Fulani herdsmen: Mo ti Buhari lẹ́yìn ṣùgbọ́n ìjínigbé ìgbà gbogbo yìí náà ń kọmí lóminú

Alaafin Ọyọ

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oba Adeyemi III

Àkọlé àwòrán, Alaafin ni oun to dunni ju ni pe bi gbogbo eyi ṣe n ṣẹlẹ bọọ lawọn agbofinro n wo

Kii ṣe tuntun mọ pe aarẹ Muhammadu Buhari ri lẹta kan gba laipẹ yii lati tete wa wọrọkọ fi ṣada lori bi nnkan ṣe n lọ lorilẹede Naijiria.

Ni bayii, ọrọ ọhun ti yii kan oriade o. Alaafin ilu Ọyọ, iku baba yeye, Ọba Lamidi Adeyẹmi kẹta naa ti wa kọ lẹta tirẹ ranṣẹ si aarẹ bayii; ori ọrọ ijinigbe ati gulegule awọn darandaran Fulani ni ilẹ Yoruba naa ni koko inu iwe lẹta rẹ.

Àkọlé fídíò, Obasanjo: Atiku kìí se Áńgẹ́lì, àmọ́ yóò se dáadáa ní ìlọ́po méjì ju Buhari lọ

Alaafin to mẹnuba awọn iṣẹlẹ haa-hinn to waye lori ọrọ abo to mẹhẹ ni ilẹ Yoruba laipẹ yii ni aarẹ Buhari ti wọn fi joye ko lee gbadiyẹ lori eto abo.

Iku baba yeye ni ẹya Yoruba lagbara lati gbe igbesẹ lati gba ara rẹ silẹ bi eto abo ko baa gbe pẹẹli si lẹkun naa.

Àkọlé fídíò, Wòlíì Kasali sọrọ nípa awuyewuye pé o lè ìyàwó rẹ̀ jáde nílé

Alaafin ilu Ọyọ ni ko si aniani pe digbi ni oun wa lẹyin Aarẹ Buhari ati iṣejọba rẹ ṣugbọn ominu n kọ oun lẹnu ọjọ mẹta yii lori ipenija ọrọ abo jakejado orilẹede Naijiria, paapaa julọ ilẹ Yoruba titi kan ipinlẹ Kwara, Kogi ati Edo.

"Eyi nii ṣe pẹlu bi gulegule idukukulaja mọni awọn darandaran Fulani ti ṣe wa n di lemọlemọ bayi loju awọn opopona marosẹ gbogbo ni ilẹ Yoruba. Yala ni Ọwọ ni, Akurẹ ni, opopona ilIfẹ/ Ijẹsa ni titi lọ de agbegbe Ibrapa ati Ijẹbu ni ipinlẹ ogun ni ọrọ ko ti yatọ

Alaafin ni lẹyin ifikuluku ati ijiroro pẹlawọn agbaagba ati majẹobajẹ ilẹ Yoruba, o han gbangba pe inu hilahilo lawọn eeyan n gbe bayii nitori awọn kọlọransi yii ti wọn n fipa ba aya lo niwaju ọkọ, ti wọn si tun n ba nnkan ọgbin jẹ pẹlu oniruru iwa familete n tutọ miran.

O ni oun to dunni ju ni pe bi gbogbo eyi ṣe n ṣẹlẹ bọọ lawọn agbofinro n wo lai lee ṣe ohunkohun