Osun state lockdown update: Awọn òṣìṣẹ́ padà sí ẹnu iṣẹ́ ní ìpińlẹ̀ Osun

Oríṣun àwòrán, twitter/Adegbeoyega oyetola
Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti dẹ ọwọ aṣẹ konile o gbele to gbe kalẹ lati dẹkun itankalẹ arun coronavirus ni ipinlẹ naa.
Ninu atẹjade kan to fi sita lalẹ ọjọbọ, gomina ipinlẹ Ọṣun, Gboyega Oyetọla ṣalaye pe ofin konile o gbele yoo wa silẹ lati maa waye laarin agogo mẹsan si marun un owurọ.
O ni ki gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba lati akasọ igbega keje soke o pada si ẹnu iṣẹ wọn.
Bakan naa lo ṣalaye pe gbogbo awọn ọja nlanla ni ipinlẹ ọhun ni ko ṣi wa ni titi pa, ṣugbọn awọn ọja yooku ti wọn ṣi, awọn ọlọja nibẹ gbọdọ bọwọ fun awọn ilana idaabobo ara ẹni ti ajọ NCDC ati ileeṣẹ eto ilera apaps gbe kalẹ.
Amọṣa o, ọsẹ meji ni wọn yoo kọkọ fi yiri igbesẹ ilana tuntun yii wo.
Funke Olakunrin: Àwọn afunrasí lórí ikú Funke Olakunrin ti wà nílé ẹjọ́ ní Akure

Awọn afunrasi ti ọwọ ofin mu lori iku arabinrin Funkẹ Ọlakunrin to jẹ ọmọbibi aṣiwaju ẹgbẹ afẹnifẹre, Baba Rueben Faṣọranti pada si ile ẹjọ lọjọru nibi ti wọn yoo ti maa farahan niwaju adajọ majisireeti agba ni ilu Akurẹ.
Ni ọjọ kejila oṣu keje ọdun 2019 ni awọn agbebọn kan kọlu ọkọ ti oloogbe Funkẹ Arakunrin wọ ni opopona marosẹ Sagamu si Ọrẹ.
- Ilé ẹjọ́ tún ti sún ìgbẹ́jọ́ Alfa Babatunde Sotitobire síwájú
- Wọ́n tún ti pa ọmọbìnrin míì lásìkò ìbálòpọ̀ tipá nílùú Ibadan
- Wàhálà tí àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn àt'àwọn ẹgbẹ́ ìjayà míràn ń dá sílẹ̀ láwọn ọgbà fásitì Nàìjíríà
- Irú kí lèyì! Pásítọ̀ gún ìyàwó rẹ̀ lọ́bẹ nínú ṣọ́ọ̀ṣì, ló bá tì í bọ ara rẹ̀ náà níkùn
Adajọ majisireeti agba, Victoria Bob-Manuel ti kọkọ gbọ ẹjọ naa ni ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹrin ọdun 2020 to si ni ile ẹjọ ọhun ko laṣẹ labẹ ofin lẹyin to fi buwọlu ẹbẹ olupẹjọ lati fi awọn afunrasi naa si atimọle ki o to sun igbẹjọ wọn si ọjọru ọjọ kẹta oṣu kẹfa.

Awọn afunrasi mẹrin ti wọn pe orukọ wọn ni Auwal Abubakar, Muhammed Shehu Usman, Lawal Mazaje ati Adamu Adamu lawọn agbofinro mu ti wọn si n fi ẹsun igbimọpọ lati paniyan,ipaniyan ati ijinigbe ṣugbọn wọn ko ni agbẹjọro nigba ti ile ẹjọ gbọ ẹjọ naa












