Amina Zakari: INEC ní Amina Zakari kọ́ ni yóò wà ní ìdí ìbò kíkà lásìkò ìdìbò 2019

Amina Zakari

Oríṣun àwòrán, INEC

Àkọlé àwòrán, Ìgbàkejì nìyí tí ìyànsípò Amina Zakari yóò máa fa awuyewuye lórílẹ̀èdè Nàìjíríà nítorí àhesọ ọ̀rọ̀ pé ó tan mọ́ Ààrẹ Buhari
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ INEC ti sọrọ lori awuyewuye to n ja ranyinranyin lori iyansipo Amina Zakari gẹgẹ bi olori igbimọ ibudo ikabo aarẹ ti yoo waye loṣu keji ọdun 2019.

Ọpọ awọn eeyan pẹlawọn ẹgbẹ alatako gbogbo ni wọn ti tako iyansipo Amina Zakari ti o jẹ ana fun Buhari.

Amọṣa, oludari ipolongo ati idanilẹkọ lajọ INEC, Oluwọle Osaze-Uzzi ṣalaye fun BBC News Yoruba pe ko si nnkan ti o kan Hajia Zakari pẹlu ibo kika ni ipo tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan an si naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọgbẹni Osaze-Uzzi to jẹ agbẹnusọ fun ajọ INEC ṣalaye pe ojuṣe igbimọ ti wọn fi Amina Zakari ṣe olori fun ni lati ṣaayan eto gbogbo fun lilọ wọọrọwọ eto ibo kika ati pe Alaga ajọ naa ni Ọga agba patapata lori eto ibo kika ti ko si si ohun kan ti o lee yii pada.

"Aini imọ to kunna lori igbimọ yii lo n fa gbọyi-sọyi ati awuyewuye to n waye naa", Osaze-Uzzi ṣalaye fun BBC News Yoruba.

"Ojuṣe igbimọ ti alaga ajọ yii fi arabinrin Amina Zakari ṣe olori fun ni lati rii pe gbọngan ti wọn yoo lo fun ibo kika wa ni sẹpẹ, gbogbo eto ati ohun elo ti wọn yoo lo nibẹ pẹlu bii eto abo, ohun elo ayelujara ati bẹẹ bẹẹ wa ni sẹpẹ lai si idiwọ. Ko si ohun to kan an pẹlu ibo kika nitori ojuṣe alaga ajọ INEC niyẹn."

O ni arabinrin Zakari kun oju iwọn lati di ipo yii mu nitori ọkan lara awọn ọmọ igbimọ alakoso ajọ INEC ni ti kii sii ṣe oni lo ti wa nibẹ.

O wa fi da awọn ọmọ orilẹede Naijiria loju pe eera kan ko ni rin ibo wọn nitori ajọ naa ṣetan lati rii pe eto idibo apapọ ọdun 2019 kẹsẹjari.

Báwo ni Amina Zakari àti Buhari ṣe tan?

Ọrọ iyansipo Amina Zakari gẹgẹ bii alamojuto ibudo ikabo fun ọdun 2019 ti n fa ọpọ awuyewuye lati igba ti ajọ INEC ti kede rẹ ni ọjọbọ.

Ohun ti ọpọ si n ke ibosi le lori naa ni pe, arabinrin Amina Zakari tan mọ aarẹ Muhammadu Buhari, ọkan lara awọn eeyan ti yoo dije fun ipo aarẹ lorilẹede Naijiria ni ọjọ kẹrindinlogun oṣu keji, ọdun 2019.

Àkọlé fídíò, Ìgunnukó: Àwọn Tápà gbà pé ẹni tó bá ń sin Ìgunnukó kò ní ráùn ohun rere

Ohun ti wọn n sọ ni pe, ko tọna labẹ ilana pin in re-la a re, ọkan ko gbọdọ jukan lọ pe, ki ibatan oludije kan tun lọwọ ninu eto kika ibo ti o ti n kopa.

Bi o tilẹ jẹ wi pe, alaga ajọ INEC lo laṣẹ lati ṣeto iyansipo ajọ naa, ti o si jẹ pe oun lo ṣe eto iyansipo tuntun yii, aarẹ Buhari ko lagbara rẹ labẹ ofin lati yii pada.

Amọ sibẹ awọn eeyan ati onwoye ko yee sọrọ lori ipa ti o ṣee ṣe ki igbesẹ yii ni, lori oju ti awọn eeyan yoo fi wo abajade eto idibo apapọ naa.

Bawo ni Amina Zakari ṣe tan mọ Buhari?

Alaga ajọ INEC ati awọn igbimọ rẹ

Oríṣun àwòrán, INEC

Àkọlé àwòrán, Oniruuru iha lawọn eeyan, lẹgbẹlẹgbẹ, ati lajọlajọ ti sọ lori igbesẹ yii

Boya ka bi ara wa leere ibeere yii; bawo gan ni Amina Zakari ṣe tan mọ Buhari?

  • Ọmọ Emir Kazaure ni ipinlẹ Jigawa ni Amina Bala Kazaure, ṣugbọn ọmọ ipinlẹ Katsina ni Buhari.
  • Ọkọ Amina, bi o tilẹ jẹ pe o ti ku, ọmọ ilu Kazaure naa ni.
  • Ipinlẹ Kano ni o ti pari ileewe alakọbẹrẹ rẹ.
  • Fasiti, Ahmadu Bello, ABU ni Zaria lo ti kẹkọ gboye imọ ijinlẹ ninu ogun pipo lọdun 1980 ṣugbọn Buhari ko lọ si fasiti yii.
  • Aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹ, Goodluck Jonathan lo yan an sipo gẹgẹ bii kọmiṣọna lajọ eleto idibo Naijiria, INEC ṣaaju idibo apapọ lọdun 2015.

Bi o ba ri bẹẹ, bawo wa ni Zakari ati Buhari ṣe wa tan ?

  • Igbeyawo lo so Buhari ati Amina Zakari pọ. Iroyin to tẹ BBC News lọwọ jẹ ko di mimọ pe, ẹgbọn aarẹ Buhari obinrin lo fẹ baba Amina Zakari, iyẹn Emir ti Kazaure.
  • Iyawo baba Amina Zakari ni ẹgbọn Buhari, ṣugbọn kii ṣe iya rẹ.
Àkọlé fídíò, Kwara yóò gbàlejò BBC Yoruba

Kini awọn eeyan n sọ lori igbesẹ yii?

Oniruuru iha lawọn eeyan, lẹgbẹlẹgbẹ, ati lajọlajọ ti sọ lori igbesẹ yii.

Gomina ana ni ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayoṣe ni 'boya ki wọn kuku yan ọmọ aarẹ gẹgẹ bii alaga ajọ eleto idibo INEC?'

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Gbajugbaja oniroyin, Dele Momodu ni tirẹ ṣalaye lori ikanni twitter rẹ pe '...Haba!'

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Ohun ti Dokita Rafiq Raji ati Ajibade Adegbitẹ fi ṣakawe rẹ ni tiwọn ni pe '...igbesẹ ti ko bojumu ni eyi.'

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Skip X post, 4

End of X post, 4