Sunday Igboho: Bí ń kò bá jẹ́ èèyàn dáadáa, Ọlọ́run kò ní ṣe oun dáadáa fún mi

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Instagram sunday_igboho

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ilumọọka agba awujọ kan, Oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ eeyan mọ si Sunday Igboho ti yari kanlẹ pẹlu awọn eeyan to n sọrọ aidaa nipa rẹ.

Igboho gbọnmu lori iwa aidaa ti awọn eeyan naa n hu si loju opo Instagram rẹ ninu fidio kan to ju sibẹ lọjọ Aiku.

Sunday Igboho, ẹni to wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ pẹlu ọrẹ rẹ kan lo n sọrọ naa lowe lowe, lai darukọ awọn to n ba wi.

Amọ o daju pe Igboho ni awọn eeyan kan lọkan to n tahun si ninu fidi o.

Gbajumọ awujọ naa ni oun dupẹ lọwọ Ọlọrun Ọba to se oore daadaa fun oun, bi oun ba si jẹ eeyan radarada ni, Ọlọrun ko se nnkan daadaa fun oun.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọ̀n bàbá wa

"Bi eeyan ba lowo laye, yoo lowo lọrun ni, bi eeyan ko ba si jẹ nnkan kan laye, ko lee jẹ nnkan lọrun.

Awọn to maa n bu eeyan, ẹ ri pe awọn talaka ti ko ba nkankan mu ni, awọn ọta Ọlọrun ni wọn nitori awọn ti Ọlọrun ba se daada fun, ọta Ọlọrun nii maa tẹ wọn tabi ba wọn jẹ."

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

O fikun pe o yẹ kawọn eeyan fura si awọn to ba kundun ki wọn maa pẹgan eeyan ẹlẹgbẹ wọn, o ni awọn ti ko jẹ nnkan kan ni, nitori ẹni to ba jẹ nnkan ko ni bawọn pẹgan eeyan laelae.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọdọọdún làwọn ọmọ ònilẹ̀ ń dà wá láàmú ní Soka, kí Sunday Igboho tó gbà wá sílẹ̀ - Àwọn olùgbé Soka

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Instagram/Sunday Igboho

Awọn olugbe agbegbe Soka niluu Ibadan ṣe alaye fun ikọ BBC Yoruba wi pe, lati nnkan bii ọdun mẹta sẹyin ni wahala awọn ọmọ onilẹ ti n waye ni lemọlemọ ni adugbo naa ki o to di wi pe Sunday Igboho da sii lọdun yii.Ọpọlọpọ awọn ogiri ile ni wọn ṣe ami si wi pe, awọn ọmọ onilẹ ti gbẹsẹ lee pẹlu atilẹyin ile ẹjọ giga, lasiko ti ikọ BBC Yoruba ṣe abẹwo si agbegbe naa lowurọ Ọjọ Ẹti.

Awọn olugbe agbegbe naa to ba wa sọrọ labẹ aṣọ ṣalaye pe, pupọ ninu awọn abulẹṣowo to ta ilẹ fun awọn lo ti di oloogbe.

Awọn ọmọ awọn oloogbe naa lo wa yirapada di ọmọ onilẹ to n ṣoro bi agbọn, pẹlu ẹsun wi pe ọna aitọ ni wọn gba ra awọn ilẹ naa.

Ara awọn ile ti awọn ọmọ onilẹ sami si lati gba ni Soka

Ọkan lara awọn olugbe agbegbe naa, ti o ni ki a fi orukọ bo oun laṣiri ṣe alaye wi pe, igba mẹfa ọtọọtọ ni awọn ọmọ onilẹ ti lọ gba aṣẹ ile ẹjọ lati gbẹsẹ le awọn ilẹ ti awọn eeyan ti kọle si lori, ni agbegbe Soka.

Ara awọn ile ti awọn ọmọ onilẹ sami si lati gba ni Soka

O tẹsiwaju wi pe, "ohun to maa n gbẹyin ọrọ lọpọ igba ni ki awọn ọmọ onilẹ naa gba owo ibọbẹ lẹyin idunkukulaja wọn, ṣugbọn airi owo gba lọdun yii lo da gbọmi si omo o to silẹ."

Ara awọn ile ti awọn ọmọ onilẹ sami si lati gba ni Soka

"Awọn ọmọ onilẹ naa ko ọlọpaa lẹyin, t'oun ti aṣẹ ile ẹjọ gẹgẹ bi iṣe wọn lọsẹ yii. ki ilumọọka ajafẹtọmọniyan Sunday Igboho to gbẹna woju wọn.Lati ọjọ Isẹgun ti isẹlẹ naa ti waye, awọn olugbe agbegbe naa ṣe alaye wi pe, awọn ko tun tii ri ọmọ onilẹ kankan mọ ni agbegbe Soka niluu Ibadan.