Jamiu Abiola: Ẹ dìbò fún Buhari kí ẹ fi bu ọlá fún bàbá mi

Abiola and Buhari

Oríṣun àwòrán, WIKIPEDIA

Àkọlé àwòrán, Ọdún tó kọjá ni Ààrẹ Buhari bu ọlá fún Olóyè Moshood Abiola tí wọ́n sì fi June 12 se àyájọ́ Ọjọ́ Òmìnira ní Nàíjíríà.

Ọmọ oloye Moshood Abiola ti wọn kọ lati kede wi pe o jawe olubori ninu idibo si ipo aarẹ ti june 12, 1993, Jamiu Abiola ti rọ awọn ọmọ Yoruba lati di ibo wọn fun Aarẹ Buhari lọdun 2019 lati fi bu iyi fun baba oun.

Jamiu to jẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ to n se ipolongo fun ipada si ipo aarẹ Buhari (Directorate of Contact and Mobilisation of the Women and Youth Presidential Campaign Team) sọ wi pe Buhari kii se ẹlẹyamẹya.

Jamiu lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ ni ilu Eko se apejuwe Buhari gẹgẹ bi ọmọluabi nitori to bu ọla fun Moshood Abiola, lẹyin ọdun mẹẹdọgbọn ti baba oun ti jade laye.

Àkọlé fídíò, 'Twitter ló gbà mí lọ́wọ́ ikú'

O rọ awọn ọmọ Oodua lati dibo wọn fun Aarẹ buhari lẹẹkeji ni Ọjọ Kẹrindinlogun, Osu Keji, ọdun 2019 lati ma se tabuku M.K.O Abiola ati iyawo rẹ, Kudirat Abiola ti wọn sekupa.

Ti a ko ba gbagbe, ọdun to kọja ni Aarẹ Buhari bu ọla fun Oloye Moshood Abiola ti wọn si fi June 12 se Ọjọ Ayajọ Ominira(Democracy Day) ni Naijiria laaarin awọn miran naa to da lọla.