Ondo, Edo governorship election: Wo ìdí tí oò fi ní lè wọ Amẹ́ríkà bí o bá lọ́wọ́ sí rírú òfin ìbò

Aarẹ Trump

Oríṣun àwòrán, Donald Trump/Instagram

Ijọba ilẹ Amẹrika ti ni ko ni si fisa fun awọn kan to lọwọ ninu makaruru idibo inu osu kọkanla ipinlẹ Kogi ati Bayelsa ati gbogbo rogbodiyan to ti ba imurasilẹ idibo Edo ati Ondo ti yoo waye lọjọ satide ọsẹ yii ati ti ọjọ kẹwa oṣu kewa to n bọ yii rin.

Botilẹ jẹ pe idibo ko tii waye ni Edo ati Ondo, akowe agba orile-ede Amẹrika Mike Pompeo fofin fisa Amẹrika de awọn ẹniyan kan nitori ipa ti wọn ko bi eto idibo awọn ipinlẹ mejeeji yii se n bọ lọna.

Gẹgẹ bi atẹjade ti agbẹnusọ eka Morgan Ortagus fọwọ si lọjọ aje ṣe sọ "ko ni fisa ilẹ Aměrika gbigba fun wọn.

Àkọlé fídíò, Ìtàn ọ̀rẹ́ tó fi ògùn gba ọkọ ọ̀rẹ́ rẹ̀ ni Akomolede BBC Yorùbá fẹ́ kọ́ wa lònìí

Gẹgẹ bi wọn se ko atẹjade naa:

"Ni ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu keje, ọdun 2019, a kede pe a fi ofin de gbigba fisa awọn ọmọ Naijiria kan ti wọn lọwọ si magomago idibo ni inu oṣu keji ati ikẹ̀ta ọdun 2019."

" Loni, akowe agba ilẹ Amerika n fi awọn miran kun awọn ti ofin fisa gbigba de nitori ipa ti wọn ko bi eto idibo inu osu kẹsan ati ikẹwaa ṣe n bọ ni Edo ati Ondo

"Awọn eniyan wọnyi huwa aitọ lai fi ti ipa to ni lara awọn ọmọ Naijiria ṣe ati nkan ti o ṣe fun eto ijọba awa ara wa ni Naijiria.

Botilẹ jẹ pe ijọba ilẹ Amerika ko dárúkọ awọn ti ọrọ naa kan, sugbọn o ni igbesẹ awọn ni lati tubọ mu eto iṣejọba awa ara wa ni Naijiria gbopọn sii

"Ẹwẹ atẹjade naa fi ku pe, awọn eniyan kan ni ifofinde yii n ba wi kii ṣe awọn ọmọ Naijiria lapapọ

Àkọlé fídíò, 'Aràrá bíi tèmi, kó má rò pé kò sì ǹkan tó lè ṣe láyé ju iṣẹ́ agbe lọ'

'Ẹ ki ọwọ́ ọmọ yín b'ọṣọ lásìkò ìdìbò gómìnà Edo àti Ondo, bíbẹ̀ẹ́ kọ́...'

Ọga Agba ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria, Mohammed Adamu, ti kilọ fun awọn oloṣelu ni ipinlẹ Edo ati Ondo, to n kopa ninu idibo si ipo gomina l'oṣu Kẹsan, ati ikẹwa.

Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹsan-an, ni idibo yoo waye ni ipinlẹ Edo, ti ipinlẹ Ondo, yoo si waye ni ọjọ kẹwa, oṣu Kẹwaa.

Adamu sọ pe dandan ni fun gbogbo awọn oludije, ati alatilẹyin wọn lati pa ofin orilẹ-ede Naijiria mọ, lai si rogbodiyan kankan.

Oriṣiriṣi iṣẹlẹ lo ti n waye ni agbo oṣelu nipinlẹ Edo, paapa lẹyin ti gomina Godwin Obaseki fi ẹgẹ oṣelu APC silẹ, to si darapọ mọ PDP, nitori pe wọn ko fun ni tikẹẹti ẹgbẹ.

Lara awọn iṣẹlẹ to ti waye ni bi wọn ṣe yọ olori ile aṣofin ipinlẹ naa.tyn

Ìkúnlẹ̀ ló bá dé fún Oshiomole, Ize-Iyamu láti bẹ̀bẹ̀ fún ìbò aráàlú ní Edo

Edo 2020

Oríṣun àwòrán, Twitter

Àkọlé àwòrán, Idibo sipo gomina ni ipinlẹ Edo naa yoo waye ni Ọjọ Kọkandinlogun, Oṣu Kẹsan, ọdun 2020.

Bi ere itage lo ri ni Ọjọ Aiku nigba ti Alaga ẹgbẹ oṣelu APC tẹlẹri, Adams Oshiomole ati oludije ẹgbẹ oṣelu APC, Osagie Ize-Iyamu kunlẹ lori ẹsẹ mejeeji fun awọn eniyan ni asiko ti ẹgbẹ oṣelu APC lo ṣe ipolongo rẹ ni ilu Benin.

Oshiomole ati Osagie Ize-Iyamu naa kunlẹ bẹbẹ fun awọn eniyan lati ṣe agbatẹru fun wọn ni asiko idibo to n bọ nipinlẹ Edo naa.

Aafin ọba Edomwonyi Iduozee Ogiegbean, Enigie ti ilu Egbaen ni ipolongo idibo naa ti waye.

Edo 2020

Oríṣun àwòrán, Twitter/Osagie Ize-Iyamu

Idibo sipo gomina ni ipinlẹ Edo naa yoo waye ni Ọjọ Kọkandinlogun, Oṣu Kẹsan, ọdun 2020.

Oludije lẹgbẹ oṣelu APC naa lo asiko naa lati kede ipolongo rẹ ati awọn ohun ti yoo gbeṣe ti oun ba bori ninu idibo to n bọ naa. O pe akọle ipolongo naa ni ‘SIMPLE agenda manifesto’.

Edo 2020

Oríṣun àwòrán, Twitter/ Osagie Ize-Iyamu

Lara ohun ti Ize-iyamu ni oun yoo ṣe ni lati jẹ ki eto aabo gbooro si ni ipinlẹ Edo ati lati pese owo iranwọ fun awọn ọdọ fun idokowo.

Edo 2020

Oríṣun àwòrán, Twitter

O fikun pe oun yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn lọbalọba ni ipinlẹ naa fun ijiroro lori ọna ati mu nkan lọ deede fun awọn to wa ni awọn ilu kereje-kereje.

Edo 2020

Oríṣun àwòrán, Twitter/Osagie Ize-Iyamu

Osagie Ize-Iyamu naa dupẹ lọwọ awọn lọbalọba to wa ni bẹ fun atilẹyin wọn, ti o si bẹ wọn lati ṣe atilẹyin fun oun nigba ti asiko idibo ba de ni Osu Kẹsan.

Ìpolongo ìbò Obaseki mú làásìgbò lọ́wọ́ láàfin Ọba Benin, èèyàn mẹ́wàá farapa

O kere tan eniyan mẹwaa ni wọn wa ni ile iwosan lẹ̀yin ti ija bẹ silẹ, laarin awọn onijagidijagan to n ṣe atilẹyin fun gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki ati Pasitọ Osagie Ize-Iyamu to n dije labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP.

Gomina Obaseki naa n ṣe iṣide ipolongo rẹ saaju idibo sipo gomina ni ipinlẹ Edo ti yoo waye ni Ọjọ Kọkandinlogun, Oṣu Kẹsan, ọdun 2020.

Edo 2020

Oríṣun àwòrán, Others

Nibi ipolongo idibo to waye ni aafin Ọba Benin, Ọba Ewuare 11 ni ija ti bẹ silẹ, ti ọpọlọpọ dukia to fi mọ ọkọ ayọkẹlẹ, awọn asia ipolongo ni wọn bajẹ ni agbegbe naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ikọ ipolongo Obaseki da ẹbi rogbodiyan naa ru ikọ ẹgbẹ oṣelu APC, to jẹ alatako rẹ.

Ninu ọrọ tirẹ, Ọba Ewuare pe fun adura lọwọ awọn alalẹ lati gba fun wọn, ki idibo naa lọ ni irọwọrọsẹ.

Awọn ikọ olupolongo ibo fun gomina Obaseki

Oríṣun àwòrán, @GovWike

Ọba Ewuare ke si awọn oloye rẹ lati bẹrẹ adura ni kankan lati jẹ ki alaafia jọba lasiko idibo to n bọ lọna naa.

Ija naa bẹrẹ nigba ti gomina Obaseki to n dari awọn alatilẹyin rẹ lọ si aafin ọba koju awọn onijagidijagan to di oju ọna ati kọja wọn pẹlu ibọn, igo ati ọpọlọpọ ohun ija oloro.

Bi awọn alatilẹyin Obaseki ṣe n rapala wọ afin ọba naa ni awọn alatilẹyin Osagie Ize-Iyamu na n bu wọn.

Àkọlé fídíò, Hospital Wedding: Oṣù kan péré ni Tash fi ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Simon kó tó kú

Lẹyin eyi ni ija bẹ silẹ, ti Gomina Obaseki si kuro nibẹ lọ si papa iṣere Samuel Ogbemudia to wa ni ilu Benin, ni ipinlẹ Edo.

Obaseki ni ibi ipolongo naa sọ fun awọn alatilẹyin rẹ pe ẹgbẹ oṣelu APC lo fa rogbodiyan naa, ti o si pẹtu si wọn lati maṣe gba ẹsan lara wọn.

Ninu ọrọ ti wọn, ẹgbẹ oṣelu APC daun pe Gomina Obaseki ati awọn ololufẹ rẹ gangan lo n fa wahala ati rogbodiyan ni ipinlẹ naa.

Wo àwọn tí wòlíì ríran sí pé COVID-19 yóò pa ní ìpínlẹ̀ Edo l'óṣù kẹsàn án

Ibo pataki meji ni awọn oloṣelu Naijiria n gbaradi fun lorilẹede yii bayii lọdun yii.

Obaseki ati Iyamu

Oríṣun àwòrán, others

Akskọ ni ibo gomina ni ipinlẹ Edo.

Ekeji si ni ibo gomina ni ipinlẹ Ondo.

Amọṣa ilumọọka wolii kan, Primate Elijah Ayọdele ni oun ti gba asọtẹlẹ idajọ Ọlọrun fun ẹnikẹni to ba gbiyanju ati ṣe eru lasiko idibo to n bọ ni ipinlẹ Edo.

Primate Elijah Ayọdele sọ eyi ninu atẹjade asọtẹlẹ kan to gbe jade.

O ni Ọlọrun ti fi ẹni ti yoo bori idibo naa han oun ati pe ẹnikẹni to ba gbiyanju ati tọwọ bọ idibo naa lati eru yoo fori ko idajọ Ọlọrun.

Àkọlé fídíò, Prophecy 2020: Adeboye àti Ayọdele sọ nípa ọjọ́ ìwájú 2020

Primate ni Ọlọrun ti fi han oun pe arun coronavirus ni yoo pa ẹnikẹni to ba gbiyanju lati doju ibo ru ni ipinlẹ.

"COVID-19 ni yoo pa ẹnikẹni to ba ṣe eru ibo"

Ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹsan an, ọdun 2020 ni ibo sipo gomina ni ipinlẹ Edo yoo waye.

Àkọlé fídíò, Kogi vs Bayelsa: Primate Ayodele sọ àsọtẹ́lẹ̀