98 years improsonment for First Bank staff : Oreoluwa Adesakin tó jẹ́ òsìsẹ́ First Bank tẹ́lẹ̀ ni adé ẹ̀wọ̀n sí mọ̀ lórí nílé ẹjọ́ gíga Ibadan

Oríṣun àwòrán, Efcc
Oreoluwa Adesakin to jẹ osisẹ ile ifowopamọ First Bank tẹlẹ ni wẹn ni ko lọ fi ọdun mejidinlọgọrun jura lẹwọn.
Ile ẹjọ giga ipinlẹ Oyo ti ni ki Oreoluwa Adesakin lọ lo ọdun mejidinlọgọrun lẹwọn lori ẹsun jiji owo.
Oreoluwa Adesakin jẹ osisẹ First Bank tẹlẹ ki ọwọ to tẹẹ pe o sẹ jibiti owo to le diẹ ni milionu mọkandinlaadọta naira.
Adajọ Muniru Olagunju lo se idajọ naa lẹyin igbẹjọ, ti wọn tun ti ni arabinrin naa ji owo dọla ilẹ America to din diẹ ni aadọrin le ni ọọdunrun dọla to jẹ ti First Bank eyi ti Oreoluwa da sapo ara rẹ.
Adari ẹka ifitonileti fun ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu, EFCC ni Naijiria, Wilson ??uwujaren salaye bi won se gbe Oreoluwa ni ẹka EFCC to wa ni Ibadan lori ẹsun mẹrinla naa.
Lati osu karun un , ọdun 2013 ni arabinrin Adesakin ti n ji awọn owo yii ki ọwọ to tẹẹ pẹlu ẹri to daju lati ọdọ ajs EFCC ninu iwadii wọn.
Bayii ti ile ẹjọ́ ti ni Oreoluwa Adesakin jẹbi awọn ẹsun naa, yoo lo ọdun mejidinlọgọrun un lapapọ ni ọgba ẹwọn leralera wọn ni eyi ti yoo fi lo ẹdun meje papọ laigba ona abayọ owo itanran rara.
Yatọ si lilọ sẹwọn, wọn ni Adesakin yoo tun da gbogbo owo to ji ko pada fun ile ifowopamọ First Bank.
Lati ọdun 2014 ni wọn ti bẹrẹ ẹjọ naa ki Adajọ to pari rẹ bayii.
Iwadii ajọ EFCC fihan pe arabinrin ọdaran naa ninu owo naa lati fi ra ile lorisiirisii ati ilẹ kaakiri ipinlẹ Oyo ni eyi ti ọwọ ofin si ti ba bayii.
















