Olumilua: Mimiko ní olóògbé náà kìí ṣe olóṣèlú jẹgúdú-jẹrá, irú rẹ̀ kò sì wọ́pọ̀ mọ́

Olusegun Mimiko

Oríṣun àwòrán, others

Idi ree ti kọmisana tẹlẹ nigba ti oloogbe Bamidele Olumilua jẹ gomina nipinlẹ Ondo ijọun, toun naa si pada jẹ gomina nipinlẹ naa lẹyin rẹ, Dokita Olusegun Mimiko fi n ṣe idaro ọga rẹ, Olumilua, to papoda ni owurọ Ọjọru lẹni ọgọjọ ọdun.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori iku Olumilua, Mimiko ni eeyan gidi ati ẹni Ọlọrun ni ọga oun naa, to si jẹ oselu to nifẹ awọn araalu pẹlu ibẹru Ọlọrun.

Mimiko sọ siwaju pe " igba ti mo ṣíṣẹ labẹ wọn lọdun 1992 gẹgẹ bii kọmisana, wọn kọ wa bi wọn ṣe n fi ara ati ọkan sin ilu, oselu tiwọn kii si ṣe oselu jẹgudu-jẹra, ki la le ri ko, oselu ti wọn fi sin Ọlọrun ati eniyan ni."

"Inu mi dẹ dun pe titi ti wọn fi papoda, n ko jinna si wọn, awọn naa ko si fi mi silẹ ninu gbogbo ipo akoso ti mo dimu, wọn maa n gba mi niyanju, ko dẹ si gbogbo ayẹyẹ ti mo ṣe nigba ti mo wa ni gomina, ti wọn kii wa."

Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ondo naa ni orileẹ-ede Naijiria maa mọ ipapoda Olumilua lara nitori oloselu bii tiwọn ko pọ mọ, to jẹ pe bi wọn ṣe n fi tọkan-tara sin araalu, ni wọn n sin Ọlọrun.

Mimiko wa gbadura pe ogun ti oloogbe Bamidele Olumilua fi silẹ ko ni bajẹ, ti Ọlọrun yoo si tẹ si afẹfẹ rere.

Olumilua: Ọdún kan àti oṣù mẹ́wàá ni Bamidele Olumilua fi ṣe gómìnà ní ìpínlẹ̀ Ondo ijọ́un

Bamidele Olumilua

Oríṣun àwòrán, others

Yoruba ni ọjọ taa dele aye ko to ọjọ ta ba ku, nitori iṣẹ ọwọ wa ni yoo sọ nipa ohun ta ba gbe ile aye ṣe.

Bẹẹ ni ọrọ ri fun gomina tẹlẹ nipinlẹ Ondo ijọun, tii tun ṣe agba oselu ati majẹobajẹ ilu, Bamidele Isola Olumilua to jade laye ni aarọ Ọjọru.

Ni wọn igba to jẹ pe arise ni arika, arika si ni baba iregun, ohun ta ba fi oni ṣe, itan ni yoo da lọjọ ọla, idi ree ta fi ṣe akojọpọ itan igbe aye agba oselu to di oloogbe naa.

Ibi, igbe aye ati iku Bamidele Olumilua:

Olomiluwa

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo n fi ye wa pe Olumilua jade laye ṣugbọn a ko tii lee fi idi iku to paa mulẹ.

Ọdun 1940 ni wọn bi Bamidele silu Ikere Ekiti, o kawe, o gboye rẹpẹtẹ ni Naijiria ati loke okun, ko to dara pọ mọ eto iselu.

Bamidele dara pọ mọ ẹgbẹ oselu Ẹlẹsin SDP ni saa isejọba alagbada kẹta, to si dupo wọle gomina nipinlẹ Ondo ijọun ni oṣu Kinni ọdun 1992.

Lasiko ti Olumilua jẹ gomina, Olusegun Agagu ni igbakeji rẹ, nigbati Dokita Olusegun Mimiko jẹ komisana feto ilera, ohun iwuri si lo jẹ pe Agagu ati Mimiko pada jẹ gomina nipinlẹ Ondo, lẹyin Olumilua.

line

Olumilua: Gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo nígbàkanrí, Bamidele Olumilua, jáde láyé

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo n fi yeni pe gomina ipinlẹ Ondo nigbakan ri, Ajihinrere Bamidele Olumilua ti di ara ilẹ.

Baba Olumilua jade laye ni owurọ Ọjọbọ.

Gẹgẹ bi ohun ti ọmọ rẹ ṣe lalaye fun BBC News Yoruba lori ẹrọ ibanisọrọ, ẹni ọgọrin ọdun ni Ajihinrere Bamidele Olumilua ki ọlọjọ to de.

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo n fi ye wa pe Olumilua jade laye ṣugbọn a ko tii lee fi idi iku to paa mulẹ.

line

Amọ kokoro awọn ologun ko jẹ ki awọn eeyan ipinlẹ Ondo gbadun obi Olumilua to gbo kaka, nitori oṣu Kọkanla ọdun 1993 ni awọn ologun gba ijọba lọwọ awọn oloselu alagbada, eyi ti oloogbe Sani Abacha ṣe agbatẹru rẹ, ti wọn si yẹ aga akoso mọ Olumilua nidii.

Yoruba ni bi ẹṣin ba da ni, a mọ tun gun, idi ree ti Bamidele tun fi dara pọ mọ ẹgbẹ oselu PDP lọdun 1998, ti wọn si yan sipo alaga igbimọ to n seto idẹrun fawọn arinrin-ajo silẹ mimọ Jerusalemu.

Amọ ninu oṣu kẹjọ ọdun 2005, ni ẹgbẹ oselu PDP fi ikede sita pe Bamidele Olumilua kii ṣe ọmọ ẹgbẹ oun mọ, nigba to si di ọdun 2006 ni oloogbe naa dara pọ mọ awọn agba ilu kan lati da ẹgbẹ oselu Action Congress, AC silẹ.

Àkọlé fídíò, Nollywood stars: Àwọn èèkàn òṣèré sinimá ní Nàìjíríà jẹ́wọ́ ara wọn lórí fífi ohùn àmì

Ni ọdun 2012 tun ni wọn yan Olumilua gẹgẹ bii baba isalẹ fasiti ipinlẹ Ekiti, EKSU.

Nigba to jẹ pe awaye ku ko si, Bamidele Olumilua jẹ ipe Ọlọrun ni owurọ kutu hai Ọjọru, ọjọ Kẹrin oṣu Kẹfa ọdun 2020 lẹni ọgọrin ọdun nilu rẹ, Ikere Ekiti.

BBC Yoruba wa gbadura pe ọba oke yoo dẹ ilẹ fun ẹni re to lọ.