Revolution Now: NLC ní bí agbófinró ṣe mú Soworẹ àti àwọn yókù rẹ̀ sí àhámọ́ tẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ oṣiṣẹ l'orilẹede Nigeria, NLC, ti keboosi pe ki wọn o tu Omoyele Sowore ati awọn oludije miran silẹ ni kiakia.
Ẹgbẹ osisẹ, ninu atẹjade kan ti Akọwe apapọ rẹ, Comrade Peter Ozo-Eson fi sita, kede pe o jẹ iyalẹnu bi awọn oṣiṣẹ alaabo "ṣe kọlu awọn to ṣe iwọde Revolution Now l'ọjọ Aje, ti wọn si mu wọn lọ si ahamọ.
NLC tọka si i pe, ẹtọ gbogbo ọmọ Naijiria ni labẹ abala ofin ikọkandinlogoji ati ogoji ninu iwe ofin Naijiria, lati ṣe iwọde ti ko ni jagidijagan, ti wọn si tun ni ẹtọ lati korajọpọ tabi darapọ mọ ipejọpọ to ba wu wọn.

O ni "Oju ti a fi wo bi awọn oṣiṣẹ alaabo ṣe kọlu awọn oluwọde alaafia ọhun, ni titẹ ẹtọ ọmọniyan loju."
"Iwọde alaafia tako iṣejọba ti ko dara tabi awọn igbesẹ ati ilana ijọba ti ko dara fun araalu, jẹ ọkan lara awọn ẹtọ ọmọniyan to ṣe koko, to si n mu ki eto iṣejọba awaarawa o dagba si.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Èmi àti Saheed kìí ṣe ọmọdé, a ti jọ ṣe Sinimá papọ̀, èyí túmọ̀ sí pé ìjà ti parí - Fathia Balogun
- "Mo fẹ́ pa ara mi torí ojú àbùkù tí wọn ń fi wò mí pé mo fi iṣẹ́ abẹ bímọ"
- Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọn bàbá wa - Sunday Igboho
- Ọjà Àgbáláta ní Badagry rèé, níbití ẹran ejò ti dùn ju ẹran adìẹ lọ
- Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ nkan tó wà láàrin èmi àti Ireti Ajanaku - Tope Alabi
A ko si gbọdọ fi aaye gba awọn oṣiṣẹ alaabo wa, lati maa fi ara wọn han gẹgẹ bi ọta iṣejọba awa ara wa gẹgẹ bo ṣe han ninu iwa wọn l'ọjọ Aje."
Bakan naa ni Ọgbẹni Ozo-Eson tun sọ pe, bi awọn oṣiṣẹ ajọ alaabo DSS ṣe fi oludasilẹ iwọde Revolution Now, Omoyele Sowore si ahamọ, ko ba oju mu to, nitori pe igbesẹ Sowore ko fi ibi kankan dunkooko mọ iṣọkan tabi ijọba Naijiria.









