Ayuba Sarafa, Olọ́kadà kan tó jẹ́ eni ọdún 22 pokùnso ní Ibadan

Okun ipokunso kan

Oríṣun àwòrán, Nigeria lawyer

Iroyin naa ni ile akoti kan ni agbegbe Amuloko ni Ayuba Sarafa pa ara re si

Ẹgb ile aburo baba Ayuba ni wón ti ba oku ré nigba ti Arabinrin Nike to je iya rẹ wa a lọ si ibẹ.

Ayuba Sarafa to jẹ ẹni ọdun mejilelogun ni wọn ni o pokunso sile akọti kan no agbegeb Amuloko nilu Ibadan ni ijọba ibilẹ Ọna Ara nipinlẹ Ọyọ.

Aburo Baba rẹ, Ogbẹni Kazeem tijani ni won ni ọkan rẹ ko balẹ lati aaro ọjọ Alamisi ti wọn ti n wa Ayuba pe o jade, ko de pada wa sile lalẹ gẹgẹ bii ise rẹ.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC: Kí ní ìtúmọ̀ Sílébù àti àmi ohun tó ń fún ni?

Ọgbẹni Kazeem ni lẹyin ọpọ igba ti foonu Ayuba ti n dun ni awọn kan gbọ ninu ile akọpati naa ti wọn si rii to ti pokunso sibe pẹlu foonu rẹ lapo rẹ.

Koda, wọn ri bata salubata to wọ kuro nile pẹlu ọra to di bisikiiti, Sinsin, asọ awọtẹlẹ tuntunkan, asọ ilewọ to fi n se ibomu, ati awọn nkan pẹẹpẹẹpẹ miran nibẹ, lẹyin eyi ni wọn ti fi to awọn ẹbi leti ni Apomu.

Awọn ẹbi sapejuwe Ayuba pe kii jẹ gbese nidi ọkada to gba lawin to si n san owo rẹ ni san diẹdiẹ.

Ógbẹni Kazeem ni ọdọ oun ni Ayuba n gbe lati bii sdun mẹta sẹyin nibi to ti n ba oun sisẹ ko to lọ gba awin ọkada naa.

Wọn ni gbogbo iyara Ayuba ni wọn ti tuwo sugbọn ko si lẹta ipokunso tabi ti idagbere nibẹ rara.

Ogbẹni Tosin James to jẹ alaga ẹgbẹ awọn ọlọkada ni Amuloko sapejuwe Ayuba bi ọdọmọkunrin ti ara rẹ balẹ ti kii ja.

O ni kete to ba ti san owo rẹ tan lo maa n rẹrin ni eyi to jẹ ki iku rẹ ya gbogbo awọn eeyan lẹnu ni gareeji ọkọ

Ogbẹni James ni Ayuba ra ọkada naa ni N390,000 o si ti fẹ san owo rẹ tan nitori pe N77,000 pere lo ku ti ayuba maa san.

Awon ọlọpaa ni wan maa se iwadii bi o ti yẹ ki wan le fi enu ọrọ iku Ayuba jona sojukan sugbọn awọn ara gareeji lorisirisi lo n gabdura ki Olorun tu ẹbi Ayuba ninu.

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Aṣa: Ọ̀rọ̀ Ẹ̀yán ni Bunmi Femi Amao ń kọ́ wa lórí ètò Akọ́mọlédè àti Àṣà lóri BBC Yoruba