Femi Fani-Kayode: Ọ̀rẹ́ lásán ni Halima Yusuf jẹ́ sí mi, kìí ṣe àfẹ́sọ́nà mi

Halima Yusuf ati Femi Fani Kayode

Oríṣun àwòrán, Femi Fani Kayode

Àkọlé àwòrán, Halima Yusuf ati Femi Fani Kayode
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Nnkan bi ọjọ diẹ sẹyin ni iroyin kan gbode lori ayelujara pe, Minisita tẹlẹ feto irina ọkọ ofurufu, Femi Fani-Kayode fẹ gbe iyawo tuntun.

Bẹẹ ba si gbagbe, ko tii ju bi osu kan lọ, ti iroyin gbalẹ lori ayelujara pe igbeyawo Fni-Kayode ati iyawo ile rẹ ti fori sanpọn.

Ṣugbọn minisita ọhun ti fọhun sita pe, irọ patapata ni iroyin naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni oun ko ṣetan lati gbe iyawo lasiko yii, obirin ti awọn eeyan n ṣọ pe oun fẹ gbe niyawo, Alima Yusuf, kii ṣe afẹsọna oun, bikoṣe ọrẹ lasan.

Àkọlé fídíò, Goitre Patients: Àwọn èèyàn tó ní àrùn gẹ̀gẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìkórira àti ìdẹ́yẹsí ní àwọn ń kojú

Fani-Kayode lo kede ọrọ naa ninu atẹjade kan to fi sita loju opo Instagram rẹ, nibi to ti parọwa si awọn eeyan lati dẹkun pinpin iroyin ofege nipa oun kiri lori ayelujara.

O ni "Awọn kan ti n gbe ahesọ kan kiri lori ayelujara pe mo n mura fun igbayawọ laipẹ, irọ ni o."

"Omidan Halima Yusuf, ti wọn n pe ni afẹsọna mi kii ṣe afẹsọna mi rara, ọrẹ lasan lo jẹ si mi, o si tun jẹ olufọkantan ati ẹni apọnle lọwọ mi."

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Fani-Kayode ṣalaye pe obinirin naa, yatọ si awọn eeyan miran, jẹ olutunu fun oun lasiko yii, ati pe oun mọ riri rẹ ninu aye oun.

Minisita naa pari ọrọ rẹ pẹlu ẹbẹ pe, ki gbogbo awọn gboyi-sọyi lọ so ewe agbejẹ mọwọ nitori oun ko ṣetan lati gbe obinrin naa niyawo.

Tani Halima Yusuf?

Ọmọ bibi ipinlẹ Bornu ni Halima, ṣugbọn ipinlẹ Gombe lo fi n ṣebugbe pẹlu awọn ẹbi rẹ, ko to tẹkọ leti lọ si ilu Abuja ni nnkan bi ọdun diẹ sẹyin lati bẹrẹ iṣẹ owo ṣiṣe.

"Halima Yusuf" wey Femi Fani Kayode call im 'comforter'

Oríṣun àwòrán, Halima Yusuf

Àkọlé àwòrán, Halima Yusuf

Gẹgẹ bo ṣe sọ loju popo Instagram rẹ, Halima ni alaṣẹ ati oludari ileeṣẹ Sly Royal, nibi to ti n ta aṣọ awọn obinri ati awọn ẹṣọ ara.

Bakan naa lo tun ṣọ pe oun n ṣowo awọn ohun aṣara loge fun awọn obinrin.

Àkọlé fídíò, Goitre Patients: Àwọn èèyàn tó ní àrùn gẹ̀gẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìkórira àti ìdẹ́yẹsí ní àwọn ń kojú

Bo tilẹ jẹ pe o ṣoro lati sọ iye ọjọ ori rẹ, ati ileewe to lọ lasiko yii, ọpọ eeyan lo ti n woye pe, o yẹ ko sọrọ lori ibaṣepọ rẹ pẹlu Femi Fani-kayode.