Taraba Killings: IGP ti jọ̀wọ́ Hamisu Wadume fún aádájọ́ àgbà Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, others
Ọ́fíísì agbẹ́jọ́rò àgbà Nàìjíríà tí gbá ẹjọ́ Bala Hamisu ti gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Wadume tó jẹ́ gbájúgbajà ajínigbé ní ìpínlẹ̀ Taraba kúrò lọ́wọ́ ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá Muhammed Adamu.
Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá ní ọjọ kẹta oṣù keji ọdun yìí fi ẹ̀sùn onípele mẹ́rìnlá, ìgbésùnmsmí, ìpànìyàn, ìjínígbé àti kíkó ǹkan olóró síkàwọ́ lọ́nà àìtọ́ pẹ̀lú àwọn ogun míràn.
Mẹ́fà nínú àwọn ogún náà ló péjú si ilé ẹjọ tó fi mọ́ Wadume lónìí ọjọ́rú.
Àwọn ọmọogun mẹ́wàá tọ́rọ̀ náà kàn kò yọjú silé ẹjọ́ lónìí, bákan náà ni wọ́n ò yọjú silé ẹjọ́ nínú oṣu kẹta ọdun.
Sááju ni agbẹ́jọ́rò fún àjọ ọlọ́pàá Simon Lough ti sọ fún àdájọ Binta Nyako pé ilé iṣẹ ọmọogun kò jọ̀wọ́ àwọn ọmọogun tọ́rọ̀ kàn láti waá sílé ẹjọ́.
Èyí ló mú kí adájọ rànṣẹ́ pe ki ọgá àgbà ilé iṣẹ́ ọmọogun jọ̀wọ́ àwọn ọmọogun mẹ́wàá tí ọ̀rọ̀ náà kàn fún àjọ ọlọ́pàá.
Ẹ̀wẹ̀, agbẹ́jọ́rò láti ọ́fíìsì agbẹjọ́rò àgbà ìjọba Labaran Magaji tó péjú sílé ẹjọ́ fún ìgbà àkọ́kọ́ lónìí sàlàyé pé, àwọn ti gba, ẹjọ́ náà lọ́wọ́ àjọ ọl\apàá lánàá ọjọ́ ìṣẹ̀gún.
O ti bèrè pé kí wọ́n sún ìgbẹ́jọ́ náà síwájú láti ríidájú pé gbogbo àwọn tí ẹjọ́ náà kan wá sílé ẹjọ́.
Adájọ́ ti sún ìgbẹ́jọ́ náà sí ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹfà, ní dédé aago mẹ́wàá ààbọ̀ òwúrò.
Ọlọ́pàá tí tẹ Hamisu Wadume

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police Force
Ṣe wọn ni ẹgbẹrun Saamu ko lee sa mọ Ọlọrun lọwọ. Eyi lo difa fun afurasi Ogbontarigi ajinigbe ni, Alhaji Hamisu bala Wadume.
Ọwọ palaba rẹ segi ni bi ọsẹ meji sẹyin nigba ti awọn ọlọpaa ikọ ọtẹlẹmuyẹ marindọti ti a mọ si IG intelligence Squad mu ni ipinlẹ Taraba.
- Ambode ní kò sí gìrì, eré ọwọ́ lásán ni EFCC ń ṣe
- Ta ni Seun Fakorede, ọmọ ọdún 27 tó fẹ́ di kọmiṣọna?
- Ọlọ́pàá ti mú ẹni márùn ún lórí ìjà láàrin Hausa àti Yorùbá l'Eko
- Ìjìyà ń bẹ fún àwọn ti adé ọ̀rọ̀ náà bá ṣí mọ́ lóri -Ọga àgbà FRSC
- Ike Ekweremadu, igbákejì ààrẹ ilé aṣòfin àgbà tẹ́lẹ́ rí èèmọ̀ he nilùú Germany!
Amọṣa ki a to wi ki a to fọ, nibi ti awọn oṣiṣẹ ikọ naa ti n gbee lọ ni awọn ọmọ ogun kan ti ṣina ibọn bolẹ ti wọn si pa ọlọpaa mẹta ati araalu meji.
Afurasi ajinigbe naa nikan ni ko ku ninu ikọlu naa eleyi ti awọn ọmọ ogun ọhun ni awọn ro pe awọn ajinigbe lawọn ọlapaa to gbe Wadume nigba naa.

Oríṣun àwòrán, Nigeria police force
Ọrọ yii di iṣu ata yan an yan an laarin ileeṣẹ ọlọpaa ati ileeṣẹ ọmọ ogun lorilẹ-ede Naijiria.
Koda, ni ilẹ yii ati loke okun ni awọn eeyan ti bu ẹnu ẹtẹ lu iṣẹlẹ naa.
Amọṣa, ni ọjọ Aje ni ọwọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ọlọpaa tun ra Wadume mu pada ni ilu Kano ti o lọ farasinko si.
Atẹjade kan ti olu ileeṣẹ ọlọpaa fi sita ṣalaye pe ọga agba ọlọpaa lorilẹ-ede Naijria, Mohammed Adamu ti kan sara sawọn ọlọpaa to mu u.
O ki wọn fun ẹmi ifọkansin wọn ati ifaraẹnijin ti wọn fi ri afurasi naa mu.
Ọga agba ọlọpaa Adamu ko ṣai ki ẹbi awọn ọlọpaa ati araalu to doloogbe nitori ati mu afurasi naa.
Bakan naa lo tun ṣalaye pe afurasi ọhun yoo ran awọn ọtẹlẹmuyẹ lọwọ lati wa idahun si ọpọlọpọ ibeere ti o n yọju lori iṣẹlẹ naa ati ọgba ajara iṣẹ laabi wọn.
Iṣẹlẹ to fa bi afurasi ajinigbe naa ti ṣe sa lọ mọ ofin lọwọ ni ọjọ kẹfa, oṣu kẹjọ, ọdun 2019 fa ọpọ arinyanjiyan laarin ile iṣẹ ọlọọpa ati awọn ọmọ ogun.
Eyi to si mu ipaya ba awọn eeyan kaakiri orilẹ-ede yii ki aarẹ Muhammadu Buhari to paṣẹ wi pe ki wọn tọpinpin iṣẹlẹ naa.
Igbimọ to n ṣewadi iṣẹlẹ ọhun ṣi wa lẹnu iṣẹ ni lọwọlọwọ.












