Púpọ̀ nínú àwọn awakọ̀ ni kò tíì mọ̀ pé ilé ẹjọ́ ti wọ́gilé gbígba owó lọ́wọ́ àwọn dẹ́rẹ́bà ni ibudokọ ipinlẹ Oyo

BBC Yoruba rin kaakiri awọn ibudokọ kan nilu Ibadan lati fi ọrọ wa awọn awakọ lẹnu lori aṣẹ ti ile ẹjọ pa wi pe agbekale awọn alakoso to n gba owo ni ibudokọ, "Park Managers" ko ni atilẹyin ofin.
Abẹwo ti a ṣe si awọn ibudokọ kan l'owurọ Ọjọbọ lo fi idi ẹ mulẹ pe pupọ ninu awọn awakọ naa ni ko tii gbọ nipa aṣẹ ile ẹjọ lori awọn alakoso to n gba owo lọwọ ni ibudokọ.
Bo tilẹ jẹ pe pupọ ninu awọn awakọ naa ni ko fẹ fi oju han tabi da orukọ wọn;
Awọn ti o ba wa sọrọ labẹ aṣọ ṣalaye fun akọroyin wa pe gbogbo ohun ti yoo mu itẹsiwaju ati irọrun ba iṣẹ ọkọ wiwa ni awọn fi ọwọ si.
- Wo ẹ̀bùn owó tabua tí gbajúgbajà oníṣòwò kan fún bàbá "Lórí Irọ́"
- Akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá mú ìbọn ìléwọ́ lọ ilé ìwé láti yìín lu olùkọ́ tó ní kó gé irun orí rẹ̀
- Alhaja Muslimot Salami tí àwọn darandaran kọlù ní Ogun tí padà jẹ́ Olorun nípè!
- Àìṣàtìpó rí ló ń da Ejiogbe láàmú, àsìkò ìjọba tèmi ló dé- Alhaji Mukaila Auxilliary
- Ṣé lóòtọ́ ni omidan yìí ya wèrè ní kété tí ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ ní òun fẹ́ fi ṣaya?
Ọkan lara awọn awakọ naa to n na agbegbe New Garrage si Iwo Road ṣalaye pe oun ko gbagbọ wi pe o ṣeeṣe ki awọn maa ṣiṣẹ awakọ nipinlẹ Ọyọ ki ẹnikẹni ma si gba owo Ibudokọ lọwọ wọn.
O ni nitori gbogbo ibi ni wọn ti n gba owo lọwọ awakọ lorilẹ-ede agbaye, ọna ti wọn fi n gba a kan yatọ sira wọn ni.

Idahun si awọn ibeere ti a bi awọn awakọ to n na Challenge, Mọlete, Gate titi de Mọkọla Roundabout naa tun fi idi ẹ mulẹ wi pe pupọ wọn ninu ko tii gbọ nipa aṣẹ ti ile ẹjọ pa.
Bẹẹ si ni a ri melo kan lara awọn alakoso ibudokọ naa ti wọn ba iṣẹ wọn lọ ni awọn agbegbe ti a de l'owurọ Ọjọbọ.
Titi di asiko ti a kọ iroyin yii, gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde ati igbimọ alakoso ibudokọ nipinlẹ Ọyọ ko ti i fesi lori aṣẹ ti ile ẹjọ pa.
L'ọjọ kẹtadinlogun, oṣu keji, ọdun 2021 ti agbekalẹ awọn alakoso ibudokọ pe ọdun kan gerege ni ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ wọgile e pẹlu alaye wi pe igbesẹ naa ko ni atilẹyin ofin.
- Wo ẹ̀bùn owó tabua tí gbajúgbajà oníṣòwò kan fún bàbá "Lórí Irọ́"
- Mínístà, Kọ̀wé fipò rẹ sílẹ̀ tàbí kí o dákẹ́ tí ò kó bá wá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó sọnù- ọmọ Nàìjíríà
- Philip ẹni ọdún 99 tó jẹ́ ọkọ Ọbabìnrin Elizabeth ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ nílé ìwòsàn
- Wo iye kọ́ńdọ́mù táwọn ọmọ Nàìjíríà fi ń ṣara rindin lọ́dún















