GSS Kagara abduction news update: Ìròyìn òfegè ni pé a ti rí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Government Science College, Kagara gbà padà

Gomina
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Gomina ipinlẹ Niger, Alhaji Abubakar Sani Bello ti sọ pe irọ ni iroyin to n jade pe awọn to ji awọn akẹkọọ gbe ti fi wọn silẹ.

Wọn ni irọ ni iroyin naa nitori pe iroyin ofege ni.

Gomina Sani Bello sọ pe titi di asiko yii wọn ko tii ri awọn akẹkọọ naa gba.

O ni awọn ṣi n gbiyanju lati wa awọn akẹkọọ naa ri ni.

Gomina naa salaye fun BBC pe Sheik Ahmad Gumi to jẹ gbajugbaja alfa ni oun ti sepade pẹlu awọn janduku kan lori ọrọ awọn ti wọn ji gbe nile ẹkọ Government Science College ni Kangara ni ipinlẹ Niger.

Sheik naa ni kii ṣe awon to ji awọn ọmọ gbe gangan ni oun pade bi awọn ileeṣẹ iroyin kan ṣe n sọ kiri.

Àkọlé fídíò, Femi Falana, Endsars: Awolowo kò fáààyè gba kí èèyàn máa yàgò fún Màálù nígboro

Ṣugbọn awọn janduku naa ṣelelri lati ran wọn lọwọ wa awọn akkọọ naa ri.

Ati pe awọn mọ awọn to ji awọn ọmọ naa gbe, ki wọn le tete fi wọn silẹ.

Minista eto aabo

Oríṣun àwòrán, @Nigeria Army

Mínístà, Kọ̀wé fipò rẹ sílẹ̀ tàbí kí o dákẹ́ tí ò kó bá wá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó sọnù- ọmọ Nàìjíríà

Awọn ọmọ Naijiria yari lori ayelujara nitori ọrọ ẹnu minista tuntutn ti aarẹ Buhari ṣẹṣẹ yan sipo gẹgẹ bi Minsita eto aabo Naijiria.

Èrò àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí àṣẹ Mínístà ètò aàbò

Ogagun fẹyin ti agba Bashir Magashi lo sọ fun awọn ara abule kan pe ki wọn gbeja ara wọn kuro lọwọ awọn oniṣẹ ibi to n dunkooko mọ wọn nibẹ.

Bakan naa lo tun ṣapejuwe awọn to ji awọn akẹkọọ Kagara ni ipinlẹ Niger ni aarin gbungbun Naijira gẹgẹ bii alailagbara ti kii ṣe akọni to le koju awọn eeyan to duro bi akọni.

O ni ki awọn eeyan Naijiria pese aabo to peye nibikibi ti wọn ba wa ki wọn si di oju lalakan fi n ṣọri fun ara wọn.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Lẹyin to sọrọ yii ni awọn ọmọ Naijira faraya lori ayelujara pe ko kuku kọwe fipo rẹ silẹ tabi ko gbẹnu rẹ dakẹ ti ko ba nkan to kan fun oun gẹgẹ bii minista eto aabo.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Skip X post, 3

End of X post, 3

Àkọlé fídíò, Oladele Ogbeyemi Albert: Irin tí mò ń lò máa ń bá mi sọ̀rọ̀ nínú ẹ̀mí kí ń tó gbẹ́ wọn sóh

Awọn miran ni ko ma lo ẹṣọ aabo awọn eleto aabo to n ṣo Minista funra rẹ to ba da ara rẹ loju

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Awọn miran bii Kayode Ogundamisi ni eyi ti fihan pe ko si eto aabo kankan fun ara Naijria rara

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 5

Senate

Oríṣun àwòrán, @Senate

Buhari kéde ìlú kò fararọ lásìkò yìí- Ilé Igbimọ̀ Aṣofin Nàìjíríà

Wọ́n ti tilẹ̀kùn gbogbo ilé ẹ̀kọ́ níjọba ìbílẹ̀ Rafi, Munya, Mariga àti Shiroro pa ní ìpínlẹ̀ Niger

Ile igbimọ Aṣofin agba ni Abuja ti kede pe ki Aarẹ Muhammadu Buhari kede ilu kofararọ bayii ni Naijiria.

Àkọlé fídíò, Shasha Crisis in Ibadan: Gbọ́ ohun tó ṣokùnfà ìjà láàrin Aláboyún, soo bàtà àti Hausa alá

Wọn ni o to gẹ ọmọ Leffi ni ibi ọrọ ipenija eto aabo de duro bayii kaakiri ipinlẹ Naijiria.

Awọn ọmọ ile kede yii lẹyin ti awọn oniṣẹ ibi kan kọlu ile ẹkọ Government Science School, Kagara, ni ipinlẹ Niger, ni aarin gbungbun Naijiria.

Wọn ni ki Aarẹ tẹlẹ aba ti igbimọ tẹẹkoto lori ipenija eto aabo Naijiria tile igbimọ Aṣofin fẹnuko le lori lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kétam ọdun 2020.

Wasu daga cikin daliban sun tsere

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Wasu daga cikin daliban sun tsere

Akẹ́kọ̀ọ́ 27, òṣìṣẹ́ méjì àti mọ̀lẹ́bí méjìlá ni àwọ́n agbébọn jí gbé ní ìpínlẹ̀ Niger

Gomina ipinlẹ Niger, Abubakar Sani ti sọ pe awọn akẹkọọ mẹtadinlọgbọn, oṣiṣẹ ileewe meji atawọn mọlẹbi mejila ni awọn agbebọn kan ji gbe nipinlẹ naa.

Sani lo ṣi aṣọ loju eegun lori iye awọn eeyan naa nibi ipade awọn akọroyin kan to waye ni Minna.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn akẹkọọ ọhun jẹ ọmọ ile iwe Government Science School, to wa ni Kagara, ṣugbọn apapọ iye eeyan to ti dawati bayii je mọkanlelogoji.

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti pàṣe kí àwọn ológun ṣàwárí àwọn èèyàn náà ní kíákíá

Gomina naa ṣalaye pe awọn agbebọn ọhun tun yinbọn pa ọkan lara awọn akẹkọọ naa.

Bo tilẹ jẹ pe Sani sọ pe ijọba oun ko ni san owo itusilẹ kankan fun awọn ajinigbe naa, ṣugbọn o ti paṣẹ pe ki wọn ti gbogbo ileewe ti awọn akẹkọọ n gbe pa nipinlẹ ọhun.

Ẹwẹ, Aarẹ Muhammadu Buhari ti bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ ijinigbe naa ninu atẹjade kan ti amugbalẹgbẹ rẹ lori ọrọ iroyin ati ipolongo, Garba Shehu fi ṣọwọ si awọn akọroyin.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa lori BBC: Olùkọ́ Bolanle Adekanmi kọ́ wa nípa oríṣíi Àròkọ Yorùbá tó wà

Buhari ni oun ti paṣẹ fun awọn ọlọpaa atawọn ọmọ ogun lati wa gbogbo ọna lati ṣawari awọn ọmọ ile iwe ọhun.

O sọ pe ijọba ohun yoo ṣe iranwọ to yẹ fun awọn oṣiṣẹ eto abo lati ri pe opin de ba gbogbo ophun to jọ mọ iṣẹrubalu ati ijinigbe ni Naijiria.

Agbebọn kan pẹlu ibọn rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn agbébọn pa akẹ́kọ̀ọ́ kan, jí ọ̀pọ̀ akẹ̀kọ̀ọ́ gírama àti olùkọ́ gbé níléèwé girama GSS Kagara ní Niger

Awọn agbebọn tun ti ya bo ileewe girama kan ni ipinlẹ Niger nibi ti wọn ti yinbọn pa akẹkọọ kan ti wọn si tun ji ọpọ awọn akẹkọọ ati olukọ gbe.

Iroyin lati awọn ileeṣẹ iroyin abẹle kan fi idi rẹ mulẹ pe ileewe Government Science School Kagara ni ipinlẹ Niger ni awọn agbebọn naa kọlu.

Àkọlé fídíò, Ẹ̀yin olórin ẹ̀mí tó ń bóra, lo èékáná gígùn, oò yàtọ̀ sí aṣẹ́wó hòtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ń gbé bíi súùtì Pepper Menti - Bola Are

Iroyin naa ṣalaye pe ni nnkan bii agogo meji oru ni awọn agbebọn naa ya wọ ileewe naa pẹlu aṣọ ileewe naa lara wọn.

Awọn alaṣẹ ijọba ipinlẹ Niger ṣalaye pe awọn ko tii le fi idi iye awọn akẹkọọ tabi oluks ti wọn ji gbe mulẹ.

Amọṣa awọn orisun iroyin kan ṣalaye pe niwọn igba to jẹ pe iye awọn akẹkọs to wa nilewe naa to ẹgbẹrun kan iye awọn akẹkọọ ati olukọ ti wọn ji gbe naa lee pọ diẹ.

Àkọlé fídíò, Lori iro: Ká ni àwọn Òbí mi gbà fún mí, èmi àti Sunny Ade á jọ máa 'Compete- Baba Lórí ir

Gẹgẹ bi awọn orisun iroyin miran ṣe fi idi rẹ mulẹ, awọn kan lara awọn akẹkọs naa ti sa asala kuro lọwọ awọn ajinigbe naa.

Nibayii, wọn ṣi n ka iye awọn akẹkọs to ku ki wọn to lee mọ ni pato iye awọn akẹkọọ ati olukọ ti wọn ji gbe.

Awọn alaṣẹ ko tii fi iroyin sita lori iṣẹlẹ ijinigbe naa.

Gbọnmọgbọnmọ awọn agbebọn to n kọlu ileewe girama lati ji awọn akẹkọọ gbe kii ṣe iroyin tuntun mọ lorilẹede Naijiria paapaa lagbegbe oke ọya orilẹede Naijiria.

Ni oṣu kejila, ọdun 2020 lawọn agbebọn ji ọdunrun akẹkọọ gbe nileewe girama Kankara Secondary school ni ipinlẹ Katsina eleyi to fa ọpọ ọrọ latawọn orilẹede agbaye gbogbo.

kilaasi ileewe kan