Aláàfin: Àìrí iṣẹ́ ṣe ọ̀dọ́ lágbègbè mi ń peléke, ó sì nílò àmójútó

Alaafin Oba Adeyemi III

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oba Adeyemi III

Alaafin tilu Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyeme Kẹta ti rawọ ẹbẹ si gbajugbaja olokoowo nii, Aliko Dangote lati nawọ iranwọ rẹ fi da ile iṣẹ silẹ ni agbegbe rẹ.

Oba alade naa fi arọwa yi sita lopin ọsẹ nibi ipade kan pẹlu igbimọ alakoso ile iṣẹ Dangote nilu Eko.

Oba adeyẹmi tun kan saara si Dangote fun igbiyanju rẹ lati wa ọna jijẹ-mimu fawọn ọdọ Naijiria, eleyi to ni o jẹ ọna kan gbogi lati mu idagbasoke ba orileede Naijiria.

Ninu ọrọ rẹ, Dangote seleri lati wa wọrọkọ fi ṣada lori ohun ti Alaafin beere, pẹlu afikun pe oun ṣetan lati mu anfaani ile iṣẹ ati idokoowo wa si agbegbe rẹ, eyi ti yoo mu adinku ba iye awọn ọdo ti ko niṣẹ lọwọ.

Dangote ni agbajọwọ bayi laa fi sọya ati pe, o ṣe pataki lati pese ọna iṣẹ fawọn ọdọ gẹgẹ bi ọna kan lati dẹkun iwa janduku to n peleke lawujọ wa.

Alaafin, awọn iyawo rẹ ati Aliko Dangote

Oríṣun àwòrán, Alaafin of Oyo

''Bi a ba fẹ jẹ mudunmudun ohun ta ṣiṣẹ fun, o di dandan ki a mu aabo ni pataki. Iṣẹ aabo ilu kii ṣe ti ijọba nikan, bi kii ṣe ti gbogbo wa. A si nilo owo lati le ri ṣe''

Saaju ni Alaafin ti mẹnuba ipenija aisiṣẹ fawọn ọdọ lagbegbe rẹ ati jakejado Naijiria.