BB Naija: Kí ló pa Elisha Abbo, Leycon àti Naira Marley pọ̀, tí àríyá yóò fi wáyé?

Inu ẹni kii dun, ka pa mọra ni ọrọ awọn ololufẹ Olalekan Agbeleshebioba, ti sps eeyan mọ si Leycon, to gbegba oroke ninu asekagba idije BB Naija fun tọdun 2020.
Idi ni pe Senator to n soju ẹkun idibo Ariwa Adamawa, Elisha Ishaku Abbo ti kede pe oun fẹ se apejẹ ati ayẹyẹ idawọ idunnu pẹlu Leycon to jawe olubori naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ṣó yẹ kí akẹ́kọ̀ọ́ tàbùkù mi torí mo ya ‘Tatoo’ sí gbogbo ara?- Olùkọ́ yarí
- Miyetti Allah ní kí wọn wọ́gilé Amotekun, Sunday Igboho yarí
- Lẹ́yìn ọgọ́ta ọdún tí Nàíjíríà gba òmìnira, wo ipò tí àṣà àti èdè Yorùbá wà
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ tọkọ-taya àti èèyàn méjì míì tó gé orí òkú ní Ibojì
- Ẹ kíyèsára! Ògiri tó gbé Nàíjíríà ró ń mì tìtì, ó sì le wó - Osinbajo figbe ta
- Laycon, kú oríire àmọ́ bá ń kó owó orí nínú ẹ̀bùn rẹ nílé BB Naija - Ìjọba Eko
Ninu fidio kan to gba ori ayelujara kan bayii, ni Sẹnatọ Abbo ti kede pe, nitori oun se agbatẹru fun Leycon, o di dandan ko jawe olubori ninu idije naa.
"Gbogbo ẹyin ololufẹ Leycon, ẹ sunmọ lonii bi ka dijọ se ariya. Mo ti sọ fun yin pe Lecon n gbe owo ile BB Naija bọ wa sile, o si ti de bayii.
Nitori naa, ẹyin ti Naira Marley, nibo lẹ wa? O ya, a n lọ silu Eko lọ se ariya, Naira Marley, o ya sunmọ ibi, jẹ ka ls se ariya fun Lekan ooooo."
Bẹẹ ba si gbagbe, Sẹnatọ Abbo yii ni ẹnu n kun lati ọdun to kọja lori ẹsun pe o lu obinrin kan ninu ile itaja, ti fidio naa si gba ori ayelujara kan.
Amọ ọjọ Aje ni iroyin gbalẹ pe, ile ẹjọ giga ilu Abuja ti ni ki Sẹnatọ Abbo yii lọ san miliọnu lọna aadọta naira fun obinrin naa, ti Abbo fiya jẹ.
Lẹyin wakati mẹrinlelogun ti idajs naa waye, ni akọtun fidio miran tun lu sori ayelujara ninu eyi ti Sẹnatọ Elisha Abbo ti n kesi Naira Marley pe kawọn lọ silu Eko, ls se ariya fun Lekan.
Ibeere ti ọpọ eeyan wa n beere ni pe, ki lo pa Sẹnatọ Elisha Abbo, Naira Marley ati Lekan pọ?
Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí Sẹ́nétọ̀ Elisha Abbo san N50m fún obìnrin tó fìyà jẹ

Oríṣun àwòrán, Punchng
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe, ile ẹjọ giga ilu Abuja, to wa ni Maitama, ti dajọ pe ki sẹnetọ to n ṣoju ẹkun idibo Ariwa Adamawa, Elisha Abbo, san aadọta miliọnu Naira, gẹgẹ bi owo itanran, fun oṣiṣẹ ile itaja kan to fi iya jẹ.
Oṣu karun-un, ọdun 2019 ni fidio kan jade sori ayelujra, to si ṣafihan bi Sẹnetọ Abbo ṣe n ko igbaju, igbamu fun obinrin kan ni ṣọọbu ti wọn ti n ta awọn eroja ibalopọ nilu Abuja.
Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo koro oju si ihuwasi sẹnetọ naa.
Eyi mu ki ọrọ naa de ileeṣẹ ọlọpaa, ti wọn si kọkọ gbe e lọ si ile ẹjọ majisireti kan ni agbegbe Zuba, nilu abuja.
Ṣugbọn, adajọ ile ẹjọ naa, Abdullahi Ilelah, wọgile ẹjọ naa, lẹyin ti Abbo kọwe pe oun ko ni ẹjọ kankan latiu jẹ.
Arabinrin naa, Osinibibra Warmate, pẹlu iranlọwọ awọn agbẹjọro rẹ, pe ẹjọ miran si ile ẹjọ giga ilu abuja, ti wọn si fi ẹsun kan Sẹnetọ Abbo pe o tẹ ẹtọ rẹ mọlẹ.
Onidajọ ile ẹjọ giga naa, Samira Bature si ti dajọ pe ki Sẹnets Abbo san miliọnu lọna aadọta Naira fun arabinrin Warnate, lati fi tu u ninu.














