Yahaya Jammeh: Obìnrin mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fẹ̀ṣùn ìfipábánilòpọ̀ kan ààrẹ Gambia

Oríṣun àwòrán, Fatou Jallow
Ọmọbinrin arinrinoge nigbakan ri, ti fi ẹsun kan aarẹ ana lorilẹede Gambia, Yahaya Jammeh pe, O fi ipa ba oun lopọ lasiko to fi wa ni ipo aarẹ.
Toufah Jallow, to ti n gbe ni orilẹede Canada bayii sọ pe, oun sa kuro ni Gambia lẹyin ti Jammeh fi ipa ba a ni aṣepọ.
Ijẹri ọmọbinrin naa wa lara aabọ iwadi ti ajọ ajafẹtọ ọmọniyan, Human Rights and Trial International gbe kalẹ. Ajọ naa lo n ṣewadi ẹsun ifipabanilopọ mi i ti wọn fi kan aarẹ nigba kan ri ọhun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
BBC gbiyanju lati ba Ọgbẹni Jammeh, to n gbe ni orilẹede Equatorial Guinea lọwọlọwọ sọrọ, lati gbọ tẹnu rẹ lori ẹsun naa.
Amọ agbẹnusọ fun ẹgbẹ oṣelu rẹ, APRC, ti sẹ lori awọn ẹsun ifipabanilopọ naa.
Ousman Rambo Jatta sọ ninu atẹjade kan ti wọn fun BBC pe "Gbogbo awọn ẹsun ti wọn fi n kan aarẹ wa nigba kanri ti su awa gẹgẹ bi ẹgbẹ oṣelu ati awọn eniyan orilẹede Gambia,''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Jatta sọ siwaju si pe, "Aarẹ nigba kan ri naa ko ni asiko lati maa sọrọ lori awọn iroyin ti kii ṣe otitọ. O jẹ ẹni to bẹru Ọlọrun, ati olori to bọwọ fun awọn obinrin ilẹ Gambia."
Amọ Toufah Jallow sọ fun BBC pe, oun fẹ ẹ fi oju kan Jammeh nile ẹjọ ko le doju kọ idajọ.
"Mo ti gbiyanju lati pa a mọra, ki n si gbe ọrọ naa kuro l'ọkan mi, ṣugbọn, ko rọrun.
Idi niyi ti mo fi pinnu lati sọrọ sita lasiko yii, nitori asiko yii gan an lo dara ju fun mi lati sọ iriri mi. Mo si tun fẹ ẹ ri daju pe, Yahaya Jammeh mọ nkan to ṣe."
Bakan naa lo sọ pe, oun fẹ jẹri niwaju igbimọ ti Aarẹ Adama Barrow gbe kalẹ. Barrow lo wọle sipo aarẹ ninu eto idibo to waye l'oṣu Kejila, ọdun 2016.
Igbimọ naa n wadi awọn ẹsun titẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ to waye lasiko iṣejọba Jammeh. Awọn ẹsun naa ni i ṣe pẹlu ipaniyan, ifiyajẹni to waye lasiko ijọba ọlọdun mejilelogun to ṣe.
Wọn fi ipa le Jammeh kuro nipo l'oṣu Kinni, ọdun 2017 lẹyin ti awọn alaṣẹ ẹkun naa ran awọn ọmọ ogun lọ si orilẹede Gambia nigba ti Jammeh kọ lati kuro ni iṣakoso.
Bawo gan an lo ṣe ṣẹlẹ?
Jallow sọ pe, igba ti oun wa ni ẹni ọdun mejidinlogun ni oun pade Ọgbẹni Jammeh, lẹyin ti oun jawe olubori gẹgẹ bi ọmọbinrin to rẹwa ju ni olu ilu orilẹede naa, Banjul l'ọdun 2014.
Oṣu diẹ lẹyin to bori yii, o ni aarẹ nigba kan ri naa ṣe bi baba fun oun nigba ti awọn pade. O maa n gba a ni imọran, o maa n fun ni owo ati ẹbun. Bakan naa lo fa omi ẹrọ sile mọlẹbi rẹ.
Lẹyin eyi, nibi apejẹ alẹ kan ti ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ aarẹ ṣeto , o ni aarẹ sọ pe ki oun fẹ oun. O kọ, o si tun ko awọn ẹbun ti amugbalẹgbẹ naa fẹ ẹ fun, ko le gba lati fẹ aarẹ.
Jallow sọ pe, ẹyin eyi ni amugbalẹgbẹ naa sọ pe, dandan ni fun oun lati kopa nibi eto isin kan nile ijọba l'oṣu Kẹfa, ọdun 2015, gẹgẹ bi ọmọbinrin to rẹwa ju l'orilẹede naa.
Ṣugbọn nigba to de, ile ti aarẹ n gbe ni wọn mu u lọ.
O f'ojuhan pe, aarẹ n binu simi. Jallow sọ pe aarẹ gba oun ni eti, o si tun gun un ni abẹrẹ kan ni apá.
''O fi nkan ọmọkunrin rẹ pa mi ni oju, o ti mi subu, o bọ aṣọ l'ọrun mi, ko to o ba mi lopọ.''
Bo tilẹ jẹ wipe BBC ko ti fi idi ẹsun ti ọmọge arẹwa naa sọ mulẹ, ṣugbọn oṣiṣẹ ijọba Gambia nigba kan, ti ko fi orukọ rẹ sita sọ pe, oun mọ pe awọn iṣẹlẹ ti ko bojumu maa n waye nile aarẹ.
'Obinrin lo maa n pọ ju ninu awọn to maa n ṣiṣẹ nile aarẹ, wọn si maa n gba ọpọ wọn lati tẹ ifẹkufẹ aarẹ l'ọrun ni.''
O ni oun ranti pe, oun maa n ri Arabinrin Jallow nile ijọba, ni awọn 'aago ti ko bojumu nigba mii.''















