Ooni: Mo rọ àwọn àgbẹ̀ àti darandaran láti gba ìrẹ́pọ̀ láàyè

Awọn eeyan pejọ si aafin Ọọni lati se ọdun isu tuntun

Oríṣun àwòrán, Ooni of Ife

Ọọni tilu Ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi Ọjaja Keji, ti rawọ ẹbẹ si awọn agbẹ ati darandaran lati wa ni irẹpọ, ki ounjẹ lee tubọ buyaari fun wa.

Aba Adeyẹye, ẹni to parọwa yii ni aafin rẹ lasiko ayẹyẹ ọdun isu tuntun tun sọ pe, ti ọwọn gogo ounjẹ ba fi wa nitori ija awọn agbẹ ati darandaran, a jẹ pe a n kọ lẹta ipe fun aisan ni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni ounjẹ aṣara loore nikan lo lee le aisan jinna si agọ ara wa.

Ọba Ogunwusi ni laipẹ ni wọn yoo pada si ohun to n waye ni atijọ nidi dida awọn ọja tuntun silẹ si ni ilu Ile Ifẹ.

Ọọni n la isu tuntun fun jijẹ

Oríṣun àwòrán, Ooni of Ife

Ọọni Ifẹ ni ọja Ejigbo Mẹkun ti wa lati ẹẹdẹgbẹta ọdun sẹyin, bi wọn si se se agbende rẹ pada ni ọdun yii se afihan ohun rere to n bọ.