Sunday Igboho: Muslimot Moronkeji Salami ti wọ́n kọlú ní Ijebu Oru ti dolóògbé

Musilomt

Oríṣun àwòrán, others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Alhaja Muslimot Moronkeji Abeni Salami ni awọn darandaran kọlu ni Ijẹbu Oru ni ọsẹ melo kan sẹyin.

Iroyin yii gba gbogbo igboro kan nitori pe o ṣẹlẹ lasiko ti Sunday Igboho n gbena woju awọn fulani darandarn lori bi wọn ṣe n ṣọṣẹ kaakiri ilẹ Yoruba.

Bayii, BBC ti fidiẹ mulẹ pe, Alhaja Muslimot ti pada jẹ Olorun ni pe lọjọ kẹrindinlogun, oṣu keji ọdun yii.

Wọn si ti sin Alhaja naa ti ko moribọ lẹyin ikọlu naa lọjọ kẹtadinlogun, oṣu keji, ọdun 2021 yii ni ilana musulumi.

Alhaja Muslimot Salami

Oríṣun àwòrán, others

Ki lo ti kọkọ ṣẹlẹ sẹyin nipa Alhaja Salami Muslimot?

Afurasí Fulani daran-daran fi ìbọn fọ́ ìka obìnrin kan lójú pópó

Darandaran fulani ati maalu rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ti tẹ darandaran mẹrin, to fi iya jẹ obinrin kan, Morenike Salami ni Ijebu-Oru.

Gẹgẹ bi nkan ti agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ naa, Abimbola Oyeyemi sọ fun BBC, oju ọna ni awọn afurasi daran-daran Fulani ọhun ti kọlu Morenike.

Ọgbẹni Oyeyemi fi kun ọrọ rẹ pe ọjọ Aje, ọjọ kọkanla, oṣu Kinni ni iṣẹlẹ naa waye.

Bakan naa lo sọ pe wọn o ko awọn afurasi naa lọ sile ẹjọ, ti iwadii ba pari.

Ninu fọran kan to tẹ BBC Yoruba lọwọ, to si tun ba iroyin to n lọ mu, lo ti han pe awọn afurasi daran-daran Fulani naa fi ibọn fọ ìka obinrin naa.

Morenike Salami

Oríṣun àwòrán, Others

Ọmọ rẹ to sọrọ ninu fọnran naa sọ pe, o ni iya oun ṣeeṣi wa ọkọ rẹ kọja laarin awọn maalu wọn, lasiko to n lọ si ile to n kọ lọwọ ni Ijẹbu-Oru, ni wọn fi kọlu.

O ṣalaye pe niṣe ni iya oun ṣe bi ẹni to ti ku, ki wọn to fi silẹ lẹyin ti wọn ti fi iya jẹ.

Lọwọlọwọ, Arabinrin Morenike wa nileewosan ijọba ipinlẹ Eko to wa ni Ikeja, nibi to ti n gba itọju.

Bakan naa ni fidio kan naa wa lori ayelujara to ṣafihan rẹ lori ibusun nileewosan, ti ọmọ rẹ si n sọrọ nipa bi iṣẹlẹ naa ṣe waye.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

Agbẹnusọ ọlọpaa sọ pe lasiko ti awọn afurasi naa pada wa lati ko maalu wọn lẹyin ti wọn kọlu arabinrin naa, ni ọwọ ọlọpaa tẹ wọn nibi aago mẹwa alẹ.

Ọrọ ikọlu awọn daran-daran Fulani ko ṣẹṣẹ ma a jade ninu iroyin.

Dokita n tọju Morenike ti wọn ge ika rẹ.

Oríṣun àwòrán, @Renny_1

Eyi gan na lo fa bi gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ṣe fun awọn daran-daran Fulani nipinlẹ naa ni gbedeke lati kuro.

Bakan naa ni ni ipinlẹ Ọyọ, nibi ti ajijagbara, Sunday Igboho ti fun wọn ni gbedeke .

Bukola Saraki ati Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, @bukolasaraki/@SundayIgboho2

Bukola Saraki sọ̀rọ̀ sókè lórí ìgbésẹ̀ Sunday Igboho

Bukola Saraki ké sí Buhari láti pe àpérò àwọn èèkan ọmọ Nàìjíríà

Yoruba ni aisi nibẹ, ni aibawọn da si, ọrọ yii, ọrọ rẹ ni, bo ba lọ soko ati odo, ibẹ naa lo baa.

Eyi lo mu ki aarẹ ile aṣofin agba tẹlẹ, Sẹnetọ Bukọla Saraki naa fi sọrọ soke lori awọn isẹlẹ to n waye laarin ẹya Fulani ati Yoruba nipinlẹ Oyo ati ipa ti Sunday Igboho ko nibẹ.

Saraki, ninu atẹjade kan to fisita lori isẹlẹ naa, wa ke si Aarẹ Muhammadu Buhari lati pe ipade apero awọn eekan ọmọ orilẹede Naijiria, nibi ti wọn yoo ti joko jiroro lori eto abo to dojude.

Sẹnetọ Saraki ṣalaye pe nibi ọrọ n dojukọ lorilẹede Naijiria bayii, ohun to tọna ni ki ijọba bẹrẹ igbesẹ to loorin lori rẹ.

O ni aṣẹ "ẹ kuro nilẹ ẹwa" ti wọn fun awọn darandaran Fulani ni ipinlẹ Ondo ati Ọyọ, ti tubọ mu ki nnkan o le koko, ti kaluku si n kaya soke.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

O ni ohun ti iṣẹlẹ meji yii n tọka si naa ni gulegule ipe fun ipinya orilẹede Naijiria, eyi to ti n yọju sita fun igba diẹ sẹyin bayii, paapaa julọ lawọn ẹkun bii ila oorun, guusu ati aarin gbungbun guusu.

Bakan naa lo kọminu si bawọn eekan orilẹede Naijiria ṣe dakẹ lori awọn iṣẹlẹ to n waye wọnyii.

"Didakẹ yii lewu pupọ, o si fihan pe nnkan o rọgbọ. Gbogbo wa la gbọdọ sọrọ soke lori wiwa ọna abayọ si iṣoro oloju meji aisi abo ati aisi iṣọkan lorilẹede yii."

Àkọlé fídíò, African Eye: Wo Jane Mugo, obìnrin bíi ọkùnrin tó ń ṣiṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ bíi James Bond

Bakan naa lo tun rọ gbogbo awọn to n gbero ati dije fun ipo aarẹ Naijiria lọdun 2023, lati gbe igbesẹ fun iṣọkan orilẹede Naijiria.

O ni wọn gbọdọ ronu lori irufẹ orilẹede Naijiria ti wọn fẹ dari, boya Naijiria to wa ni iṣọkan tabi eyi to pin yẹlẹyẹlẹ.