Revolution Now: Deji Adeyanju ní ìwọ́de míràn ń bọ̀ ní Satide tí wọn kò bá fi Sowore sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, @YeleSowore
Ajafẹtọ ọmọniyan kan, Deji Adeyanju ti ni Omoyele Sowore to wa ni iahamọ ọlọpaa DSS, ti kọ lati gba ounjẹ ni ọwọ awọn ọlọpaa lati ọjọ ti wọn ti ti i mọle.
Adeyanju sọ eyi lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori ipo ti Sowore wa, ẹni to jẹ adari fun awọn afẹhọnu han to n pe fun atunse eto ijọba lorilẹede Naijiria, eyii to fa a idi ti wọn fi ti i mọle.
Adeyanju ni lẹyin ti Sowore kọ lati gba ounjẹ ni ajọ DSS wa gba awọn ẹbi ati ọrẹ rẹ nimọran, lati ma a gbe ounjẹ wa fun un lojoojumọ.
Ajafẹtọ ọmọ eniyan naa, ni awọn ko le e sọ pato igba ti ijọba yoo fi Sowore silẹ nitori o ti yẹ ki wọn fi silẹ tabi ki wọn gbe lọ si ile ẹjọ gẹgẹ bi ofin ti sọ.
O fikun pe awọn yoo se ifẹhọnu han miran ni Ọjọ Satide, Ọjọ Kẹwa, Osu Kẹjọ, ọdun 2019, ti ijọba ba kọ lati fi silẹ ni Ọjọ Abamẹta.
Bakan naa ni Adeyanju ni awọn mọkanlelogun eniyan to fẹhọnu han ni ipinlẹ Eko ni Ọjọ Karun un , Osu Kẹjọ, ọdun 2019 ni o si wa ni atimole ọlọpaa ni agbeegbe Panti to jẹ Olu-ile isẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko.
Ajafẹtọ naa wa fikun wi pe ifẹhọnu awọn ko nii se lati gba ijọba pẹlu ipa, amọ awọn n bere fun ijọba to bun iyi kun awọn ọmọ Naijiria, ki eto aabo orilẹede Naijiria gbooro si, ati wi pe ki alaafia ki o jọba ni Naijiria.
‘A kò jáde ṣe ìwọ́de ìtagbangba mọ́, inú ọkàn wa lá ti máa ṣe ìfẹ̀hónú hàn’
Yoruba ni taa ba ni eegun baba ẹni yoo jo, amọ ti ko ba jo mọ, ko si ẹni to lee mu ni si.
Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ Revolution Now to n se iwọde lati beere fun ijọba to duro re ni orilẹede Naijiria, nigba ti wọn pinnu pe awọn ko jade mọ fun iwọde ita gbangba ti wọn bẹrẹ lọjọ Aje.

Gẹgẹ bi akọroyin BBC Yoruba ti se akojọpọ rẹ, awọn eeyan to n se iwọde naa ni wọn ti fi ipade si oni ọjọ Isẹgun pe awọn yoo tẹsiwaju pẹlu iwọde awọn, lẹyin ti awọn ọlọpaa fi afẹfẹ alata ati tajutaju tu wọn ka lọjọ Aje.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọn bàbá wa - Sunday Igboho
- Dangote, jọ̀ọ́ nawọ́ ìrànwọ́ láti dá iléeṣé sílẹ̀ fún wa ní Ọyọ - Aláàfin rawọ́ ẹ̀bẹ̀
- Láti orí 'Our Mumu don do' sí 'Revolution Now'
- Bí ọdún Ọ̀ṣun Oṣogbo ṣe bẹ̀rẹ̀ rèé àti pàtàkì rẹ̀ fún Nàíjíríà
- Saudi ṣàtúnṣe lílẹ òkò mọ́ Asitani láti dẹ́kun títẹra-ẹni-pa
Sugbọn iyalẹnu lo jẹ fun wa nigba ti ikọ iroyin wa de adugbo Ọjọta, amọ ti eegun awọn oluwọde Revolution Now ko sẹ nibẹ, bi o tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa ati ọmọ ogun ti duro wa wa wa si agbegbe naa, lati wa pade awọn oluwọde ọhun.
Nigba ti akọroyin wa pe ọkan lara awọn eeyan to n lewaju iwọde naa, Usman Oloyede lori aago, lori idi ti wọn ko fi kofiri wọn lati wa tẹsiwaju ninu iwọde ti wọn n se, Oloyede fesi pe awọn ko lee jade sita mọ wa se iwọde .

"Kii se dandan ki awọn eeyan ri wa loju koroju pe a n se iwọde ni ibikibi lorilẹede Naijiria, amọ gẹgẹ bi awọn ọmọ Naijiria ti n joko sile, maa fi ẹhonu han ninu ọkan wọn, naa ni awa naa fẹ maa se pẹlu. Inu ọkan wa ni awa naa ti fẹ maa fi ẹhonu han."
- Ẹ yàgò fún gbájúẹ̀, a kò tíì gba ẹnikẹni fún iṣẹ́ tíṣà - Ìjọba Ọyọ lọgun
- Ọdún iṣu tuntun wáyé ní Ilé Ifẹ̀, Ọọ̀ni rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sáwọn àgbẹ̀ àti darandaran
- Gbígba onídùròó Zakzaky ṣàfihàn àṣeyọrí ìfaradà wa lásìkò ìfìyajẹni - Shiite
- Ó tó gẹ́ẹ́! Àsìkò tó láti fi ìwọ́de gba ara wa sílẹ̀ lọ́wọ́ ebi àti oko ẹrú - Sowore
Oloyede tun fikun pe, ohun to mumu ju laya awọn bayiii ni bi awọn yoo se gba idande awọn ọmọ ẹgbẹ Revolution Now tawọn ọlọpaa mu si ahamọ, ti awọn yoo si fi isu si ina, maa fi inu wa ọbẹ lori igbesẹ to ku ti awọn yoo tun mu pọn lori ifẹhonuhan wọn ọhun.

Oríṣun àwòrán, @YeleSowore
"Ẹ panumọ́ lórí bẹ ṣe ń bú Buhari pé ó mú Ṣoworẹ sí àhámọ́"
Ẹgbẹ kan to n se atilẹyin fun aarẹ Muhammadu Buhari nidi eto iroyin, BMO, ti kesi Ọjọgbọn Wọle Soyinka, Fẹmi Falana atawọn ọmọ orilẹede yii miran, to koro oju si bawọn ọtẹlẹmuyẹ se gbe asaaju ẹgbẹ Revolution Now, Omoyele Sowore si ahamọ, pe ki wọn pa ẹnu wọn mọ.
Atẹjade kan ti alaga ẹgbẹ BMO naa, Niyi Akinsiju ati akọwe rẹ, Cassidy Madueke fisita wa bu ẹnu atẹ lu Soyinka, Falana atawọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ajafẹtọ ẹni miran, fun bi wọn se n se koriya fun awọn eeyan ti wọn fẹ da rogbodiyan silẹ lorilẹede Naijiria.
Ẹgbẹ naa wa rọ awọn eeyan to lami laaka lorilẹede Naijiria lati maa sọrase, ki wọn si maa huwa ọlọgbọn lasiko ti wọn ba n dasi ọrọ ilu lọna ati mase bu epo eebo si rogbodiyan to wa nilẹ.

"Awa mọ pe igbesẹ to tọ ni ijọba Naijiria gbe pẹlu bi wọn se da oniwahala lẹkun lati mase fi tipa gba ijọba to ni atilẹyin ofin. Gẹgẹ bii orilẹede to sẹsẹ seto ididbo tan lawọn ipinlẹ ati nijọba apapọ, ko si idi kankan fun awọn eeyan kan tabi ẹgbẹ kankan lati wa ọna ti wọn yoo fi se ayipada ijọba to wa lode."
Ẹgbẹ BMO tun ni oun fẹ ran Ọjọgbọn Soyinka atawọn eeyan rẹ yoku leti pe awọn agbofinro kii sadede gbe ẹnikẹni lọna aitọ, ayafi ti ẹri to daju ba wa nilẹ pe irufẹ awọn eeyan bẹẹlatipasẹ iwa, ise ati ọrọ ẹnu wọn, jẹ ewu nla fun eto aabo, irẹpọ ati isọkan orilẹede yii.












