PDP: A ò fẹ́ ẹ̀jẹ̀ Buhari gẹ́gẹ́ bí alábojútó ìbò kíkà

Oríṣun àwòrán, INEC OFFICIAL
Ẹgbẹ òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP) ti ní awọn kọ bi wọn ṣe yan Amina Zakari to jẹ ọmọ sí ọmọ iya aarẹ Buhari gẹgẹ bi alaga igbimọ ti yoo ka ibo to n bọ lọna ni Naijiria.
Ẹgbẹ oṣelu naa ni bi ajọ eleto idibo ba fi le ṣe eyi, a jẹ pe alaga ajọ naa, Ọjọgbọn Mahmoud Yakubu n san ọna ati wọle pada fun aarẹ ni.
Bakan naa, ẹgbẹ oṣelu PDP fi sita loju opo Twitter wọn pe awọn fi gbogbo ẹnu sọ ọ pe awọn kọ yiyan sipo Amina Zakari to jẹ̀ ẹjẹ aarẹ Muhammadu Buhari ninu idibo kan naa ti Buhari ti jẹ oludije.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Kola Ọlọgbọndiyan to jẹ adari ẹka iroyin fun igbimọ ipolongo idibo ẹgbẹ naa sọ fun awọn oniroyin nibi ipade apero ti wọn ṣe peawọn ko gba Zakari to jẹ kọmisna ajọ eleto idibo to nboju to eto ilera ati itọju nitori ọpọlọpọ ẹsun to ti wa lọrun rẹ.









