Lagos Jumat Mosques: Títì pa ni ìlẹ̀kùn àwọn mọ́ṣáláàṣí kan wà ní ìpínlẹ̀ Eko lásìkò ìrun Jímọ̀

Paroparo ni mọṣalaaṣi to wa ni Lekki ati Ikoyi dá

Paroparo ni awọn mọṣalaaṣi kan da nilu Eko, lasiko irun Jimọ to yẹ ko waye.

Eyi yani lẹnu botilẹjẹ pe ijọba ipinlẹ Eko ti kede pe ki awọn ile ijọsin bẹrẹ sini ṣi pada lati ọjọ Jimọ, ọjọ keje, oṣu Kẹjọ, lẹyin oṣu bi i maarun ti wọn ti ti ilẹkun wọn nitori isede aarun coronavirus.

Lasiko ti akọroyin BBC kan de awọn mọṣalaaṣi bi ti Ikoyi ati Lekki lati kirun, titi pa ni awọn ilẹkun ibẹ wa lai si irun Jimọ.

Ṣugbọn ṣa, irun Jimọ waye ni awọn mọṣalaaṣi kan.

Aworan olujọsin ni Mọsalasi

Awọn musulumi nipinlẹ Eko yoo laanfani lati kopa ninu irun Jimọ loni lẹyin nkan bi oṣu mẹrin ti ijọba fofin de akojọpọ lawọn ile ijọsin.

Awọn ṣọọṣi naa yoo ṣi pada lọjọ Aiku.

Lati oṣu kẹta ọdun 2020 ni ijọba ti ni ki wọn sọ agadagodo sawọn Mọṣalaṣi ati Ṣọọṣi nitori ajakalẹ arun Covid-19.

Àkọlé fídíò, Kwara: Fọ́fọ́fọ́ ni mọ́ṣáláṣí kún tí ìlànà ìjìnàsíraẹni 'social distancing' sí forí

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu sọ pe igbesẹ ṣiṣi awọn mọṣalaṣi yi jẹ apẹrẹ pe Naijiria n tẹsiwaju ninu idoju ija kọ arun Covid-19.

Ṣugbọn ṣa ijọba ni ida meji awọn to ba yẹ ko wa ni aaye ijọsin naa ni awọn yoo faye gba lati jọsin.

Bẹẹ ni wọn ni awọn olujọsin gbọdọ tẹle ilana bi wiwọ ibomu,fifọ ọwọ ati ijinasiraẹni lasiko ti wọn ba n kirun.

Ìjọba Nàìjíríà fi ọ̀sẹ̀ mẹ́rin kún ìséde ààrùn Coronavirus

Aarẹ Muhammadu Buhari ti fi ọwọ si afikun ọsẹ mẹrin si abala keji didẹwọ isede coronavirus.

Akọwe ijọba apapọ, to tun jẹ Alaga fun igbimọ to n mojuto itankalẹ aarun Covid-19, Boss Mustapha, lo kede eyi lasiko ti o n ba ara ilu sọrọ l'Ọjọbọ.

O ni isede to n bẹrẹ laago mẹwa alẹ ṣi wa sibẹ.

Mustapha sọ pe igbesẹ yii waye lati le fi idi aṣeyọri ti Naijiria ti n ṣe lori igbogbun ti aarun coronavirus mulẹ.

Àkọlé fídíò, Ìdílé tí ọkọ da ọmọ síta tóríi ojú Búlùú tí wọ́n ní bá BBC sọ̀rọ̀

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, àwọn ayipada ti yoo kan wa ni pe wọn yoo bẹrẹ si ni ṣi papakọ ofurufu fun irinajo si ilẹ okeere diẹdiẹ, ni ibamu pẹlu awọn ilana to yẹ.

Igbimọ amuṣẹya naa sọ pe ki awọn ileeṣẹ baalu to n rinrinajo lọ silẹ okeere, ati awọn alaṣẹ papakọ ọk ofurufu bẹrẹ igbaradi fun ṣiṣi irinajo silẹ okeere.

Awọn nkan mii to tun wa ninu ilana tuntun naa

Bakan na ni irinajo ọkọ oju'rin naa yoo bẹrẹ pada.

Ṣugbọn ko gbọdọ si irinajo laarin ipinlẹ kan si omiran lasiko isede fun awọn arinrinajo loju popo.

Botilẹjẹpe ofin ṣi de awọn ile faaji, ijọba sọ pe oun ti gbẹsẹ kuro lori ofin to de lilọ si awọn ọgba igbafẹ, ṣugbọn ko gbsdọ si ifarakan ara nibẹ.

Ko tan sibẹ o, Ọgbẹni Mustapah tun kede pe awọn eero ọkọ baalu labẹle le ma a de si papakọ ọkọ ofurufu ni wakati kan ataabọ ṣaaju irinajo wọn, dipo wakati mẹta ti ijọba kede tẹlẹ.

Ṣugbọn ṣa, o sọ pe dandan ṣi ni fun gbogbo eniyan lati maa tẹle awọn ilana ti ijọba la kalẹ.

Awọn olutọju alarun Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Others

Ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe ìjọba àpapọ̀ lórí Covid-19 ti fẹdun ọkan wọn han lori bi itankalẹ aarun Coronavirus ṣe n pọ si laarin awọn to n bẹ nì'jọba.

Eyi si ni wọn lo n mu isoro ba eto isejọba ati didaabo bo ilu lọna to yẹ lorilẹ-ede Naijiria.

Alaga igbimọ ọhun, to tun jẹ akọwe ìjọba apapọ, Boss Mustapha lo salaye ọrọ yii lasiko ijabọ bi nkan ṣe lọ fun ara ilu to ma n waye l'Abuja lojoojumọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O sọ ọ di mimọ pe, ṣiṣe ofin konile ogbele tuntun miran le waye lati dẹkun itankalẹ arun yii to n peleke sii.

Akọwe ìjọba wa rọ gbogbo ọmọ Naijiria lati tẹle àwọn ilana to yẹ lati dena aarun Coronavirus nitori pe aarun naa ko mọ olowo tabi talaka.

Àkọlé fídíò, Kemi Dairo: Iṣẹ́ abẹ nínú ọpọlọ àti ẹ̀rọ ni mo fi ń gbọ́ ọ̀rọ̀ báyìí

Ikilọ alaga yii ko sẹyin bi awọn gomina ipinlẹ lọkan o jọkan, ṣe n lugbadi arun naa ni lọọlọ yii.

Laipẹ yii ni Gomina Ondo, Rotimi Akeredolu, Gomina Ebonyi David Umahi ati awọn miran lugbadi aarun naa.

Mustapha wa kilọ fun awọn to wa nipo aṣẹ lati sọra nitori gbogbo awọn to ti lugbadi arun laipẹ ba ṣe aisan, eyi yoo di isejọba lọwọ lati seto ilu ati lati daabo bo wọn.

Awọn olutọju alarun Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Others

"A rọ gbogbo ọmọ Naijiria lati maa foju s'ọri bi alakan, yala o jẹ olowo tabi talaka. Aarun yii ko bikita ipo ti ẹnikẹni wa, sugbọn igbimọ amusẹya ìjọba ko ni sinmi, lati maa ṣe ikilọ ni igba gbogbo."

Ẹwẹ, Boss Mustapha ni, awọn nkan to ba jẹyọ ni awọn ọsẹ to n bọ yii, ni yoo sọ inu odo ti igbimọ naa yoo da ọrunla si lori pe, boya ki ìjọba kede igbele gbogboogbo miran..

"A o le sọ nkan ti yoo sẹlẹ lọjọ iwaju sugbọn nkan to ṣe pataki julọ ni pe, didaabo bo awọn ọmọ Naijiria lo ṣe pataki julọ."

Àkọlé fídíò, Mama Arsenal: Màmá àgbà yìí máa ń lọ sí ìbùdó tí wọ́n ti ń wo bọ́ọ́lù láti wòran

"Lati ṣe eyi, to ba jẹ pe kikede konileogbele lọna abayọ, a o ṣe bẹẹ gẹgẹ.

A o gbe abajade iwadi ati ero wa siwaju Aarẹ lati ṣe ipinnu lori aba igbimọ amusẹṣe, nkan to ba sẹlẹ ni ọṣẹ mẹta si asiko yii ni yoo sakawe igbesẹ ti ijọba yoo gbe."

Ọmọdé yóò máa sọnù ládùúgbò, arúgbó leè kú láì tọ́jọ́, tí wọn bá jókòó sílé lásìkò ìjọsìn - CAN

Awọn olujọsin ni ṣọọṣi

Oríṣun àwòrán, others

Saaju la ti kede pe awọn asaaju ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi (CAN) ti n sọrọ lori aṣẹ ti ìjọba apapọ pa pe, awọn ọmọde ati arugbo ko gbọdọ lọ sile ijọsin.

Nigba ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ lori iṣẹlẹ yii, awọn alaga ẹgbẹ CAN nipinlẹ Oyo ati Ondo, Pasitọ Benjamin Akanmu ati Ayo Oladapo woye pe, ijọba fẹ tete sekupa awọn arugbo ni, ti wọn ko ba ni anfaani lati jade sita.

Lero ti Akanmu, erokero ati iku ojiji ko jinna si arugbo to ba da nikan wa nile, ti aigbọ ọrọ Ọlọrun ni oore koore ko si le ṣe awọn ọmọde loore.

O wa daba pe ki ijọba kesi awọn onimọ ijinlẹ lati tete wa ọna abayọ si arun Coronavirus yii, nitori itọju la nilo, kii ṣe ka gbe ilẹkun ile ijọsin ti pa.

"Ohun to n ba ijọba ipinlẹ Oyo lẹru ni pe awọn eeyan to n lugbadi arun Covid-19 n pọ si dipo ki wọn dinku, eyi lo mu ko tilẹkun ile ijọsin, ẹni to si kan lo mọ, amọ gbogbo ọkan lo n pohungbẹ lati wa sile Ọlọrun, ipa ti adura si n ko, kii ṣe ipa kekere."

awọn eeyan njọsin ni ile ijọsin

Oríṣun àwòrán, others

Ninu ọrọ tiẹ, alaga ẹgbẹ CAN ni Ondo salaye pe, ijọba kan n fi ẹtẹ silẹ, maa pa lapalapa ni nitori awọn onimọ isegun ti kede saaju pe, awọn arugbo ni ko sa fun Covid-19, kii ṣe ọmọde.

Oladapo ni " Ti awọn obi ba lọ sile ijọsin, nibo ni wọn fẹ fi awọn ọmọ wọn si, ṣe wọn yoo tilẹkun mọ wọn sile ni abi wọn yoo ko wọn da si titi? Ijọba apapọ ko ro ero rẹ daadaa ko to gbe sita."

O fikun pe o dara bi awọn arugbo ba joko sile, amọ wahala ni wọn fẹ da silẹ pẹlu ọmọde ti wọn ni ko jokoo sile, tori awọn ọmọde ko ni pẹ maa sọnu ladugbo.

Oladapo, to faramọ awọn ilana tijọba Ondo gbe kalẹ lori ijọsin tun ni, ohun to dara ni bi ijọba ṣe kọkọ tilẹkun ile ijọsin pa nitori igbagbọ ninu Kristi ko ni idiwọ, isẹ Ọlọrun si n tẹ siwaju.