Coronavirus update: A kò ní gba owó lọ́wọ́ ará ìlú fún ohun eèlò àyẹ̀wò Covid-19 tí a ṣẹ̀sẹ̀ ṣe - NIMR

Oríṣun àwòrán, @nimrnigeria
Ileeṣẹ to n ṣe iwadii nipe eto ilera ni Naijiria, Nigerian Institute of Medical Research, NIMR, ti kede pe ọfẹ ni ohun eelo ti wọn ṣẹṣẹ ṣe, eyii to lagbara lati ṣayẹwo arun Covid-19 pẹlu esi rẹ laarin ogoji iṣẹju.
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa to ba BBC Yoruba sọrọ, Dokita Iwalokun Bamidele lo ṣi aṣọ loju ọrọ naa.
O ni iṣẹ takun takun ti awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa ṣe lo jẹ ko ṣeeṣe lati ṣagbekalẹ irinṣẹ ọhun ti wọn pe orukọ rẹ ni "SARS-COV-2."
- Ọgọ́rin arìnrìnàjò tó padà wá sí Nàìjíríà ló ní Coronavirus - PTF
- Ifẹ́ Yorùbá ló mú mí fi ẹ̀mí wéwu láti koju ajínigbé ní Kishi - Sunday Igboho
- Ẹ́ yé parọ́ mọ́ mi kiri, n kò múra ìgbéyàwó, ọ̀rẹ́ lásán ni Halima - Femi Fani-Kayode fọnmú
- Ìbò 900m làwọn èèyàn di lórí ètò BBNaija tó ṣẹ̀ṣẹ̀ parí - MultiChoice
- PDP àti APC fi ìbọn dárà l'Ondo, ọ̀pọ̀ èèyan farapa, àìmọye dúkìá ṣòfò
Bo tilẹ jẹ pe Iwalokun ni oun ko tii le sọ igba ti awọn ọmọ Naijiria yoo ni anfani lati bẹrẹ si n lo ẹrọ ọhun fun ayẹwo, o ni iṣẹ n lọ lọwọ lati pari gbogbog eto to ni ṣe pẹlu lilo rẹ.
Nipa bi awọn eeyan yoo ẹ maa lo erọ naa, o ni yoo wa ni awọn ile iwosan ijọba ti awọn to ba fẹ ṣe ayẹwo yo maa lọ sibẹ fun ayẹwo wọn.
Ni ti pe awọn eeyan yoo san owo ayẹwo ọhun, Iwalokun sọ pe ko si ohun to jọ bẹẹ.
O ni "Mi o lero pe awọn eeyan yoo san owo kankan lati lo ẹrọ na fun ayẹwo arun Covid-19 rara, nitori ara anfani ijọba fun awọn eeyan niyẹn."
Ẹwẹ, alaga ẹgbẹ awọn dokita ni Naijiria, NMA, Ọjọgbọn Innocent Ujah ki awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ NIMR ku iṣẹ takun takun fun igbiyanju wọn lati ṣagbekalẹ ẹrọ ọhun.
Ujah, to ti fi igba kan jẹ oludari ileeṣẹ naa sọ pe ko rọrun lati gbe iru ẹro ayẹwo bẹ jade ni Naijiria lai si atilẹyin owo iranwọ lati ọdọ ijọba.
- Ìjọba àpàpọ̀, jọ̀ọ́ máṣe yẹ̀ lórí àdéhùn rẹ fẹ́gbẹ́ òṣìṣẹ́ - Ile aṣojú-ṣòfin
- Ilé ẹjọ́ gíga ní kí òsìsẹ́ First Bank tẹ́lẹ̀ lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún 98 lórí ẹ̀sùn pé o jí mílíọnù 49 àti $368, 000 níbẹ̀
- N kò mọ ẹni tó fẹ́ gba ìyàwó mi, àmọ́ wọn máa ń sọ pé ó rẹwà - Mike Bamiloye
- Sadiya Umar Farouq ti ní pé ọwọ òun mọ́ lórí N2.67 biliọnù owó oúnjẹ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ICPC ní wọ́n se mọ́kumọ̀ku
O ni "Mo ki adari ileeṣẹ naa fun igbiyanju rẹ lati gbe ẹrọ naa jade, paapaa lasiko yii ti ijọba ko fi bẹẹ gbe owo kalẹ fun iwadii imọ ijinlẹ, bẹẹ ko le e si idagbasoke laisi iwadii ijinlẹ to peye."
Ọjọgbọn naa pari ọrọ rẹ pe "Oju ti awa ẹgbẹ awọn dokita fi wo agbekalẹ ẹrọ yii ni pe o jẹ ohun to dara pupọ, inu wa dun, o si tun jẹ ohun iwuri, nitori naa, a ki NIMR ku oriire."
Lẹyin naa lo rọ ijọba apapọ lati maa ṣatilẹyin fun iwadii imọ ijinlẹ ni Naijiria nipa pipese owo fun awọn ileeṣẹ to n ṣe iwadii.
- Ayuba Sarafa, Olọ́kadà kan tó jẹ́ eni ọdún 22 pokùnso ní Ibadan
- Ìjọ́ba ìpínlẹ̀ Ogun náà ti gbóríyín fún Laycon gẹ́gẹ́ bíi ògidì ọmọ Ogun sùgbọ́n dandan ní owó orí sísan
- Àríyá yá! Sẹ́nátọ̀ Elisha Abbo kési Naira Marley láti ṣe àríyá fún Leycon tó borí ní BB Naija
- Lẹ́yìn ọgọ́ta ọdún tí Nàíjíríà gba òmìnira, wo ipò tí àṣà àti èdè Yorùbá wà















