Lagos 2019: Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ awakọ̀ èrò ṣíná ìbọn níbi ìpolongo ìbò Sanwo-Olu l'Eko

Aworan idarudapọ awọn janduku pẹlu ohun ija lọwọ

Oríṣun àwòrán, PMnews

Àkọlé àwòrán, Gómìnà Ambọde ni ó ń sọ̀rọ̀ nígbà tí wàhálà náà bẹ́ sílẹ̀

Oniroyin mẹta lo faragbọta nibi ipolongo idibo oludije ipo gomina ipinlẹ Eko labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC, Babajide Sanwo-olu nilu Eko ni ọjọ iṣẹgun.

Nibi ipolongo idibo ọhun to waye ni gbagede Skypower field ni Ikeja nilu Eko ni wahala ti bẹ silẹ ni nnkan bii agogo kan abọ ọsan lasiko ti gomina Akinwumi Ambọde fi wa lori pepele nibi ti o ti n sọ ọrọ rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bii iroyin ti o n tẹ BBC News Yoruba lọwọ ṣe sọ, laaarin awọn igun ẹgbẹ awakọ ero NURTW meji ni ina wahala naa ti suyọ ti wọn si bẹrẹ si nii yibọn fun ara wọn.

Lara awọn ti ọta ibọn ba ni oniroyin kan lati ileeṣẹ iwe iroyin the Nation, Emmanuel Oladesu, Temitọpẹ Ogunbanke lati iwe iroyin NewsTelegraph pẹlu ayaworan ileeṣẹ mohunmaworan Ibilẹ Television, Abiọdun Yusuf atawọn eeyan miran.

Amọṣa, ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Eko ni awọn ṣi n ṣe iwadii lori ọrọ naa ati pe laipẹ ni atẹjade yoo jade lori rẹ.

Àkọlé fídíò, Alao Akala:Èmi àti Ajimọbi kò ṣe ìlérí kankan fún ara wa

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Chike Otti ni oju awọn agbofinro to gbogbo ohunkorun to ba fẹ da omi alaafia ipinlẹ naa ru.

Ninu atẹjade ti Sẹsan Daini to jẹ alukoro ileeṣẹ ipolongo ibo fun sanwo -olu, oludije ẹgbẹ oṣelu APC fun ipo gomina ni ipinlẹ Eko, lootọ ni wahala bẹ silẹ ṣugbọn laarin awọn ọmọ ẹgbẹ kan ni.

"wahala to waye lopin eto naa wa laaarin awọn igun ẹgbẹ meji kan ti wọn wa nibi eto naa."

Iroyin tun ṣalaye pe nṣe lawọn janduku lo anfani wahala to bẹ silẹ naa lati fi ja ọpọ awọn eeyan to wa fun ipolongo naa lole awọn ohun ini wọn.