Elisha Abbo: Ẹ̀sìn àti ẹ̀kọ́ ilé tí mo ní kò gba ká na obìnrin

Oríṣun àwòrán, @ElishaCliff
Sẹnetọ Elisha Ishaku Abbo, ti fidio ori ayelujara kan gbe jade pe o na obinrin abilekọ kan nile itaja ti tọrọ aforijin lọwọ awọn orilẹede yii, awọn abiyamọ, ati obinrin to na pe ki wọn fi ori jin oun, oun ko ni hu iru iwa aidaa bayii mọ.
Abbo tọrọ aforojin yii pẹlu ikaanu nla, lasiko ipade akọroyin to se ni olu ile ẹgbẹ PDP to wa nilu Abuja.
Asofin ẹgbẹ PDP naa, to tọrọ aforijin pẹlu lọwọ ẹgbẹ oselu rẹ, awọn mọlẹbi, ọrẹ tun mẹnuba pe, iwa bayii se ajeji si oun lati ẹyin wa, ti oun si kabamọ fun iwa toun hu yii, lainaani ohun to bi oun ninu lati se bẹẹ.
Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:
- 'Ẹwọn ọdun mẹẹdọgbọn ko pọ ju fun afipabanilopọ'
- Damasus, Omotola, Ezekwesili, Funmi Iyanda dá sí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ Fatoyinbo
- Ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀: Orí Twitter ló ti bẹ̀rẹ̀, ikú ló já sí
- COZA: Mi ò fípá bá obìrin lò pọ̀ rí láyé mi - Pásítọ̀ Fatoyinbo
- Ààrẹ fi nǹkan ọkùnrin rẹ̀ pa mí lójú, kó tó fipá bámi lòpọ̀ - Ọmọge Arẹwà
O wa rawọ ẹbẹ si tọkunrin-tobinrin ọmọ orilẹede yii lati wa aaye ninu ọkan wọn fi fori jin oun nitori eniyan lo n dẹsẹ, Ọlọrun si lo maa n fori jin ni.
Abbo, to ni ọmọ kii mọ ẹkọ jẹ ko ma ra lọwọ, tun tọrọ aforijin lọwọ ijọ Ọlọrun lagbaye lori iwa aidaa ti oun hu yii, nitori o ni gẹgẹ bii asoju Kristi, iru iwa yii ko tọ si oun.
Bakan naa lo fikun pe itọni ti oun gba ninu ile ati ijọ Ọlọrun ko fọwọsi iru iwa yii, nitori idi eyi, oun tọrọ idarijin niwaju Ọlọrun ati awọn eeyan ti iwa oun yii ti jẹ ẹdun ọkan fun.









