Gani Adams: Inú ìpèbí ni Ọ̀yọ́mèsì ti pàṣẹ kí n yan olóyè mi

Àkọlé fídíò, Gani Adams: Inú ìpèbí ni Ọ̀yọ́mèsì ti pàṣẹ kí n yan olóyè mi

Ni opin ọsẹ, ni ayẹyẹ ọdun kan Iba Gani Adams ni ori oye aarẹ ọna kakanfo ilẹ Yoruba wa sopin.

Amọṣa, ọkan lara awọn eto ti aarẹ Gani Adams gbe kalẹ lasiko ayẹyẹ naa ti n fa ọpọ awuyewuye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lasiko ayẹyẹ rẹ ni Iba Gani Adams yan igbimọ oloye rẹ ninu eyi to ti yan awọn ọmọ Yoruba kaakiri awọn ipinlẹ to jẹ Yoruba.

Lorilẹede Naijiria si ni igbimọ oloye Aarẹ ọna kakanfo. Eyi si ti n mu ki awọn onwoye kan atawọn ọmọ ilẹ Yoruba kan o maa beere pe ṣe o lẹtọ ki aarẹ ọna kakanfo o yan ijoye fu ara rẹ.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC News Yoruba, Iba Gani Adams funrarẹ ṣalaye pe, awọn ọyọmesi gangan lo fun oun laṣẹ lati yan igbimọ oloye ni kete ti oun ba de ori oye.

Àkọlé fídíò, Abìjà: Bàbá mi fi iṣẹ́ ọdẹ ti ń pa lémi lọ́wọ́ ni nítorí babaláwo ni

O ni kii ṣe imọ oun nikan bikoṣe pẹlu aṣẹ Alaafin ati Ọyọmesi, oun si tun fi to Ọọni ile Ifẹ pẹlu leti.

"Lati igba ti mo ti wa ninu ipebi ni igbaradi fun ati joye, ni awọn Ọyọmesi ti jẹ ko di mimọ fun mi pe, mo gbọdọ yan oloye si igbimọ mi.

Wọn tilẹ jẹ ko di mimọ fun mi nipa awọn nnkan to ṣẹlẹ si awọn aarẹ Ọna Kakanfo ti ko yan igbimọ oloye wọn"

Àkọlé fídíò, Eko Akete yóò gbàlejò BBC Yoruba

Iba Gani Adams ni lati aye Iba akọkọ ni wọn ti n yan oloye si igbimọ aarẹ Ọna kakanfo ati pe, awọn oloye wọnyii ni wọn maa n ran aarẹ lọwọ lati ṣakoso ipese eto abo fun gbogbo ilẹ Yoruba, de ibi gbogbo to ruwe de tabi ta gbongbo de.

O ni ọrọ oṣelu ati okoowo to gbilẹ ni saa awọn aarẹ mejeeji to jẹ ki oun to jẹ lo faa ti ọpọ lode oni fi woo pe ko si ninu itan pe aarẹ yan igbimọ oloye laikii ṣe ọba.