbagbọ pe ki ajọsepa yii tun tẹsiwaju lọjọ iwaju".

Ojọ̀ kinni, osu kẹwaa, ọdun 1960 ni Naijiria gba ominira

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC: Kí ní ìtúmọ̀ Sílébù àti àmi ohun tó ń fún ni?