Sunday Igboho: Gani Adams ní dídákẹ́ òun lórí ìṣẹ̀lẹ̀ Igangan kìí ṣe ìwà ojo

Gani Adams ati Sunday Igboho

Aarẹ Ọna kakanfo ilẹ Yoruba, Oloye Gani Adams ti leri leka, to si tọ ilẹ la pe gbogbo igbinyanju awọn ẹya kan lati sọ ilẹ Yoruba di ibudo ogun lawọn yoo tako.

Oloye Gani Adams jẹjẹ yii lasiko to n fesi lori ọrọ ti ẹgbẹ apapọ eeyan Arewa, ACF ati Miyetti Allah sọ pe ogun n bọ nitori atako ti wọn n se si ẹya Fulani lẹkun iwọ guusu Naijiria.

Adams sisọ loju ọrọ yii ninu atẹjade kan ti amugbalẹgbẹ rẹ fisita eyi to pe akori rẹ ni "Aifararọ eto aabo: Alawada ni ẹgbẹ ACF ati Miyetti Allah"

Bẹẹ ba gbagbe, ẹgbẹ Arewa ati Miyetti Allah lo koro oju si awọn igbesẹ ti Sunday Igboho gbe, ti wọn si n pariwo pe ki ijọba gbe ti si ahamọ, bẹẹ ni wọn ni ogun le waye.

Gani Adams

Oríṣun àwòrán, Iba Gani Adams

Amọ ninu ọrọ rẹ, Gani Adams ni alawada lasan ni ẹgbẹ mejeeji naa, bẹẹ si ni ko si irufẹ idunkooko to wu ki wọn se, ti oun ko ni fi daabo ilẹ Yoruba lọwọ awọn darandaran apaniyan.

"Yoo dara ki awọn ẹgbẹ mejeeji lati apa oke ọya naa sọ ọrọ ti wọn n sọ jade, bi bẹẹ kọ, wọn yoo ri ibinu ilẹ Yoruba.

Bi wọn se n sọ ọrọ arunilayasoke yii tumọ si pe ẹkun ariwa Naijiria n lu ilu ogun amọ a ko ni gba ki wọn sọ ilẹ Yoruba di ibudo ogun."

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba ni iwadi oun fihan fihan pe taa ba wo awọn ohun to n waye lori ayelujara lẹnu ọjọ mẹta yii, o ti foju han pe awọn ọta kan wa ninu ile ati nita ẹkun iwọ oorun guusu Naijiria.

O ni "awọn eeyan yii lo n lo iwa akọni Sunday Igboho lati dete iwa ibanilorukọ jẹ si mi, ti wọn si fẹ fi gbogbo iwa akikanju, laalaa ati aayan mi lati ọdun mejidinlọgbọn sẹyin sinu idanwo."

Adams ni bi oun se dakẹ lati ọjọ mẹta sẹyin ko safihan pe ojo ni oun, amọ gẹgẹ bi ipo oun bii Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, o di dandan ki oun gbe igbesẹ lasiko to ba yẹ.

Bakan naa lo ni oun gbọdọ fikunlukun pẹlu awọn eeyan, ki oun to le gbe igbesẹ kankan.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọ̀n bàbá wa

"Ohun ti Igboho sọ ko buru rara to ipe fun ogun abẹle ti ẹgbẹ Arewa ati Miyetti Allah lapapọ n pe, o si seni laanu pe ijọba apapọ dakẹ lai fọhun pẹlu isoro awọn darandaran apaniyan yii.

Iwadii ti fihan pe awọn ọmọ Yoruba to le ni ọọdunrun ni wọn ti jade laye lati ọwọ Fulani darandaran ni ọpọ agbegbe nilẹ Yoruba.

Bakan naa ni ọpọ ni wọn ti ji gbe salọ, tawọn ẹbi wọn si san owo ti apapọ rẹ le ni aimọye biliọnu naira gẹgẹ bii owo itanran."

Àkọlé fídíò, Lawal Ayankemi Oluwatoyin: Mo kọ̀ láti máa tọrọ owó nítorí ojú mi tó fọ́, iṣẹ́ ló wù mí

Gani Adams kasẹ ọrọ rẹ nilẹ pe, lati igba ti awọn Fulani ti wọ ilẹ kaarọ Oojire lọdun 1818, ni wọn ti se ọpọ ijamba lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria.

O ni o si foju han pe guusu Naijiria ni afojusun wọn, idi si ree to fi jẹ pe ẹnikẹni to ba tako awọn Fulani darndarn ti di ọta awọn eeyan ẹkun ariwa Naijiria.