Ambode pe fun ijiya ẹwọn ọdun mẹẹdọgbọn fun afipabanilopọ

Oríṣun àwòrán, Lagos state government
Gomina ipinlẹ Eko, Akinwunmi Ambode ti sọ wi pe ko si ohun to buru ninu ijiya ẹwọn ọdun mẹẹdọgbọn fun ẹnikẹni to ba jẹbi ẹsun ifipabanilo tabi eyikeyi iwa idunmọhuru mọ obinrin ninu ile.
Ni ọjọ Aje ni gomina Ambode sọ ọrọ yii nigba to n lewaju ayẹyẹ irin ipolongo kan ti wọn ṣe lati tako iwa ipa ninu ile ati iwa ifipabanilo lawujọ.
Gomina Ambọde ni asiko to lati dide tako iwa kotọ naa lawujọ.

Oríṣun àwòrán, Lagos state government
"Iwa ifipabanilopọ kii ṣe ohun to yẹ ki a fun ni ijiya yẹpẹrẹ. Mo da aba, ẹwọn ọdun mẹẹdọgbọn.
"A nilo ofin tuntun lati koju ọwọja iwa yii lawujọ. Iwa ọdaran paraku ni iwa ipa ninu ile ko si si ọwọ miran lati fi muu ju ọwọ lile lọ.
"Ni kia lo si yẹ ki a se atunse si ofin to de gbigbogun ti iwa ipa ninu ile ti ọdun 2017 pẹlu awọn ijiya tuntun lati fi awọn ti aje iwa yii ba si mọ lori jofin daindain."
O ni ipinlẹ Eko ti lamilaaka ninu awọn igbesẹ lati koju iwa ipa si awọn obinrin atawọn ọmọde pẹlu bi ikọ ti wọn gbe kalẹ lori rẹ ti se gbe awọn ilana kalẹ leyi ti o mu irọrun ba fifi iroyin nipa isẹlẹ iwa ipa labẹle to awọn ileesẹ to yẹ leti ati mimu ijiya to tọ ba awọn to ba hu iwa ọhun.

Oríṣun àwòrán, Lagos State Government
"Ohun ti o n sẹlẹ yii jẹ iwa ibajẹ ti o n sọ awọn obinrin di ohun itẹmọlẹ lawujọ leyi ti o ti n mu ọpọ ninu wọn maa sunkun asunmi.
"Ipinlẹ Eko ti bẹrẹ igbesẹ lati mu ayipada nla jade wa lori eyi."
Bakan naa ni Gomina ipinlẹ Eko tun kan saara si ẹka idajọ fun idasilẹ asayan ileẹjọ to n gbọ ẹsun to rọ mọ iwa ibanilo lọna ti ko tọ.

Oríṣun àwòrán, Press Association
Amọsa, Gomina Ambọde ni isẹ ku sọwọ awọn agbofinro lati rii wi pe wọn n se iwadi to kuna nitori ko si ani-ani wi pe awọn gan-an laraalu kọkọ maa n kan si ti irufẹ iwa ọdaran bẹẹ ba waye.
Lara awọn to wa nibi eto irin ẹyẹ naa ni igbakeji gomina ipinlẹ Eko, Ọmọwe Oluranti Adebule, adajọ agba ipinlẹ naa, Onidajọ Olufunmilayo Oke, Aya gomina ipinlẹ Eko, Arabinrin Bolanle Ambode, Kọmisọna ọlọpaa Imohimi Edgal pẹlu Amofin agba ni ipinlẹ naa, Ọgbẹni Adeniji Kazeem.












