#BeyondFakeNews: Soyinka ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìròyìn òfégè ti pa òun

Ọjọgbọn Wole Soyinka
Àkọlé àwòrán, Ọrọ lori ayederu iroyin
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọjọgbọn Wole Soyinka ṣi aṣọ loju ọrọ nibi ipade BBC ti ṣe l'Abuja lati tu aṣiri iroyin ofege, nigba ti o sọ pe ọpọ igba ni awọn kan ti gbe ayederu iroyin sita pe oun ti ku.

O fikun ọrọ rẹ pe oun ti ẹ ti gba ipe lori ago nigba ti awọn kan fẹ mọ bo ya oun si wa laaye nitori ayederu iroyin ti wọn ti gbọ pe oun ti papoda.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ọjọgbọn Soyinka ni bakan naa ni ọpọ oniroyin ofege ti kọ awọn ọrọ kan ni orukọ oun ti wọn si ni oun ni oun sọ awọn ọrọ naa.

Ọjọgbọn Wole Ṣoyinka tẹnu mọ ọ pe iroyin ofege ti di bii kokoro ajẹnirun to n jẹ Naijiria run.

Ọjọgbọn Wole Soyinka
Àkọlé àwòrán, Ọrọ lori iroyin ofege

Ṣoyinka ṣalaye pe ọpọ igba ni oun paapa ti lugbadi ayederu iroyin. ''Kiiṣe ẹẹkan tabi ẹẹmeji ni iroyin ti gbe e pe mo ku.''

Bakan naa, igbakeji Aarẹ orilẹede Naijiria, Yẹmi Ọṣinbajo ti oun naa jẹ ọkan lara awọn olujiroro nibi eto naas ọ pe wahala nla ni gbigbe ayederu iroyin n da silẹ ni awujọ.

Ọṣinbajo ninu ọrọ to sọ nibi ipade apero ti ileeṣẹ BBC ṣe lati polongo tako ayederu iroyin, sọ pe diẹ lo ku ki ayederu iroyin da igbeyawo oun ru lasiko ti iroyin kan jade pe oun n ba awọn to maa n rin ihoho nile ijo d'ọrẹẹ.

Yemi Osinbajo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn akópa jẹ́ kó di mímọ̀ pé awọn iroyin ayederu ti n gbayi gaan laarin awujọ yala ọ̀rọ̀ ti wọn kọ, fọto tabi fidio

Eto naa waye gẹgẹ bi idibo orilẹede Naijiria yoo ṣe waye ninu oṣu keji ọdun 2019, ọkan lara akitiyan ile iṣẹ igbohunsafẹfẹ BBC ni lati jẹ ki awọn eniyan m ohun ti iroyin ofege jẹ.

Ile iṣẹ iroyin BBC ṣe agbekalẹ rẹ lati gbogun ti awọn ayederu iroyin. Ọkan o jọkan ile iṣẹ igbohun safẹfẹ ati awọn alabaṣiṣẹpọ pẹlu ile iṣẹ BBC lo peju pesẹ fun ilanilọyẹ lori awọn ayederu iroyin.

Lara awọn eeyan pataki to wa nibi eto naa ni Igbakeji aarẹ orilẹede yii, Ọjọgbọn Yemi Oṣinbajo, Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka, adari agba fun ẹka iroyin ni BBC, Jamie Angus ati bẹẹbẹẹ lọ.

BBC Fake News Conference
Àkọlé àwòrán, BBC Fake News Conference

Awọn akópa jẹ́ kó di mímọ̀ pé awọn iroyin ayederu ti n gbayi gaan laarin awujọ yala ọ̀rọ̀ ti wọn kọ, fọto tabi fidio bẹẹ si ni awọn mọ Naijiria gan ti ṣe tan lati gba a.

Ọrọ yii ni awọn olujiroro nibi ipade apero naa n yanana.

BBC Fake News Conference
Àkọlé àwòrán, BBC Fake News Conference