Sadiya Umar Farouq: Èmi kò jí nínú owó oúnjẹ àwọn akẹ́kọ̀ọ́, irọ́ ni Bolaji Owasanoye, alága ICPC ń pa

Sadiya Umar Farouq ti ní pé ọwọ òun mọ lórí N2.67 biliọnù owó òúnjẹ àwọn akẹkọọ tí ICPC ní wọn se mọkumọku
Iroyin to n tan kaakiri ni pe alaga àjọ to n gbogún ti iwà ibajẹ ICPC ni awọn osisẹ ijaba kan ti lu owo ounje awọn akẹkọọ ni ponpo.
Sadiya Umar Farouq ti ní pé ọwọ òun mọ lórí N2.67 biliọnù owó òúnjẹ àwọn akẹkọọ tí ICPC ní wọn se makumọku
Saaju ni wọn ni alaga ajọ ICPC to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra ni Naijiria, Ọjọgbọn Bolaji Owasanoye ti fẹsun kan awọn èèkàn osise nile isẹ ijọba to n mojuto ọrọ eto ọgbin ati awọn miran pe wọn lu biliọnu meji ati abọ to yẹ ki wọn fi bọ awọn akẹkọọ ni ponpo.
- N kò mọ ẹni tó fẹ́ gba ìyàwó mi, àmọ́ wọn máa ń sọ pé ó rẹwà - Mike Bamiloye
- Wo bí ìtàkurọ̀sọ láàrin Donald Trump àti Joe Biden yóò ṣe wáyé
- Àríyá yá! Sẹ́nátọ̀ Elisha Abbo kési Naira Marley láti ṣe àríyá fún Leycon tó borí ní BB Naija
- Ṣó yẹ kí akẹ́kọ̀ọ́ tàbùkù mi torí mo ya ‘Tatoo’ sí gbogbo ara?- Olùkọ́
Bolaji Owasanoye ni: "A woye pe wọn dọgbọn si ọna ti wọn fi gbe owo naa jade nipa lilo sub-TSA ki oju kankan ma lee se abojuto bi owo naa se n ajde ati ibi to n gba lọ.
Sibẹsibẹ, a sawari pe awọn owo kan ti wọn ni awọn fi pese ounjẹ fun awọn akẹkọọ lasiko isede ajakalẹ arun coronavirus ni awọn ile iwe kan ko ri bẹẹ rara.
Koda, awọn akẹkọọ naa ko tilẹ si nile iwe lasiko Covid 19 naa rara, leyin o reyin ni a rii pe apo awọn kan ni owo naa wọ lọ.
A ti bẹrẹ iwadii ti wa ni kikun bayii".
Lati igba ti iroyin naa ti jade ni ọpọ eeyan ti n fi ẹnu kun awọn to wa nile isẹ ijọba apapọ to n mojuto ọrọ irọrun nipa ipese iranwọ lẹyin isẹlẹ pajawiri fun awọn ara ilu ti wọn pe ni: Federal Ministry of Humanitarian Affairs
Eyi ko seyin bo se jẹ pe ile isẹ yii lo mojuto pinpin ounjẹ fawọn akẹkọọ lasiko isede Coronavirus
Ko pe sii ni ileese yii naa fesi loju opo twitter wọn pe ọwọ awọn mọ lori iwadii ajọ ICPC yii nitori awan pin ounjẹ naa bi o ti yẹ
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Alaye lori esi ileese ti ICPC fi ẹsun kan ree:
Won ni awọn eeyan kan to fẹran wahala ati laasigbo lo wa nidi ọrọ naa.
Ati pe o kan wu awọn ẹni ibi yii lati tu ọra ajọ ICPC si ọna miran ni ti wọn si doju ẹsun naa kan ileese ijọba to jẹ Ministry of Humanitarian Affairs.
Wọn tun ni ọra awọn ile iwe ijọba apapọ ti ICPC n sọ yatọ si ti awọn akẹkọọ ti awẹn fun ni ounjẹ lasiko Coronavirus.
- Ilé ẹjọ́ gíga ní kí òsìsẹ́ First Bank tẹ́lẹ̀ lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún 98 lórí ẹ̀sùn pé o jí mílíọnù 49 àti $368, 000 níbẹ̀
- Laycon, kú oríire àmọ́ bá ń kó owó orí nínú ẹ̀bùn rẹ nílé BB Naija - Ìjọba Eko
- Wike, má gbé jàgídíjàgan wá sí Ondo, APC kò ní ṣ'èèrú nínú ìdìbò gómìnà tó ń bọ̀- Kalejaye
- Ayuba Sarafa, Olọ́kadà kan tó jẹ́ eni ọdún 22 pokùnso ní Ibadan















