Ọ̀ṣun Oṣogbo: Èyí ni àwọn ayẹyẹ tí yóò wáyé ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan lásìkò ọdún Ọ̀ṣun Oṣogbo

Oríṣun àwòrán, Osun Osogbo
Inu osu Kẹjọ ọdọọdun ni ọdun Ọṣun Oṣogbo maa n waye ni ojubọ Ọṣun, eyi ti ẹgbẹlẹgbẹ awọn olujọsin ati oluworan maa n peju si jakejado agbaye.
Akoko ọdun Ọṣun Oṣogbo yii jẹ asiko yatayoto nilu Osogbo, ti wọn si tun maa n lo akoko naa lati se etutu fun ilu tabi fọ ilu mọ ni ilana ti ibilẹ.
A gbọ pe ọdun Ọṣun Oṣogbo ti le ni ẹẹdẹgbẹrin ọdun to ti bẹrẹ, a ko si lee sọ nipa isẹdalẹ ọdun Ọṣun Oṣogbo, ka ma mẹnuba itan idasilẹ ilu Osogbo funra rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Gẹgẹ bi itan ti fi ye ni, awọn eeyan kan ti Olutimẹyin, ogboju ọdẹ ko sodi, lo de idi agbami odo nla kan, ti wọn n pe ni odo Ọṣun., ti wọn si tẹdo seti odo naa, lọna ati gba awọn eeyan rẹ silẹ lọwọ iyan ati ebi.
Ibudo yii ni wọn wa ti Yemoja ti wọn n pe ni Ọṣun fi yọju si Olutimẹyin, ti onitọun naa si rọ Ọṣun lati lewaju oun ati awọn eeyan rẹ ls si ibi ti wọn yoo tẹdo si ta mọ si ilu Oṣogbo bayii.

Oríṣun àwòrán, Osun osogbo
Ọṣun seleri lati raga bo wọn pẹlu ileri pe awọn naa yoo maa pada wa ni ọdọọdun lati wa maa bọ oun bii orisa.
Awọn eeyan naa faramọ oun ti Ọṣun beere yii, ti ọdun Ọṣun Oṣogbo si maa n waye lọdọọdun lati igba naa wa, titi di oni yii.
Ọsẹ meji ni wọn fi maa n se ọdun Ọṣun Oṣogbo, eyi to maa n kun fun oniruuru eto to jẹ mọ aṣa ibilẹ lati gb ajọdun naa larugẹ.
Awọn eto to maa n waye lasiko ọdun Ọṣun Oṣogbo:
Iwọ Popo:
Iwọ Popo ni wọn maa fi n bẹrẹ ọdun Ọṣun Oṣogbo lọdọọdun, asiko yii si ni awọn olujọsin ati awsn oluworan yoo maa yi ilu po lati fọ ilu mọ pẹlu adura ati etutu.

Oríṣun àwòrán, @osunosogbo2019
Titan Fitila Oloju mẹrindinlogun:
Eto keji to tun kan fun ọdun Ọṣun Oṣogbo ni titan fitila oloju mẹrindinlogun. Lẹyin ọjọ kẹta ti ọdun Ọṣun Oṣogbo bẹrẹ si ni eto naa yoo waye.
Wọn yoo tan fita to ni oju mẹrindinlogun titi di opin ajọdun naa.
A gbọ pe fitila ti wọn n tan yii ti le ni ẹẹdẹgbẹta ọdun.

Oríṣun àwòrán, Osun osogbo
Ibọriade:
Eto kẹta to tun maa n sami ọdun Ọṣun Oṣogbo ni eto Ibọ ori ade. Eto yii lo n se akojọpọ awọn oniruuru ade isẹmbaye ti awọn ọba ilu Oṣogbo, taa mọ si Ataoja, ti lo kọja, ti wọn yoo si lo wọn fun iwure lati gba ibukun.
Lasiko eto yii ni Ataoja to wa lori oye yoo wa nikalẹ, to fi mọ Arugba Ọṣun, Yeye Ọṣun, awọn arugba to ti gbe igba Ọṣun tẹlẹ, to fi mọ awọn olujọsin Ọṣun miran.
Arugba:
Lara awọn eto to se pataki lasiko ọdun Ọṣun Oṣogbo ni igba riru lọ si ojubọ Ọṣun Oṣogbo.
Omidan ti ko tii mọ ọkunrin, ti wọn n pe ni arugba, ni yoo ru igba naa, tawọn eeyan si maa n ri oun gangan bii orisa ti wọn yoo maa sọ isoro wọn fun, bo ba se n lewaju wọn ru igba to kun fun ohun etutu, lọ si ojubọ Ọṣun.
Ọjọ ti wọn ba lọ si ojubọ Ọṣun Oṣogbo yii ni asekagba, ti ọpọ eeyan jakejado Naijiria ati loke okun yoo si pejọ si ojubọ Ọsun lati beere ohun kan tabi omiran tabi lati gbe bi ayẹyẹ naa se n lọ fun araye.

Oríṣun àwòrán, Osun Osogbo
Lọwọlọwọ bayii, ọdun Ọṣun Osogbo ti di itẹwọgba jakejado agbaye, tawọn onileesẹ nla nla si n wa lati ilẹ okeere wa se onigbọwọ rẹ. Bakan naa lọdun 2005 ni ajọ UNESCO ti kede pe ọdun Ọṣun Oṣogbo ti di ibudo ajogunba lagbaye.
Lara anfaani ti ọpọ eeyan n jẹri si pe o wa ninu bibọ Ọṣun Oṣogbo ni pe o jẹ orisa ọlọmọ, to si maa n pese ọmọ fun awsn agan tabi dahun awọn adura miran.












