Eid el Kabir: Àwọn ohun mẹ́sàn án tí Mùsùlùmí gbọdọ̀ ṣe nínú oṣù Dhual rèé

Ka'aba ni Makkah

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Anabi Muhammad (SAW) sọ pe ko si ọjọ kankan to ṣe koko julọ ninu ọdun kan ju ọjọ mẹwaa akọkọ ninu oṣu Dhu al- Hijjah.

Awọn onimọ ti rọ awọn Musulumi lati mu ọjọ mẹwaa akọkọ oṣu Dhul Hijjah lẹyin ti wọn ti kede ọjọru gẹgẹ bi ọjọ kinni, oṣu kejila kalẹnda musulumi.

Awọn Musulumi maa ri ọjọ mẹwaa akọkọ oṣu Dhul al- Hijjah gẹgẹ bi eyi to se pataki julọ niwaju Ọlọrun.

Bakan naa ni wọn ni gbogbo adura ati aawẹ ti Musulumi ba se ni ọjọ naa yoo goke arafa lọ ni ibi ti o sunmọ Ọlọrun julọ

Sheikh Aminu Ibrahim Dauraea to jẹ ilumọọka onimọ ẹsin Islam ni orile-ede yii salaye fun BBC nipa gbogbo awọn nkan to rọ mọ Oṣu Dhu al- Hijjah ati awọn nkan ti musulumi gbọdọ ṣe.

Àkọlé fídíò, Working religious women: Ẹ̀lẹ́hàá kìí ṣe ọ̀lẹ- Aminat Adegoke

Ma ṣe ge irun tabi fa eekanna rẹ

Nkan akọkọ ni pe ti enikan ba n gbiyanju lati se aluwala, lati ọjọ akọkọ, oṣu Dhu al - Hijjah, ma se ge eekanna rẹ tabi ki o fa irun kankan lara.

Nitori pe Allah (SAWA) yoo se alekun ati ibukun si irun kọọkan ati bi eekanna naa ba ṣe gun to, titi di asiko ti yoo fi ge irun rẹ tabi eekanna.

Gba aawẹ lọjọ Arafa

Gẹgẹ bi Sheikh Daurawa sr sọ, nkan ikeji ni lati gba aawẹ lọjọ Arafa.

Hadiiti sọ pe aawẹ lọjọ Arafa maa n pa gbogbo ẹsẹ ọdun to kọja ati eyi to n bọ rẹ

Irubọ/Itọrẹ

Nkan kẹta, o ṣe pataki lati ṣe itọrẹ aanu, eyi tọ sunnah Anabi Ibrahim (SAWA) ti Allah pa laṣẹ gẹgẹ bi adanwo lati fi ọmọ rẹ rubọ, o setan lati ṣe ki Ọlọrun to fi Agbo rọpo ọmọ rẹ.

Lọ si Yidi

O ṣe pataki bakan naa ki eniyan lọ fun adua yidi lọjọ ọdun ileya, ki eniyan si wọ asọ tuntun.

Ti oo ba wa ni aṣọ tuntun; o ṣe pataki lati wọ eyi to dara ju ninu awọn aṣọ ti o ni.

O gbọdọ dara si awọn ẹbi rẹ ki o si ra aṣọ tuntun fun wọn ti o ba lagbara rẹ, ki wọn si lọ yidi pẹlu awọn obinrin.

Oṣu aawẹ ni Dhu al- Hijjah

Yatọ si pe o gba aawẹ lọjọ Arafa, o ṣe pataki lati gbawẹ lati ibere lẹẹkan oṣu naa.

Fikun iṣẹ oore ṣiṣe

O ṣe pataki lati maa ṣe saara nigbagbogbo ni oṣu Dhu al-Hijjah

Bi apẹrẹ, ti o ba n sẹ ọrẹ ẹgbẹrun kan Naira, o ni lati fi kun un tabi ki o ṣe ni ilopo

Nkan miran tun ni pe ẹni ti ko ba lọsi Hajj ọdun yii, o yẹ ko fi ilaji owo rẹ ra ounjẹ ati aṣọ fun awọn alaini, iṣẹ oore naa ni.

Ṣe abẹwo si awọn ọrẹ ati ẹbi rẹ

Nkan to yẹ Musulumi ni lati maa ṣe abẹwo si ẹbi ati ọrẹ ninu oṣu yii

Kikọ itẹ oku

O ṣe pataki lati ṣe afikun iye awon itẹ oku ni asiko oṣu ibukun yii.

O se pataki lati kọ awon saare oku ti wọn o kọ akọle bii Allahu Akbar, Allahu Akbar, La'ilaha illalLah Allahu Akbar, Allahu Akbar walillahil hamdu sii

Àkọlé fídíò, Saudi Arabia Hajj 2020: Alaga Hajj ni Naijiria ni inú wọn kò dùn sí bí Hajj kò ṣe ní wáyé.

Lilọ Hajj

O ṣe pataki lati lọ Hajj tabi Umurah.

Onimọ naa sọ pe awọn iṣesi yii lo ti ṣe akotan gbogbo opo ẹsin musulumi.

Idi niyi ti won ṣe rọ musulumi lati tiraka lati ṣe gbogno nkan wọnyi ninu oṣu mimọ yii.

Àwùjalẹ̀ wọ́gilé Ojude Oba; Ganduje náà wọ́gilé ayẹyẹ lẹ́yìn ìrun ọdún Iléyá nítori Covid 19

Ọkan lara awọn ayẹyẹ to ma n waye lasiko ọdun ileya ni Hawan Sallah

Oríṣun àwòrán, Manuel Toledo

Àkọlé àwòrán, Ọkan lara awọn ayẹyẹ to ma n waye lasiko ọdun ileya ni Hawan Sallah

Oriṣiriṣi eto amuludun, to fi mọ ẹṣin gigun lo ma n waye lasiko ọdun Ileya nilẹ Hausa.

Arun coronavirus si ni ijọba sọ pe o mu ki wọn o fagile adura Eid l'ọdun yii, lati ri i pe ero ko pọju ki aarun naa ma ba a tun ran si.

Iyalẹnu ni adura Eid ti ko ni i waye jẹ fun awọn kan nilu Kano, nitori pe ko si isede mọ, ati pe ọdun ileya akọkọ niyii ti Emir ilu Kano, Alhaji Aminu Ado Bayero, yoo ṣe lori itẹ.

Kii ṣe ilu Kano nikan ni yoo ṣafẹẹri ọdun adura Eid, ọrọ yii kan awọn ilu nla bi i Rano, Gaya, Karaye, ati Bichi to wa ni ipinlẹ Kano.

Awọn to wa lori ẹsin

Oríṣun àwòrán, NTDC TWITTER

Ṣugbọn ṣa, eyi kọ ni igba akọkọ ti wọn fi ofin de adura agbapọ, nitori awọn idi l'oriṣiriṣi.

Laarin ọdun 1981 si 1983, ayẹyẹ Hawan Sallah ko waye, nitori aawọ to wa laarin gomina igba naa, Abubakar Rimi, ati Emir to wa lori oye.

Ayẹyẹ Hawan Sallah jẹ eto pataki, ninu eyi ti Emir ti ma n gun ẹṣin yipo ilu Kano, ti awọn eeyan yoo si ma a kan saara si.

Bakan naa lọdun 2012, Igbimọ lọbalọba ilu Kano, fi ofin de adura Eid, nitori pe ara Emir ilu Kano nigba naa, Alhaji Ado Bayero ko ya.

Eyi ko ṣẹlẹ ri lati bi igba ọdun ti adura Eid ti n waye nilu Kano.

Amọ ero awọn kan yatọ lori eyi, igbagbọ wọn ni pe irẹpọ ti ko si laarin igbimọ lọbalọba ati ijọba ipinlẹ Kano, lo fa igbesẹ naa.

Eto adura ko tun waye lọdun 2013. Ayẹyẹ kankan ko si waye titi di ọdun 2014, lẹyin iku Emir Ado Bayero.

Ganduje

Oríṣun àwòrán, @KSG

Ọdun 2019 ni ijọba ipinlẹ Kano,tun fi ofin de eto adura, eyi to ba awọn ọdọ ati awọn ọmọbinrin lọkan jẹ pupọ.

Bo tilẹ jẹ pe eto aabo nijọba sọ pe o fa igbesẹ naa, o foju han pe nitori ija to wa laarin igbimọ lọbalọba ati ijọba lo fa a.

Eto adura ko tun waye lasiko itunu awẹ ọdun 2020, nitori itankalẹ coronavirus.

Bakan naa ni ọmọ ṣori ni ipinlẹ Ogun lọdun yii:

Kò ní sí ayẹyẹ ọdún Ojúde Oba lọ́dún yìí- Awujale ilẹ̀ Ijebu

Ọba Sikiru Adetona ti ilẹ̀ Ijebu ti kéde pé ayẹyẹ ọdún Ojude Oba kò ní wáyé lọ́dún yìí.

Ojude Oba festival: Kò ní sí ayẹyẹ Ojúde Oba lọ́dún yìí nítorí Coronavirus- Ọba Sikiru Adetona

Ojude Oba

Oríṣun àwòrán, @officialpcm

Awujale ati alaṣẹ agba ilẹ Ijebu, Ọba Sikiru Adetona ti kede pe ayẹyẹ ọdun Ojude Oba tọdun 2020 ko ni waye nitori arun Covid-19.

Ajakalẹ arun coronavirus yii lo n gba ẹbọ lọwọ gbogbo agbaye lati oṣu kejila, ọdun 2019 to ti bẹrẹ ni China.

Ohun naa lo si ti mu ayipada ba eto ẹkọ, irin ajo afẹ ati awọn nkan ọlọdọọọdun miran kaakiri agbaye

Ojude Oba

Oríṣun àwòrán, @folastag

Àkọlé àwòrán, Kò ní sí ayẹyẹ ọdún Ojúde Oba lọ́dún yìí- Awujale ilẹ̀ Ijebu

Oba Adetona lo kede pe Covid 19 yii ko ni jẹ ki ọdun yii waye ninu atẹjade kan ti Ebumawe ti Ago-Iwoye, Oba A.A. Adenugba fọwọ si.

O ni o ṣe pataki ki ayẹyẹ ọdun ọhun ma waye nitori ajakalẹ arun Coronavirus to n ba gbogbo agbaye finra, ti ko si yọ Naijiria sẹyin.

Oba ọhun rọ awọn ara ilu lati tẹle gbogbo ilana ti ajọ NCDC gbe kalẹ bii ọwọ fifọ loorekoore ati ijinasiraẹni lawujọ lọna ati le arun naa lọ.

Lẹyin naa lo parọwa si awọn ọmọ bibi ilẹ Ijebu lati ṣe ọdun ọhun laaye ara wọn lai si ariwo.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ọdun Ojude Oba maa n waye lọdọọdun ni ọjọ kẹta ọdun Ileya ti awọn Musulumi maa n ṣe.

Ṣaaju ni Ijọba Kano na ti paṣẹ pe:

Ijọba Kano wọgile ayẹyẹ to maa n waye lẹyin irun ọdun Ileya:

Ko tan sibẹ o, ijọba ipinlẹ naa tun ti wọgile ayẹyẹ ọdun ileya ọdun 2020 nitori Covid-19.

Lojuna ati fopin si itankalẹ aarun Coronavirus ni ipinlẹ Kano, ijọba ti kede lọjọru pe oun wọgile gbogbo ayẹyẹ ọdun Eid-el-Kabir.

Apejọpọ Hawan Daushe ti Emir maa n bẹ gomina wo nile ìjọba l'agbegbe Shettima House laarin awọn ayẹyẹ to ku ko ni waye.

Kọmísọ́nnà fun ọrọ to n lọ ni Kano, Muhammed Garba, sọ pe eyi jẹ ọkan lara igbese ijọba lati tubọ tesiwaju ninu aseyọri rẹ lati gbogun ti aarun Covid-19.

Eid-el-Kabir jẹ ayẹyẹ to mọ julọ ti awon misulumi maa n se lati buyi kun ifẹ Ibrahim to gba lati fi ọmọ rẹ rubọ, ni igbọran si aṣẹ Ọlọrun

Garba ni ipinnu ijọba yii ko sẹyii ifẹnuko igbimọ alaṣẹ leyin ipade to waye.

O ni àwọn igbimọ fẹnuko pe ki awon eniyan kirun janmọ jakejado ipinlẹ Kano, sugbọn ki wọn tẹle ilana ijina sira ẹni ati gbogbo ilana lati dẹkun aarun Covid19 ni agbegbe ibi irun janmọ

Àkọlé fídíò, Olofa ina: ẹ parí òwe yìí pé ìgbà tí ara bá tu ìgbẹ́ láà ri eṣú....

Garba kede pe ijọba yoo pese gbogbo awon nkan aabo ti won yoo nilo, bii iboju ati 'hand sanitizer' ti won yoo lo.

O ni: "Gbogbo Emir Kano Maraarun ni yoo lọ yidi ni agbegbe wọn ninu mọtọ."

"Awọn alaṣẹ ijọba kọọkan ni yoo samoju to eto yidi ni agbegbe wọn lati rii daju pe awọn olujọsin tẹle ilana ijọba lori Covid-19 "Alaye Garba ree"

Bí Coronavirus ṣé jẹ́ kí Awujalẹ wọ́gilé Ojúde Ọba ní Ijẹbu-Ode, bẹ́ẹ̀ náà ló tún ti jẹ́ kí Ganduje wọ́gilé ayẹyẹ 'Hawan Daushe' to máa n waye ninu ọdun Ileya ni Kano.