Coronavirus Updates in Nigeria: Òṣìṣẹ́ ètò ìlera méjì ló wà nínú àwọn tó lùgbàdì àrùn Coronavirus ní Ekiti

coronavirus

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Àjọ NCDC ṣàlàyé ní kíkún pé ènìyàn 348 ló lùgbàdì àrùn Coronavirus ní Naijiria ní Ọjọ́ọ̀rú nìkan ṣoṣo.

Ijọba ipinlẹ Ekiti ti kede pe oṣiṣẹ eleto ilẹra meji wa ninu awọn marun un to ṣẹṣẹ lugbadi arun naa ni ipinlẹ Ekiti.

Kọmiṣọnna fun Eto Ilẹra ni ipinlẹ naa, Mojisola Yaya-Kolade to fi idi iroyin yii mulẹ ni wọn n gba iwosan ni ileewosan ẹkọsẹ ti ijọba apapọ to wa ni Ido-Ekiti.

Kọmisọnna naa ni awọn ṣẹ awari awọn eniyan tuntun to lugbadi arun naa lẹyin ti wọn bẹrẹ si ni wa awọn to ti farakan obinrin kan ti ayẹwo fihan pe o ni aarun Coronavirus ni ileewosan.

O ni bio tilẹ jẹpe awọn oṣiṣẹ eto ilẹra ko fi ami kankan han pe wọn ni arun Coronavirus, o pọn dandan ki wọn si ma a gba itọju.

Bakan naa ni wọn fikun wi pe ijọba naa ti bẹrẹ si ni fin kokoro apakokoro ni gbogbo agbegbe ileewọsan ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Ijọba ipinlẹ Ekiti naa wa rọ awọn eniyan lati maṣe ru ofin konile-o-gbele ki wọn ba le kapa arun naa ni ipinlẹ ohun.

Ni apapọ, eniyan to ti ni arun Coronavirus ni ipinlẹ Ekiti bayii ti da mẹẹdọgbọn.

NCDC: Àlàyé bí a ó ṣe gbé òkú àwọn tó bá Covid 19 lọ látòkè òkun wálé rèé

Ajọ NCDC ti kede pe fun awọn idile to ni eeyan loke okun tabi ipinlẹ mii ti wọn ti padanu ẹmi wọn lasiko aarun Coronavirus yii, awọn ti ṣe ilana lati gbe wọn wale.

Awọn oṣiṣẹ ibudo itọju awọn alaarun coronavirus

Oríṣun àwòrán, twitter/Babajide sanwo-olu

Bi o tilẹ jẹ pe o jẹ igbesẹ to le koko gẹgẹ bi ajọ naa ṣe sọ ọ, wọn ti ṣe alakalẹ ilana ti yoo ṣamojuto irinajo lati gbe wọn wale ni ibamu pẹlu ofin to wa nilẹ.

Ninu iwe ilana naa, wọn ṣalaye iru iṣẹlẹ to lee ṣe okunfa ki wọn gbe oku kuro lati ipinlẹ kan tabi orilẹ ede mii.

To ba jẹ iku ti Covid 19 fa ni, ninu ki wọn sin oku ẹni bẹẹ si ibi ti o ku si tabi bi ẹbi ba fẹ, wọn lee gbe e lọ fun wọn ṣugbọn ilana yii le pupọ tori wọn ni lati forikori pẹlu gbogbo awọn alaṣẹ tọrọ kan.

Bakan naa, iwe ọhun mẹnu ba bi wọn yoo ṣe tọju oku ẹni to jẹ pe Covid 19 lo ṣokunfa rẹ ati pe ohun aa ṣe lasiko irinajo ti wọn ba n gbe oku lọ fun apẹrẹ,

Igbesẹ gbigbe oku wọle naa ni:

*Titi pa ni posi ti wọn fi gbe oku gbudọ wa wọn ko gbudọ ṣi posi loju popo

*Wọn gbudọ ṣe ayẹwo imọ ijinlẹ sayensi fun oku ki wọn si tọju ayika ti wọn yoo lo

* Wọn lee gbe oku laarin ipinlẹ si ipinlẹ pẹlu ọkọ agboku awọn onimọ ilera tabi ọkọ mii to wa fun gbigbe oku, to ba jẹ lati oke okun, ki wọn gbe e gẹgẹ bi ẹrù lori ọkọ baalu.Ẹkunrẹrẹ alaye yii wa ni oju opo Twitter ajọ NCDC.